Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu—Bí Ó Ṣe Kàn Ọ́
ÀWỌN ẹkùn, ìjàpá, ẹranko rhino, labalábá—họ́wù, ó jọ pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ orúkọ àwọn irú ọ̀wọ́ tí a ń wu léwu kò lópin! Láìsí iyè méjì, ìwọ yóò gbà pé ènìyán ní láti gba púpọ̀ lára ẹ̀bi náà. Ṣùgbọ́n báwo ni èyí ṣe kàn ọ́?
Lójú àwọn ìṣòro ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé, ó ha bọ́gbọ́n mu láti retí pé kí àwọn ènìyàn tí ire ara wọ́n jẹ lọ́kàn máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìwéwèé ìdáàbòbò, bí ó ti wù kí àwọn ìwéwèé náà ó gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ tó? Ìwé ìròyin Time sọ pé: “Kò rọrùn láti ṣètìlẹ́yìn fún ọ̀ràn àyíká ní àwọn agbègbè púpọ̀ jù lọ ní apá ìsàlẹ Sahara ní Áfíríkà, níbi tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyán ti ń dojú kọ rúkèrúdò ìṣèlú, ogun ẹ̀yà ìran, ìyàn àti àrùn àjàkálẹ̀.” Bákan náà ló rí ní àwọn ibòmíràn.
Àwọn ìyípadà tegbòtigaga pọn dandan bí a óò bá yanjú ìṣòro àwọn irú ọ̀wọ́ tí a ń wu léwu. Gẹ́gẹ́ bí ìwe The Atlas of Endangered Species ṣe sọ, àwọn ìyípadà wọ̀nyí “tóbi tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé àwọn ìjọba nìkan ni wọ́n lè ṣe wọ́n.” Ó wáá dámọ̀ràn pé: “Níbi tí a bá ti ń dìbò yan àwọn ìjọba, ó jẹ́ ẹrù iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan láti rí i dájú pé, nígbà tí ó bá fi di ọdún 2000, kìkì àwọn òṣèlú tí ọ̀ràn àyíká jẹ lọ́kàn nìkan ni a ń dìbò yàn.”
Ìfojúsọ́nà tí ọwọ́ lè tẹ̀ ni èyí bí? Bí a bá fi ojú ẹ̀rí tí ìtàn ń jẹ́ wò ó, a gbọ́dọ̀ parí èrò sí pé “ẹnì kan ń ṣe olórí ẹnì kejì fún ìfarapa rẹ̀,”—àti ohun alààyè tí a kò fi dọ́sìn pẹ̀lú. (Oníwàásù 8:9) Láìṣe àní-àní, ọ̀pọ̀ àwọn olùdáàbòbó gbà gbọ́ pé ohun ọ̀gbìn àti ẹranko ilẹ̀ ayé jẹ́ atọ́ka àyíká. Nígbà tí a bá ń wu wọ́n léwu, a ń wu àwa ẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú léwu. Ṣùgbọ́n èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn tí a ń fi àkúrun halẹ̀ mọ́ gbogbo ohun alààyè orí ilẹ̀ ayé.
Ìwé ìtàn tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Wò ó, èmí ń mú kíkún omi bọ̀ wá sí ayé, láti pa gbogbo ohun alààyè run, tí ó ní ẹ̀mí ààyè nínú kúrò lábẹ́ ọ̀run; ohun gbogbo tí ó wà ní ayé ni yóò sì kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:17) Síbẹ̀síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tàbí gbogbo oríṣi ohun alààyè míràn ni ó kú, nítorí pé Ọlọ́run ṣètò ọ̀nà kan fún lílà á já.
Ọkọ̀ Kan fún Lílà Á Já
Àwọn onímọ sáyẹ́ǹsí gbà gbọ́ pé ojútùú dídára jù lọ sí ìṣòro irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu lónìí ní í ṣe pẹ̀lu dídáàbò bo ibùgbé àdánidá wọn. Ó dùn mọ́ni pé ìwé ìròyin New Scientist ròyìn lórí èyí, ó sì tọ́ka sí bí àwọn olùdáàbòbó ṣe ń lo “àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ Ọkọ̀ Nóà.” Ọkọ̀ Nóà ni ọ̀nà náà tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn ẹrankó gbà la Àkúnya ọjọ́ Nóà já.
