Àwọn Ẹran Ìgbẹ́ Orí Ilẹ̀ Ayé Tí Ń Pòórá
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA
INÚ rẹ kò ha ń dùn láti rí àwọn ẹran ìgbẹ́ rírorò, lóòyẹ̀, kí o sì gbúròó wọn—ẹkùn kan, ẹja àbùùbùtán kan, tàbí ìnàkí kan bí? Láti sin ẹranko koala kan ńkọ́? Láti rí kí ilẹ̀ máa mì mọ́ ọ lẹ́sẹ̀ nígbà tí agbo ẹranko tí ó pọ̀ lọ débi tí ojú lè rí i mọ bá ń fẹsẹ̀ kilẹ̀ lọ ńkọ́? Bí ó ti wù kí ó rí, ó bani nínú jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ ènìyàn má lè gbádùn irú ìran arímálèlọ bẹ́ẹ̀—bí kò bá ṣe pé a lè ka ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí kan, ìwé kan, tàbí gọgọwú kọ̀ǹpútà kan sí ìran àrímálèlọ. Èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀?
Nítorí pé, bí o ti ń ka àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́ gan-an, ẹgbẹẹgbẹ̀rún irúgbìn àti ẹranko ni ó forí lé ọ̀nà àkúrun. Ọ̀mọ̀wé Edward O. Wilson, onímọ̀ nípa ohun alààyè kan ní Yunifásítì Harvard, fojú díwọ̀n rẹ̀ pé lọ́dọọdún, 27,000 irú ọ̀wọ́ ní ń kú run, tàbí irú ọ̀wọ́ mẹ́ta ní wákàtí kọ̀ọ̀kan. Ní ìwọ̀n àkúrun yìí, iye tí ó tó ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún irú ọ̀wọ́ tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lè kú run láàárín 30 ọdún. Ṣùgbọ́n ìwọ̀n àkúrun kò dúró sójú kan; pípọ̀ ló ń pọ̀ sí i. A retí pé nígbà tí ó bá fi di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tí ń bọ̀, ọgọ́rọ̀ọ̀rún irú ọ̀wọ́ ni yóò máa pòórá lójoojúmọ́!
Ẹranko rhinoceros dúdú ti ilẹ̀ Áfíríkà wà ní bèbè àkúrun. Pípẹran láìgbàṣẹ ti dín iye rẹ̀ kù láti 65,000 sí 2,500 láàárín àkókò tí kò tó 20 ọdún. Àwọn elégbèdè tó ṣẹ́ kù sí àwọn ìgbẹ́ Borneo àti Sumatra tí ń joro náà kò tó 5,000 mọ́. Ìparun náà tún ti kan àwọn ẹ̀dá inú omi. Ẹja òbéjé ọlọ́láńlá tí a ń pè ní baiji ti Odò Yangtze ní China ti fara gbá a. Ìbàyíkájẹ́ àti pípẹja-nípakúpa ti mú kí wọ́n ṣẹ́ ku nǹkan bí ọgọ́rùn-ún péré, gbogbo wọn sì lè kú láàárín ẹ̀wádún kan.
Nínú ìwé Zoo Book, Linda Koebner sọ pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti onírúurú ẹ̀ka kò fohùn ṣọ̀kan lórí ọ̀pọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan lórí ìjẹ́kánjúkánjú dídáàbò bo àwọn irú ọ̀wọ́ àti lórí ìlera àdánidá pílánẹ́ẹ̀tì náà pé: Àádọ́ta ọdún tí ń bọ̀ yí ṣe kókó gan-an.”
Ta Ló Lẹ̀bi?
