ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/8 ojú ìwé 4-6
  • Ìdí Tí Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Fi Wà Nínú Ewu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tí Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Fi Wà Nínú Ewu
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Pípa Ibùgbé Àdánidá Run
  • Ìkọlù Tààràtà
  • Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu—Bí Ìṣòro Náà Ṣe Gbilẹ̀ tó
    Jí!—1996
  • Ìdáàbò Bò Ní Ìdojú Kọ Àkúrun
    Jí!—1996
  • Àwọn Àǹfààní Igbó Kìjikìji
    Jí!—1998
  • Ǹjẹ́ Àwọn Igbó Kìjikìji Wa Yóò Máa Wà Nìṣó?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 8/8 ojú ìwé 4-6

Ìdí Tí Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Fi Wà Nínú Ewu

ÀWỌN irú ọ̀wọ́ ń kú run nítorí ìdí púpọ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò ìdí pàtàkì mẹ́ta. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn ń fa méjì lára wọn lọ́nà tí kò ṣe tààrà, wọ́n sì ń fa ọ̀kan yòó kù ní tààrà.

Pípa Ibùgbé Àdánidá Run

Pípa ibùgbé àdánidá run ń ṣàlékún rẹpẹtẹ sí bí àwọn irú ọ̀wọ́ ṣe ń dín kù. Ìwe The Atlas of Endangered Species pe èyí ní “ìwuléwu tí ó pàfiyèsí jù lọ,” ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ “èyí tí ó ṣòro láti dèna rẹ̀ jù lọ.” Bí iye ènìyán ṣe ń bú rẹ́kẹ sí í lágbàáyé ń fipá mú àwọn ẹ̀dá ènìyàn láti gba ilẹ̀ tí ó ti fìgbà kan rí jẹ́ ibùgbé àdánidá àwọn ohun alààyè tí a kò fi dọ́sìn mọ́ tiwọn. Àpẹẹrẹ gbígbàfiyèsí kan nípa èyí ni ti àwọn ẹgàn àgbáyé.

Ìdíyelé apániláyà tí ń darí àfiyèsí sí ohun tí ọ̀pọ́ kà sí ìpàdánù ọrọ̀ ṣíṣeyebíye lọ́nà tí ń múni káàánú ni pé ‘kì yóò sí ẹgàn kankan mọ́ láàárín 40 ọdún sí i.’ Ní tòótọ́, iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́rin gbogbo egbòogi tí a mọ̀ ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé ni a ń mú jáde láti inú àwọn ewéko ẹgàn ilẹ̀ olóoru. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a fojú bù ú pé àwọn ẹgàn wà ní kìkì ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-ún ojú ilẹ̀ pílánẹ́ẹ̀tì, wọ́n jẹ́ ibùgbé àdánidá fún ìdá mẹ́rin nínu márùn-ún lára àwọn ewéko tí ń hù láti inú ilẹ̀ wá.

Àwọn ìgbòkègbodò gígé gẹdú àti àwọn ìyípadà nínú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ ń gba aṣọ igi ẹlẹ́wà àdánidá lára àwọn ẹgàn Ìwọ̀ Oòrun Áfíríkà. Pípa igbó run ní kọ́ńtínẹ́ǹtì kékeré ti India tilẹ̀ ti yí ojú ọjọ́ pàápàá padà, tí ó ń dín òjò kù ní àwọn apá ibì kan, tí ó sì ń fa àkúnya omi ní apá ibòmíràn.

Bí ènìyán ṣe ń gégi lulẹ̀ láti palẹ̀ fún iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn ewéko, ẹranko, ẹyẹ, ẹ̀dá afàyàfà, àti kòkòrò ń kú dà nù. Ọ̀jọ̀gbọ́n Edward Wilson ti Harvard fojú bù ú pé ìpàdánù igbó jẹ́ àròpọ̀ ìpín 1 nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dọọdún, tí èyí sì ń pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún irú ọ̀wọ́ run nígbẹ̀yìngbẹ́yín. A ń bẹ̀rù pé ọ̀pọ̀ irú ọ̀wọ́ yóò pòórá kí sáyẹ́ǹsí tóó fún wọn ní orúkọ pàápàá.

