ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 148-149
  • A Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Sójà Ọlọ̀tẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Sójà Ọlọ̀tẹ̀
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀gá Onílé-Ìṣọ́
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • A Ní Ọlọ̀tẹ̀ Nílé Bí?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • A Pinnu Pé A Ó Máa Sin Jèhófà
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 148-149

SIERRA LEONE ÀTI GUINEA

A Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Sójà Ọlọ̀tẹ̀

Andrew Baun

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1961

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1988

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní ìlú Pendembu ní àgbègbè ìpínlẹ̀ ìlà-oòrùn Sierra Leone nígbà tí ogun bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1991.

NÍ Ọ̀SÁN ọjọ́ kan, àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ wọ ìlú wa, wọ́n sì ń yìnbọn sókè fún nǹkan bíi wákàtí méjì. Ọmọdé làwọn kan lára wọn, kódà agbára káká ni wọ́n fi ń dá ohun ìjà wọn gbé. Ara wọn dọ̀tí gan-an, irun orí wọn ran pọ̀, ó rí játijàti, ó sì jọ pé wọ́n ti loògùn olóró.

Lọ́jọ́ kejì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pààyàn, wọ́n sì ń sọ àwọn míì di aláàbọ̀ ara. Wọ́n tún ń fipá bá àwọn obìnrin lòpọ̀. Gbogbo ìlú wá dà rú pátápátá. Arákùnrin Amara Babawo àti ìdílé rẹ̀ àtàwọn mẹ́rin kan tó ṣẹ̀sẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá forí pa mọ́ sí ilé mi. Ṣe ni àyà wa ń já.

“Ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ lẹ̀ ń kà yẹn. Ó dájú pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín”

Láìpẹ́, ọ̀gá àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ kan wá, ó sì pàṣẹ pé ká wá sí àgọ́ àwọn láàárọ̀ ọjọ́ kejì láti wá gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun. A ti pinnu pé a kò ní lọ́wọ́ sí ogun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé pípa ni wọ́n máa pa ẹni tó bá kọ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ṣe la gbàdúrà mọ́jú. A tètè jí láàárọ̀, a ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, a wá ń dúró de àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ yẹn. Àmọ́ a ò rí wọn.

Nígbà tó yá, ọ̀gá àwọn sójà ọlọ̀tẹ̀ kan àti sójà rẹ̀ mẹ́rin wá ń gbé inú ilé wa tipátipá. Ṣùgbọ́n wọ́n ní kí àwa náà ṣì wà níbẹ̀, torí náà, à ń ṣe ìpàdé déédéé, a sì ń ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ níbẹ̀. Àwọn sójà kan sọ pé: “Ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ lẹ̀ ń kà yẹn. Ó dájú pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, wọ́n bọ̀wọ̀ fún wa.

Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan nínú àwọn olórí ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ wá wo àwọn ọmọ ogun wọn tó ń gbé inú ilé mi tipátipá. Ó bẹ́rí fún Arákùnrin Babawo, ó sì bọ̀ ọ́ lọ́wọ́. Ó wá jágbe mọ́ àwọn sójà tó wà níbẹ̀, ó ní: “Ọ̀gá wa ni ọkùnrin yìí. Tí irun orí rẹ̀ kan tàbí ti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá dín pẹ́nrẹ́n, ẹ dáràn! Ẹ gbọ́?” Wọ́n ní: “Bẹ́ẹ̀ ni sà!” Olórí àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ yìí wá fún wa ní lẹ́tà kan tó fi pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun Revolutionary United Front pé kí wọ́n má fọwọ́ kàn wá torí aráàlú tí kì í fa ìjàngbọ̀n ni wá.

Ní ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn náà, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ tó yapa síra bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jà, la bá sá lọ sí ilẹ̀ Làìbéríà nítòsí wa. Àwùjọ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ míì ń halẹ̀ mọ́ wa níbẹ̀. A wá sọ fún wọn pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá.” Ni sójà kan bá ní: “Ó dáa, kí ni Jòhánù 3:16 sọ?” Nígbà tá a ka ẹsẹ yẹn lórí, ó jẹ́ ká kọjá.

Lẹ́yìn náà, a tún pàdé ọ̀gá àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ míì. Ó pàṣẹ pé kí èmi àti Arákùnrin Babawo tẹ̀ lé òun. Ẹ̀rù ń bà wá pé ṣe ló fẹ́ pa wá. Ni ọ̀gá sójà náà bá sọ fún wa pé òun ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí kí ogun tó bẹ̀rẹ̀. Ó fún wa lówó, ó tún ní ká kọ lẹ́tà, ó sì bá wa mú un lọ fún àwọn ará tó wà ní ìjọ ìtòsí. Láìpẹ́, arákùnrin méjì dé, wọ́n kó àwọn ẹrù kan wá láti fi ràn wá lọ́wọ́, wọ́n sì kó wa kúrò níbẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́