Iye ẹ̀dá ènìyàn tí ń pọ̀ sí i ń mú kí ìwọ̀n àkúrun náà yára pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n a kò lè di gbogbo ẹ̀bi náà ru àkúnya iye ènìyàn nìkan. Ọ̀pọ̀ ẹ̀dá—ẹyẹlé aláṣìíkiri, ẹyẹ moa, ẹyẹ òkun auk ńlá, ẹranko thylacine, ká wulẹ̀ dárúkọ díẹ̀—ti kú run tipẹ́tipẹ́ kí iye ẹ̀dá ènìyàn fúnra rẹ̀ tó di eléwu. Ọ̀mọ̀wé J. D. Kelly, olùdarí Ìgbìmọ̀ Alábòójútó Àwọn Ọgbà Ẹranko ti New South Wales, Australia, sọ nípa àkójọ àkọsílẹ̀ tí orílẹ̀-èdè náà ní pé: “Ìpàdánù ìjónírúurú ohun alààyè láti ìgbà ìtẹ̀dó ní 1788 jẹ́ ìtìjú fún àpapọ̀ orílẹ̀-èdè.” Láìsíyèméjì, àkíyèsí yìí jẹ́ òtítọ́ nípa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè míràn. Ó tún dọ́gbọ́n fi hàn pé àwọn ohun bíburú jù míràn tún wà tí ń fa àkúrun—àìmọ̀kan àti ìwọra.
Nítorí ìṣòro àkúrun tó kárí ayé náà, onígbèjà tuntun kan, tí kò láyọ̀lé, ti gbapò iwájú ní gbígbèjà àwọn ẹranko tí ń kojú àríyànjiyàn náà—àwọn ọgbà ẹranko. Lọ́nà tí ó túbọ̀ ń pọ̀ sí i, àwọn àhámọ́ àárín ìgboro wọ̀nyí ni ibi ààbò ìkẹyìn fún irú ọ̀wọ́ púpọ̀. Ṣùgbọ́n àyè tí àwọn ọgbà ẹranko ní mọ níwọ̀n, sísin àwọn ẹran ìgbẹ́ ń náni lówó, ó sì ṣòro. Ọ̀ràn ẹ̀tọ́ ìwà híhù lórí híhá wọn mọ́ tún wà níbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ lọ́nà onípẹ̀lẹ́tù. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà tí àwọn ẹran ìgbẹ́ wọ̀nyí bá wà nínú ọgbà, wọ́n gbára lé ìwà ọ̀làwọ́ ìṣúnná owó ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn ìgbékalẹ̀ ìṣèlú àti ìṣúnná tí kò ní láárí, tí ó sì ń yí pa dà lọ́pọ̀ ìgbà. Nítorí náà, báwo ni àwọn olùwá ibi ìsádi láti inú ìgbẹ́ wọ̀nyí ṣe láàbò tó ní gidi?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Àkúrun Ha Jẹ́ Àdánidá Bí?
“Àkúrun kì í ha ṣe ara ìṣètò àdánidá fún àwọn nǹkan bí? Ìdáhùn náà ni pé, bẹ́ẹ̀ kọ́, ó kéré tán, kì í ṣe ní ìwọ̀n tí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn àkókò lọ́ọ́lọ́ọ́ wọ̀nyí. Láàárín ọ̀pọ̀ jù lọ nínú 300 ọdún tí ó kọjá, àwọn irú ọ̀wọ́ ti kú run ní ìwọ̀n nǹkan bí ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́dọọdún. Ní báyìí, ó kéré tán, ìwọ̀n tí ẹ̀dá ènìyàn ń fà nínú àkúrun àwọn irú ọ̀wọ́ pọ̀ ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún sí ìyẹn. . . . Ohun tí ó fa ìyárakánkán yìí nínú ìwọ̀n àkúrun náà ni àwọn ìgbòkègbodò ẹ̀dá ènìyàn.”—The New York Public Library Desk Reference.
“Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀dá àrà ọ̀tọ̀ tó ti kú run ti fà mí lọ́kàn mọ́ra, kíkú tí wọ́n kú run sì bà mí nínú jẹ́, ó ń bí mi nínú lọ́pọ̀ ìgbà. Nítorí pé nínú ọ̀ràn púpọ̀ jù lọ, Ènìyàn ló ti jẹ́ okùnfà àkúrun wọ̀nyí ní tààrà tàbí láìṣetààrà, nípasẹ̀ ìwọra tàbí ìwà òǹrorò, àìbìkítà tàbí ìdágunlá.”—David Day, The Doomsday Book of Animals.
“Ìgbòkègbodò ẹ̀dá ènìyàn ló ń fa kíkú tí àwọn irú ọ̀wọ́ ń kú run kí wọ́n tó wọnú àkọsílẹ̀.”—Biological Conservation.