Kíkọbiara Sí Ìkìlọ̀ Gba Ẹ̀mí Wọn Là
JÉSÙ KRISTI ti kìlọ̀ ṣáájú pé òpin ń bọ̀ lórí ètò ìjọsìn àwọn Júù èyí tí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ ojúkò rẹ̀. Kò sọ ọjọ́ tí èyí yóò ṣẹlẹ̀. Àmọ́, ó sọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ tí yóò yọrí sí ìparun yẹn. Ó rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣọ́nà kí wọ́n sì sá kúrò ní àgbègbè eléwu náà.
Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé.” Ó tún sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, . . . nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti má ṣe padà lọ kó dúkìá wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ sá jáde kíákíá bí wọn ò bá fẹ́ pàdánù ẹ̀mí wọn.—Lúùkù 21:20, 21; Mátíù 24:15, 16.
Láti lè paná ọ̀tẹ̀ tó ti wà nílẹ̀ látọjọ́ pípẹ́, Cestius Gallus kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù wá bá Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Ó tiẹ̀ wọnú ìlú náà ó sì sàga ti tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀. Ṣìbáṣìbo bá àwọn aráàlú. Àwọn tó ń ṣọ́nà tètè mọ̀ pé àjálù ti wọlé dé. Àmọ́ ṣé wọ́n á rọ́nà sá lọ? Lójijì, Cestius Gallus ṣàdédé kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò. Làwọn ajàjàgbara Júù bá bẹ̀rẹ̀ sí lé wọn lọ. Àkókò rèé láti sá jáde ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo àgbègbè Jùdíà!
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, àwọn ọmọ ogun Róòmù padà wá lábẹ́ ìdarí Fẹsipásíà àti ọmọkùnrin rẹ̀, Títù. Ni ogun bá gba gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn kan. Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn ará Róòmù fi àwọn òpó igi aboríṣóńṣó ṣe odi yí ìlú náà ká. Wọ́n dí gbogbo ọ̀nà tó ṣeé gbà sá lọ pátápátá. (Lúùkù 19:43, 44) Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nínú ìlú náà sì bẹ̀rẹ̀ sí para wọn nípakúpa. Àwọn ará Róòmù pa lára àwọn tó ṣẹ́ kù wọ́n sì kó àwọn kan nígbèkùn. Wọ́n pa ìlú yẹn àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run pátápátá. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Júù náà tó ń jẹ́ Josephus ṣe sọ ní ọ̀rúndún kìíní, ó ní, ó lé ní mílíọ̀nù kan àwọn Júù tó jìyà kú. Wọn ò tíì tún tẹ́ńpìlì yẹn kọ́ látìgbà yẹn.
Ká ní àwọn Kristẹni ṣì wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa ni, wọn ì bá pa wọ́n tàbí kí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ pẹ̀lú àwọn yòókù. Àmọ́, àwọn òpìtàn ayé ọjọ́un ròyìn pé àwọn Kristẹni ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run wọ́n sì sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù àti gbogbo àgbègbè Jùdíà lọ sáwọn òkè ńlá tó wà ní apá ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì. Àwọn kan tẹ̀ dó sí Pẹ́là, ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Pèríà. Wọ́n fi Jùdíà sílẹ̀ wọn ò sì padà síbẹ̀ mọ́. Kíkọbiara sí ìkìlọ̀ Jésù gba ẹ̀mí wọn là.
Ṣé O Máa Ń Kọbi Ara sí Ìkìlọ̀ Láti Orísun Tó Ṣeé Gbára Lé?
Táwọn èèyàn bá ti ń gbọ́ onírúurú ìkìlọ̀ tí nǹkan kan ò sì ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ kì í ka gbogbo ìkìlọ̀ kún mọ́. Àmọ́, kíkọbiara sí ìkìlọ̀ lè gba ẹ̀mí rẹ là.
Nílẹ̀ Ṣáínà lọ́dún 1975, wọ́n ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkìlọ̀ pé ìsẹ̀lẹ̀ máa wáyé. Àwọn aláṣẹ ṣiṣẹ́ lórí ìkìlọ̀ yìí. Àwọn èèyàn ṣe ohun tí wọ́n ní kí wọ́n ṣe. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀mí lèyí sì gbà là.
Ní April ọdún 1991 lórílẹ̀-èdè Philippines, àwọn tó ń gbé abúlé ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Pinatubo ké gbàjarè pé ooru gbígbóná àti eérú ń tú jáde látinú òkè náà. Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Òkè Ayọnáyèéfín àti Ìsẹ̀lẹ̀ Lórílẹ̀-Èdè Philippines ṣàkíyèsí ipò yìí fún oṣù méjì, wọ́n wá ṣèkìlọ̀ pé òótọ́ lewu rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Ní kánmọ́, wọ́n kó ẹgbẹẹgbàárùn-ún èèyàn kúrò lágbègbè náà. Nígbà tó di June 15, ní òwúrọ̀ kùtù, òkè yìí dédé bú gbàù. Àgbáàràgbá ekuru lẹ́búlẹ́bú tú dà sójú sánmà, ó sì padà rọ̀ wá sílẹ̀ bo gbogbo àgbègbè náà bámúbámú. Kíkọbiara sí ìkìlọ̀ gba ẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn là.
Bíbélì kìlọ̀ pé òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ń bọ̀. Ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé báyìí. Bí òpin ti ń sún mọ́lé, ṣé ò ń ṣọ́nà? Ṣé ò ń ṣe nǹkan kan láti sá kúrò ní àgbègbè eléwu? Ṣé ò ń tara ṣàṣà láti kìlọ̀ fáwọn mìíràn pé káwọn náà sá kúrò ní àgbègbè eléwu?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Kíkọbiara sí ìkìlọ̀ gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ là nígbà tí Òkè Pinatubo tú eérú gbígbóná jáde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Nígbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn Kristẹni tó kọbi ara sí ìkìlọ̀ Jésù yè bọ́