ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/8 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu—Bí Ìṣòro Náà Ṣe Gbilẹ̀ tó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu—Bí Ìṣòro Náà Ṣe Gbilẹ̀ tó
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àníyàn Ń Peléke
  • Àwọn Ẹran Ìgbẹ́ Orí Ilẹ̀ Ayé Tí Ń Pòórá
    Jí!—1997
  • Ìdáàbò Bò Ní Ìdojú Kọ Àkúrun
    Jí!—1996
  • Ìdí Tí Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Fi Wà Nínú Ewu
    Jí!—1996
  • Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu—Bí Ó Ṣe Kàn Ọ́
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 8/8 ojú ìwé 3-4

Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu—Bí Ìṣòro Náà Ṣe Gbilẹ̀ tó

ẸYẸ dodo ti wáá di àmì àkúrun. Èyí tí ó kẹ́yìn lára àwọn ẹyẹ tí kì í fò wọ̀nyí kú ní nǹkan bí 1680 ní erékùṣu Mauritius. Ọ̀pọ̀ lára àwọn irú ọ̀wọ́ tí ó dojú kọ ewu nísinsìnyí pẹ̀lú ń gbé ní àwọn erékùṣù. Láàárín 400 ọdún tí ó kọjá yìí, 85 lára àwọn irú ọ̀wọ́ ẹyẹ 94 ni a mọ̀ pé wọ́n ti pòórá.

Àwọn ẹran tí ń gbé àwọn kọ́ńtínẹ́ǹtì gbígbòòrò pẹ̀lú wà nínú ewu àkúrun. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹkùn tí ń káàkiri jákèjádò Rọ́ṣíà nígbà kan rí. Nísinsìnyí, kìki ẹ̀ya irú ọ̀wọ́ Amur ló ṣẹ́ kù ní Siberia, iye rẹ̀ sì ti dín kù sí 180 sí 200 péré. A ròyìn pé iye àwọn ẹkùn ìha gúúsu China jẹ́ 30 sí 80 péré. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London ròyìn pé àwọn ẹranko wọ̀nyí dojú kọ àkúrun ní Indochina “láàárín ọdún mẹ́wàá.” Bákan náà, ní India, tí ó jẹ́ ibùgbé àdánidá fún nǹkan bí ìdá méjì nínu mẹ́ta àwọn ẹkùn tí ń bẹ lágbàáyé, àwọn aláṣẹ ń fojú bù ú pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹ̀dá ọlọ́lá ńlá wọ̀nyí pòórá láàárín ẹ̀wádún kan.

Àwọn ẹranko rhinoceros àti ẹranko cheetah ń tán lọ. Ní China, àwọn òmìrán ẹranko panda ń káàkiri ní ìkẹ́gbẹ́jẹ̀ tí kò ju mẹ́wàá lọ nínú ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan. Àwọn ẹranko pine marten ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú run ní Wales, ìwé agbéròyìnjáde The Times sì sọ pé, àwọn ọ̀kẹ́rẹ́ pupá “lè kú run ní gbalasa ilẹ̀ England àti Wales láàárín ọdún mẹ́wàá sí 20 tí ń bọ̀.” Ní ẹ̀yin Àtìláńtíìkì lọ́hùn-ún, ní United States, àwọn àdán ni ẹranko afọ́mọlọ́mú orí ilẹ̀ tí a wu léwu jù lọ.

Bí ọ̀rán ti rí nínú àwọn òkun àgbáyé kò sàn jù bẹ́ẹ̀ náà lọ. Ìwe The Atlas of Endangered Species pe ìjàpá òkun ní “ẹ̀dá tí ó ṣeé ṣe kí a ti wu léwu jù lọ” lára àwọn ẹ̀dá òkun. Ó jọ pé ipò àwọn jomijòké sàn díẹ̀; ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyin New Scientist ṣe sọ, irú ọ̀wọ́ àwọn jomijòkè 89 ti wà “nínú ewu àkúrun” láàárín ọdún 25 tí ó kọjá. Nǹkan bí ìpín 11 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn irú ọ̀wọ́ ẹyẹ àgbáyé dojú kọ àkúrun pẹ̀lú.a

Ṣùgbọ́n, nípa ti àwọn ẹ̀dá kéékèèké, irú bíi labalábá ńkọ́? Ipò náà jọra. Ó lé ní ìdá mẹ́rin 400 irú ọ̀wọ́ labalábá ilẹ̀ Europe tí ó wà nínú ewu—àkúrun tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ 19. Labalábá ńlá onígbá ìjàpá ti ilẹ̀ Britain ti wọ ẹgbẹ́ àwọn irú ọ̀wọ́ tí ó kú àkúrun bíi ti ẹyẹ dodo ní 1993.

