SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
Ọ̀gá Onílé-Ìṣọ́
James Koroma
WỌ́N BÍ I NÍ 1966
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1990
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó ń bá ètò Ọlọ́run kó lẹ́tà àtàwọn nǹkan míì nígbà ogun abẹ́lé.
LỌ́DÚN 1997, nígbà tí ìjọba àtàwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ jọ wà á kò ní ìlú Freetown, mo yọ̀ǹda láti máa bá ètò Ọlọ́run kó lẹ́tà àtàwọn nǹkan míì láti ìlú Freetown lọ síbi tí wọ́n fi ṣe ẹ̀ka ọ́fíìsì fúngbà díẹ̀ nílùú Conakry ní orílẹ̀-èdè Guinea.
Lọ́jọ́ kan èmi àti àwọn ọkùnrin kan jọ wọkọ̀ èrò ní gáréèjì. A wá ń gbúròó ìbọn lọ́ọ̀ọ́kán, ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wá. Bí ọkọ̀ wa ṣe dé ibì kan láàárín ìgboro, ìbọn bẹ̀rẹ̀ sí í dún lọ́tùn-ún lósì. Ni awakọ̀ wa bá pa dà sẹ́yìn, ó sì gbọ̀nà míì. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan tó gbé ìbọn dání dá wa dúró, wọ́n ní ká sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ wa. Wọ́n bi wá láwọn ìbéèrè, wọ́n sì jẹ́ ká kọjá. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn sójà kan tún dá wa dúró. Torí pé ọ̀kan lára èrò ọkọ̀ wa mọ ọ̀gá wọn, wọ́n jẹ́ ká kọjá. Nígbà tá a fẹ́ jáde nílùú, a bá àwùjọ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ kẹta lójú ọ̀nà, wọ́n sì bi wá ní ìbéèrè, àmọ́ wọ́n ní ká máa lọ. Bí a ṣe ń bá ìrìn wa lọ sí apá àríwá là ń kan àwọn ibi tí wọ́n ti ń dá àwọn èèyàn dúró lójú ọ̀nà títí di ìrọ̀lẹ́ tí ọkọ̀ wa tó ti bu táútáú wọ ìlú Conakry.
Láwọn ìgbà míì tí mo tún lọ, mo kó àwọn páálí táwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa wà nínú rẹ̀, àwọn nǹkan èèlò ọ́fíìsì, àwọn ìwé tó jẹ́ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn ẹrù táwọn ará nílò dání. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti bọ́ọ̀sì kékeré ni mo sábà máa ń wọ̀. Àmọ́ àwọn aláàárù àti ọkọ̀ òbèlè tún máa ń bá mi gbé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kọjá odò àtàwọn igbó ẹgàn.
Nígbà kan tí mò ń gbé ohun tá a fi ń ṣiṣẹ́ láti ìlú Freetown lọ sí ìlú Conakry, àwọn sójà ọlọ̀tẹ̀ dá bọ́ọ̀sì kékeré tí mo wọ̀ dúró ní ibodè. Nígbà tí ọ̀kan lára wọn rí ẹrù mi, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bi mí ní ìbéèrè tìfura-tìfura. Mo bá tajú kán rí ẹnì kan tá a jọ lọ sílé ìwé lára àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà. Àwọn sójà yẹn ń pè é ní Olóró, òun lojú ẹ̀ sì ranko jù láàárín wọn. Mo bá sọ fún ẹni tó ń bi mí léèrè ọ̀rọ̀ pé Olóró ni mo wá rí, mo sì pè é. Olóró dá mi mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì sáré wá bá mi. A dì mọ́ra, a sì bú sẹ́rìn-ín. Ó wá dáwọ́ ẹ̀rín dúró.
Ó bi mí pé: “Ṣé kò sí o?”
Mo ní: “Mo fẹ́ kọjá sí orílẹ̀-èdè Guinea ni.”
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pàṣẹ fún àwọn sójà yẹn pé kí wọ́n jẹ́ kí ọkọ̀ bọ́ọ̀sì wa kọjá láìyẹ̀ wá wò.
Látọjọ́ náà, tí mo bá ti dúró níbi tí wọ́n ti ń dá ọkọ̀ dúró yẹn, Olóró á ní kí àwọn sójà jẹ́ kí n kọjá. Mo fún àwọn sójà náà ní àwọn ìwé ìròyìn wa, wọ́n sì dúpẹ́ gan-an. Kò pẹ́ tí wọ́n fi ń pè mí ní Ọ̀gá Onílé-Ìṣọ́.