SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
A Pinnu Pé A Ó Máa Sin Jèhófà
Philip Tengbeh
WỌ́N BÍ I NÍ 1966
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1997
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ogún lé e kúrò nílùú, ó wà lára àwọn tó kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún.
LỌ́DÚN 1991, èmi àti Satta aya mi sá fún ẹ̀mí wa nígbà tí àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ ya bo ìlú wa, ìyẹn Koindu ní Sierra Leone, tí wọ́n sì gbà á. Fún odidi ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, inú onírúurú àgọ́ àwọn tí ogun lé kúrò nílùú là ń gbé. Oúnjẹ máa ń wọ́n wa gan-an níbẹ̀, àìsàn máa ń ṣe wá, ìwà ìbàjẹ́ sì pọ̀ lọ́wọ́ àwọn tá a jọ wà nínú àgọ́.
Gbogbo àgọ́ tí a bá gbé ni a ti máa ń bẹ àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n fún wa nílẹ̀ ká lè fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbà míì wọ́n máa ń fún wa, àmọ́ wọn kì í fún wa nígbà míì. Síbẹ̀, a máa ń ṣètò ibi tí a ó ti máa ṣèpàdé láti jọ́sìn Ọlọ́run. A pinnu pé a ó máa sin Jèhófà. Bó ṣe di pé a kọ Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rin sí àwọn àgọ́ tí a gbé nìyẹn.
Nígbà tí ogun parí, a kò lè pa dà sí ìlú wa. Ogun tó jà fún ọ̀pọ̀ ọdún ti sọ ibẹ̀ dìdàkudà. Ni wọ́n bá tún kó wa lọ sí àgọ́ míì nítòsí ìlú Bo. Ibẹ̀ la ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wa karùn-ún, ẹ̀ka ọ́fíìsì ló sì fún wa lówó tí a fi kọ́ ọ.