Ipò náà jọra ní àwọn ilẹ̀ àbàtà àgbáyé, ibùgbé àdánidá mìíràn tí a ń wu léwu. Àwọn kọ́lékọ́lé ń gbẹ omi wọn, kí wọ́n lè kọ́lé, àwọn àgbẹ̀ ń yí wọn padà sí ilẹ̀ tí ó dára fún ọ̀gbìn, kí wọ́n lè fi dáko. Láàárín 100 ọdún tí ó kọjá, èyí tí ó tó ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ pápá gbígbẹ ní Europe ni a ti gbà fún iṣẹ́ ọ̀gbìn. Ìpàdánù àwọn pápá oko ní Britain láàárín 20 ọdún tó kọjá ti tanná ran ìdínkù ìpín 64 nínú ọgọ́rùn-ún lára iye àwọn ẹyẹ thrush olórin dídùn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé ìròyin Time pe erékùṣu Madagascar ní “ọkọ̀ Nóà fún ohun ọ̀gbìn àti ẹranko,” ọ̀pọ̀ yanturu onírúurú ohun alààyè inú rẹ̀ tí a kò fi dọ́sìn wà nínú ewu. Nígbà tí iye ènìyàn ń pọ̀ sí i, tí gbèsè tí ó jẹ àwọn orílẹ̀-èdè míràn sì ń pọ̀, ìkìmọ́lẹ̀ lórí àwọn olùgbé erékùṣù náà, láti sọ igbó di oko ìrẹsì di púpọ̀ sí i. Nítorí pé ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin ibùgbé àdánidá ẹranko bamboo lemur aláwọ̀ wúrà ti pòórá láàárín 20 ọdún tó kọjá, 400 péré ló ṣẹ́ kù nínú àwọn ẹranko wọ̀nyí.

Dájúdájú, ìyípadà tegbòtigaga tí ènìyàn ń ṣe nipa ọ̀ran lílo ilẹ̀ ń jin ohun alààyè tí a kò fi dọ́sìn ní ẹkùn ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan lẹ́sẹ̀. Bí àpẹẹrẹ mìíràn, ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn àwọn ará Polynesia, tí wọ́n dé sí Hawaii ní 1,600 ọdún sẹ́yìn. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde àwọn ìgbòkègbodò wọn, irú ọ̀wọ́ ẹyẹ 35 ló ti kú run.

Àwọn tètèdé abulẹ̀dó tí wọ́n wá sí Australia àti New Zealand kó àwọn ológbò tí a fi dọ́sìn wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè, díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí wáá ya ẹhànnà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyin New Scientist ṣe wí, àwọn ẹhànnà ológbò wọ̀nyí wáá ń pa irú ọ̀wọ́ 64 ẹranko afọ́mọlọ́mú ìbílẹ̀ Australia jẹ báyìí. Pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ pupa tí a kó wọlé láti ilẹ̀ Europe, wọ́n ń gbógun ti àṣẹ́kù àwọn irú ọ̀wọ́ tí a ń wu léwu.

Ìkọlù Tààràtà

Ọdẹ ṣíṣe kì í ṣe ohun tuntun. Àkọsílẹ Bíbélì nínu Jẹ́nẹ́sísì ṣàpèjúwe Nímírọ́dù ọlọ̀tẹ̀, ọdẹ kan tí ó gbé ayé ní èyí tí ó lé ni 4,000 ọdún sẹ́yìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kò mẹ́nu bà á pé ó pa odindi irú ọ̀wọ́ run, síbẹ̀síbẹ̀ ó jẹ́ apániláyà, olùgbé iṣẹ́ ọdẹ lárugẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 10:9.

La àwọn ọ̀rúndún já, àwọn ọdẹ́ ti pa àwọn kìnnìún Gíríìsì àti Mesopotámíà, àwọn erinmi Nubia, àwọn erin Àríwá Áfíríkà, àwọn béárì àti ẹranko beaver ní Britain, àti àwọn akọ màlúù tí a kò fi dọ́sìn ní Ìlà Oòrun Europe, ní àparun. Ìwé ìròyin Radio Times tí BBC fi ń tọ́jú àkọsílẹ̀ ròyìn pé: “Láàárín àwọn ọdún 1870 sí àwọn ọdún 1880, àwọn ọdẹ́ pa ìdá mẹ́rin mílíọ̀nù erin ní Ìlà Oòrun Áfíríkà nìkan. Fún ìlàjì ọ̀rúndún kan, a ń gbọ́ ìró ìbọn àwọn ènìyàn olókìkí, ọlọ́lá àti onípò, tí ń pa àwọn erin, àwọn ẹranko rhino, àgùnfọn, àwọn ẹran ìjà ńláńlá àti ohunkóhun mìíràn tí wọ́n bá rí ní Áfíríkà. . . . Ohun tí ó jọ pé ó ń múni gbọ̀n rìrì lónìí ṣètẹ́wọ́gbà lódindi gan-an nígbà yẹn.”

