Ǹjẹ́ O Lóye Ìgbà Tí A Wà Yìí?
MÍMỌ̀ pé ewu wà lè mú kí a wà láàyè. A lè fi ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àwọn erékùṣù ayọnáyèéfín méjì ṣàpẹẹrẹ èyí.
Òkè Ńlá Pelée, òkè ayọnáyèéfín tó pànìyàn jù ní ọ̀rúndún ogún, bú gbàù ní May 8, 1902, ní erékùṣù Caribbean ti Martinique. Díẹ̀ péré nínú àwọn 30,000 ènìyàn tí ń gbé Saint Pierre, ìlú tó wà lẹ́sẹ̀ òkè náà, ni kò pa.
Ní June 1991, Òkè Ńlá Pinatubo bú gbàù, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ìbúgbàù tó tóbi jù ní ọ̀rúndún náà nìyẹn. Ó ṣẹlẹ̀ ní àgbègbè tí èrò ti pọ̀ gan-an ní Philippines, nǹkan bí 900 ènìyàn ló pa. Ṣùgbọ́n, lọ́tẹ̀ yìí, kókó pàtàkì méjì ló gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀mí là: (1) mímọ̀ pé ewu wà àti (2) mímúratán láti tẹ̀ lé ìkìlọ̀.
Ìgbésẹ̀ Yíyẹ Ń Gbẹ̀mí Là
Òkè Ńlá Pinatubo ti wà láìtú nǹkan jáde fún ọgọ́rọ̀ọ́rún ọdún kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí fúnni lámì pé ó fẹ́ bú ní April 1991. Ooru gbígbóná àti gáàsì sulfur dioxide bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde láti ṣóńṣó orí rẹ̀. Ilẹ̀ mì tìtì nígbà mélòó kan, àgbájọ ìṣàn àpáta yíyòrò tó ki, tó jẹ́ àmì ìṣáájú pé aburú ń bọ̀, bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti inú òkè náà. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Nípa Òkè Ayọnáyèéfín àti Ìsẹ̀lẹ̀ baralẹ̀ kíyèsí i, wọ́n sì mú un dá àwọn aláṣẹ lójú láìpẹ́ pé, yóò jẹ́ ìwà ọgbọ́n láti kó 35,000 olùgbé àwọn ìlú àti abúlé tó wà nítòsí kúrò níbẹ̀.
Lọ́nà tí a lè lóye, àwọn ènìyàn lọ́ra láti sá fi ilé wọn sílẹ̀ láìmọ̀dí, àmọ́ àwòrán fídíò kan tó fi ewu tí ń bá ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín rìn hàn wọ́n kedere mú kí wọ́n ṣẹ́pá ìlọ́ra yẹn. Àwọn èrò rẹpẹtẹ náà kó lọ tàìkólọ ni lálà lù. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí wọ́n kó kúrò ni ìbúgbàù ńlá kan tú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àpáta kíkúnná, tó pọ̀ tó kìlómítà mẹ́jọ lóròó àti níbùú, dà sí àyíká. Ìṣàn ẹrẹ̀, tàbí ìṣàn lahar, wá pa ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn lẹ́yìn náà. Bí ó ti wù kí ó rí, bóyá ẹgbẹẹgbẹ̀rún kò kú, nítorí pé a ti kìlọ̀ fún wọn pé ewu ń bọ̀, wọ́n sì ti tẹ̀ lé ìkìlọ̀ náà.
Bíbọ́ Lọ́wọ́ Ìjábá Tí Ènìyàn Fà
Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì tiwa, àwọn Kristẹni tí ń gbé Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú ní láti pinnu lórí bóyá kí wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Sísá kúrò ní ìlú yẹn ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa gbà wọ́n là lọ́wọ́ ìparun tó dé bá àwọn olùgbé tó kù àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún Júù tí wọ́n lọ ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Àwọn ènìyàn tó wà nínú ìlú náà fún ayẹyẹ Ìrékọjá nígbà tí ẹgbẹ́ ogun ilẹ̀ Róòmù dí gbogbo ọ̀nà àsálà, lé ní mílíọ̀nù kan. Ìyàn, dídu agbára ìdarí, àti ìgbóguntì láìdẹwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Róòmù yọrí sí ikú fún àwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan.
Ìjábá tó fòpin sí ìṣọ̀tẹ̀ àwọn Júù sí ilẹ̀ Róòmù náà kò dé láìròtẹ́lẹ̀. Ní ẹ̀wádún mélòó kan ṣáájú ni Jésù Kristi ti sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò dó ti Jerúsálẹ́mù. Ó wí pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” (Lúùkù 21:20, 21) Àwọn ìtọ́ni wọ̀nyẹn ṣe kedere, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò sì fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú wọn.
Òpìtàn ọ̀rúndún kẹrin náà, Eusebius ará Kesaréà, sọ pé àwọn Kristẹni tó wà ní gbogbo Jùdíà tẹ̀ lé ìkìlọ̀ tí Jésù ṣe. Nígbà tí ẹgbẹ́ ogun Róòmù kó ogun wọn àkọ́kọ́ kúrò ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù kó lọ sí ìlú àwọn Kèfèrí ní Pella, tó wà ní ẹkùn ilẹ̀ Róòmù ní Perea. Nípa lílóye àkókò tí wọ́n wà àti títẹ̀lé ìkìlọ̀ Jésù, wọ́n la ohun tí a ti ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “ìdótì kan nínú àwọn tó burú jù lọ tó ṣẹlẹ̀ rí já.”
Lónìí, ó pọndandan kí a wà lójúfò bákan náà. Ó sì yẹ kí a gbé ìgbésẹ̀ pàtó pẹ̀lú. Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Godo-Foto, West Stock