Ọlọ́run fún Nóà ní àpèjúwe iṣẹ́ ọnà ọkọ̀ náà, àpótí onígi kíkàmàmà kan, tí yóò léfòó lójú omi àkúnya náà. Èyí dáàbò bo ìwàláàye Nóà, aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin wọn mẹ́ta àti àwọn aya àwọn ọmọkùnrin náà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣojú àwọn onírúurú oríṣiríṣi ẹranko, àwọn tí a kò fi dọ́sìn àti àwọn tí a fi dọ́sìn—ní tòótọ́, “ẹ̀dá gbogbo, nínú èyí tí ẹ̀mí ìyé wà.” (Jẹ́nẹ́sísì 7:15) Ògìdìgbó àwọn onírúurú ohun alààyè tí ó wà lónìí jẹ́rìí sí bí ọkọ̀ yẹ́n ṣe kájú ète rẹ̀ tó.
Bí ó ti wù kí ó rí, ṣàkíyèsí pé lílà á já kò sinmi ní pàtàkì lórí àwọn ìsapá ènìyàn. Nóà àti ìdílé rẹ̀ ní láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run, tí ó ní agbára láti pa wọ́n mọ́ láàyè. Ọlọ́run ni ó fòpin sí awuyewuye, ìwà ipá, àti ìwọra tí ó jẹ́ àbùdá ayé tí ó wà ṣáájú Àkúnya yẹn.—Pétérù Kejì 3:5, 6.
Àwọn Ẹranko Nínú Ayé Tuntun Náà
Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí pé ìgbọràn sí àwọn òfin rẹ̀ lè yí àwọn ẹ̀dá ènìyàn padà láti ipò bíi ti àwọn ẹranko ẹhànnà, afẹranṣèjẹ tí ń pẹran dànù, sí jíjọ àwọn ẹranko oníwà tútù, aṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́. (Aísáyà 11:6-9; 65:25) Àní nísinsìnyí pàápàá, àwọn ẹ̀rí èyí pọ̀ yamùrá. Lọ sí àwọn ìpàdé nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítòsí rẹ, kí o sì fi ojú ara rẹ rí i. Bí Jèhófà bá lè ṣàṣeparí irú ìyípadà tegbòtigaga bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀dá ènìyàn, kì yóò ha lè ṣètò fún àwọn ẹranko láti gbé pọ̀ ní àlàáfíà àti ààbò, àní bí èyí bá tilẹ̀ túmọ̀ sí yíyí àwọn àbùda wọn òde òní padà bí? Ní tòótọ́, ó ṣèlérí pé: “Ní ọjọ́ náà ni èmi ó sì fi àwọn ẹranko ìgbẹ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, àti ohun tí ń rákò lórí ilẹ̀ dá májẹ̀mú fún wọn, . . . èmi ó sì mú wọn dùbúlẹ̀ ní àìléwu.”—Hosea 2:18.
Àpọ́sítélì Pétérù kọ nípa “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run,” tí ó wà níwájú. (Pétérù Kejì 3:7) Ìdásí aláàlà tí Ọlọ́run yóò mú wá yóò pa kìkì àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run run. Ọlọ́run yóò “mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bàjẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.”—Ìṣípayá 11:18.
Finú wòye bí yóò ṣe jẹ́ ohun ìdùnnú tó láti gbé nínú ayé kan, níbi tí àwọn ẹ̀dá kò ti ní í sí lábẹ́ ìwuléwu mọ́. Ẹ wo bí ohun tí a óò ní láti kọ́ lára àwọn ohun alààyè tí a kò fi dọ́sìn tí yóò yí wa ká nígbà náà yóò ṣe pọ̀ tó! Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ẹkùn, kìnnìún, erin, yóò máa káàkiri láìsí ìdíwọ́ kankan. Àwọn ohun alààyè inú òkun yóò pọ̀ gidigidi, bí àwọn ẹ̀dá afàyàfà, kòkòrò, àti onírúurú àwọn ẹyẹ, títí kan àwọn ẹyẹ macaw yóò ti pọ̀ yanturu—bí ó ṣe yẹ kí ó rí gan-an. Pẹ̀lú aráyé onígbọràn tí a dá padà sí ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà, ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn lọ́nà pípé yóò gbilẹ̀.