Àníyàn Ń Peléke

Irú ọ̀wọ́ ẹ̀dá mélòó ní ń kú run lọ́dọọdún? Ìdáhùn náà sinmi lórí ògbógi tí o bá bi léèrè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn onímọ sáyẹ́ǹsì kò fohùn ṣọ̀kan, gbogbo wọ́n fara mọ́ òtítọ́ náà pé ọ̀pọ̀ irú ọ̀wọ́ wà nínú ewu kíkú àkúrun. Onímọ̀ ìbátan láàárín àwọn ohun alààyè àti ibùgbe wọn, Stuart Pimm, ṣàkíyèsí pé: “Àìfohùn ṣọ̀kan tí ó wà nípa bí a ṣe ń yára pàdánù [àwọn irú ọ̀wọ́] wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn iyàn jíjà nípa ọjọ́ ọ̀la wa ni.” Ó fi kún un pé: “La àwọn ọ̀rúndún tí ó ti kọjá já, a ti mú ìwọ̀n àkúrun àwọn irú ọ̀wọ́ yá kánkán gan-an ré kọjá ìwọ̀n àdánidá. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ọjọ́ ọ̀la wá túbọ̀ pòkúdu.”

Pílánẹ́ẹ̀ti wa, Ilẹ̀ Ayé, dà bí ilé kan. Àwọn ènìyàn kan tí ń ṣàníyàn nípa àwọn irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu ń kọ́ ecology, ọ̀rọ̀ kan tí a ṣẹ̀dá ní apá ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún láti inú ọ̀rọ̀ ède Gíríìkì náà, oiʹkos, “ilé kan.” Ẹ̀ka ẹ̀kọ́ yìí ń darí àfiyèsí sí àjọṣepọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn. Ìdàníyàn tí ń pọ̀ sí i nínú ìdáàbò bo ohun alààyé ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àwọn ìròyìn nípa àkúrun ni ó tanná ràn án. Ní United States, èyí ṣamọ̀nà sí ìdásílẹ̀ àwọn ọgbà ohun alààyè àti àwọn agbègbè tí a ṣọgbà yí ká, tí wọ́n ń pèsè ibi ààbò fún àwọn ẹ̀dá. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, a fojú díwọn rẹ̀ pé 8,000 àwọn ibi ìdáàbò bo ohun alààyè tí a kò fi dọ́sìn, tí a mọ̀ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ní ń bẹ lágbàáyé. Pa pọ̀ pẹ̀lú àfikún 40,000 àwọn ibi tí ń ṣèrànwọ́ láti bójú tó ibùgbé àdánidá, wọ́n para pọ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún àpapọ̀ gbogbo ojú ilẹ̀ àgbáyé.

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ń ṣàníyàn nísinsìnyí ń ṣètìlẹ́yìn fún ohun tí a sábà ń pè ní ìlépa ìdágbósí, yálà nípasẹ̀ àwọn àjọ ìlépa tí ń polongo ewu àkúrun tàbí àwọn tí ó wulẹ̀ ń kọ́ àwọn ènìyàn nípa bí àwọn ohun alààyè ṣe gbára lé ara wọn láti wà láàyè. Láti ìgbà Àpérò Nípa Ọ̀ràn Ilẹ̀ Ayé ní Rio, ní 1992, ìwàlójúfò sí àwọn ọ̀ràn àyíká ti túbọ̀ ń jẹ́ àbùdá àwọn èròǹgbà ìjọba.

Ìṣòro àwọn irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu jẹ́ kárí ayé, ó sì ń gbilẹ̀ sí i. Ṣùgbọ́n kí ló fà á? Ìgbìdánwò kankan láti dènà àkúrun àwọn irú ọ̀wọ́ ha ń kẹ́sẹ járí lọ́wọ́lọ́wọ́ bí? Nípa ọjọ́ iwájú ńkọ́? Báwo ló ṣe kàn ọ́? Àpilẹ̀kọ wa tí ó tẹ̀ lé e fúnni ní ìdáhùn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A túmọ̀ irú ọ̀wọ́ tí ó kú àkúrun sí ọ̀kan tí a kò ti rí nínú ìgbẹ́ mọ́ fún 50 ọdún, nígbà tí irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu ń tọ́ka sí àwọn tí wọ́n wà nínú ewu àkúrun, bí àyíká ipò tí wọ́n wà ní lọ́ọ́lọ́ọ́ kò bá yí padà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́