Kí á padà sórí ipò ẹkùn ọlọ́lá ńlá. Kíka iye wọn ní àwọn ọdún 1980 fi hàn pé àwọn ìsapá ìdáàbò bò ti kẹ́sẹ járí. Ìwe 1995 Britannica Book of the Year ṣàkíyèsí pé: “Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀ràn kò rí bí ó ti jọ pé ó rí. Fífara balẹ̀ kà wọ́n fi hàn pé àwọn òṣìṣẹ́ tí ó kà wọ́n ní ìṣáájú ti bù kún iye tí wọ́n kà, bóyá nítorí pé wọ́n bá àwọn apẹran láìgbàṣẹ dì í, tàbí wọ́n wulẹ̀ ń fẹ́ láti wú àwọn ọ̀ga wọn lórí. . . . Òwò abẹ́lẹ̀ tí a ń fi àwọn ẹ̀yà ara ẹkùn ṣe ń gbèrú bí ìpèse wọn tí ń lọ sílẹ̀ ṣe túbọ̀ ń mú kí iye owó wọ́n ga sí i.” Nípa bẹ́ẹ̀, ní 1995, ìdíyelé ẹkùn Siberia kán wà láàárín 9,400 dọ́là sí 24,000 dọ́là—rárá, ìyẹn kì í wulẹ̀ í ṣe fún awọ rẹ̀ tí ó níye lórí gan-an nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn egungun, ojú, irunmú, eyín, àwọn nǹkan inú, àti àwọn ẹ̀yà ìbímọ, tí gbogbo wọ́n níye lórí gan-an nínú ìṣègùn ìbílẹ̀ ti ìhà Ìlà Oòrùn.

Ìwé ìròyin Time ṣàkíyèsí pé òwò eyín erin, ìwo ẹranko rhino, awọ ẹkùn, àti àwọn ẹ̀yà ara ẹranko mìíràn jẹ́ òwo fàyàwọ́ olówó gọbọi, tí ó pawọ́ lé fàyàwọ́ oògùn líle. Kò sì mọ sórí àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú ńláńlá nìkan. Ní 1994, egbòogi ìṣègùn ìbílẹ̀ China nìkán gba 20 mílíọ̀nù ẹṣin òkun, tí ó mú kí iye tí a rí pa ní àwọn agbègbè kan ní Gúúsù Ìlà Oòrun Éṣíà lọ sílẹ̀ ní nǹkan bí ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún láàárín ọdún méjì.

Kò ṣòro láti mọ ẹni tí a lè dá lẹ́bi nígbà tí a bá dọdẹ pa irú ọ̀wọ́ kan run. Nígbà náà, àwọn tí ń rà wọ́n ńkọ́? A gbọ́ pé, ẹyẹ macaw tí a wu léwu, conure olómi wúrà, ń mú 500 dọ́là wọlé fún oníṣòwo fàyàwọ́ kan ní Brazil. Ṣùgbọ́n bí ó bá lọ tà á lẹ́yìn odi, ó ń jèrè ju ìlọ́po mẹ́ta àbọ̀ iye yẹn lọ.

Àwọn ogun àti ìyọrísí wọn, ògìdìgbó àwọn olùwá ibi ìsádi tí ń pọ̀ sí i, pa pọ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n ìbímọ tí ń ga sókè, ìbàyíkájẹ́ tí ń pọ̀ sí i, àti ìrìn àjò afẹ́ pàápàá, ń halẹ̀ mọ́ àwọn irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu. Àwọn afójúlóúnjẹ tí ń lo ọkọ̀ ojú omi àfẹ̀rọwà ń pa àwọn ẹja dolphin tí wọ́n ń dà riyẹ lọ láti wò lára, ariwo tí àwọn ọkọ̀ náà ń pa lábẹ́ omí sì lè ṣèpalára fún ìṣètò ẹlẹgẹ́ tí àwọn ẹja dolphin fi ń gbọ́ ìró.

Lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpèjúwe ìbàjẹ́ amúnisoríkọ́ tí ènìyàn ń fà yìí, o lè ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ni àwọn olùdáàbò bò ń ṣe láti dáàbò bo àwọn irú ọ̀wọ́ tí a ń wu léwu, báwo ni wọ́n sì ti kẹ́sẹ járí tó?’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn ewéko, ẹranko, ẹyẹ, ẹ̀dá afàyàfà, àti kòkòrò ń kú run bí ènìyán ṣe ń pa igbó run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́