ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 11/1 ojú ìwé 15-21
  • Ẹkọ-iwe Pẹlu Ète Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹkọ-iwe Pẹlu Ète Kan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjáfáfá Ni A Nilo Lati Di Ojiṣẹ Ti Ó Gbéṣẹ́
  • Awọn Anfaani Nínímọ̀-ẹ̀kọ́ Tí Ó Jíire
  • Ẹkọ-iwe Tí Ó Pọ̀ Tó
  • Oju-iwoye Gígúnrégé Nipa Ẹkọ-iwe
  • Ṣíṣírò Iye Ti Yoo Náni
  • Awọn Ọmọwe Eniyan, ti Wọn Sopọṣọkan
  • Bíbélì Ha Ṣàìfún Ẹ̀kọ́ Ìwé Níṣìírí Bí?
    Jí!—1998
  • Ojú Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wo Ẹ̀kọ́ Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́—Lò Ó Láti Yin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ǹjẹ́ ó Yẹ Kí Ọmọ Mi Lọ Sílé Ẹ̀kọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 11/1 ojú ìwé 15-21

Ẹkọ-iwe Pẹlu Ète Kan

“Fi [ìmọ̀, “NW”] fun ọlọgbọ́n eniyan, yoo sì maa gbọ́n siwaju.”—OWE 9:9.

1. Ki ni Jehofa reti lati ọ̀dọ̀ awọn iranṣẹ rẹ̀ nipa ìmọ̀?

JEHOFA ni “Ọlọrun olùmọ̀.” (1 Samueli 2:3) Ó ń kọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀. Mose sọtẹlẹ pe awọn eniyan ti wọn walaaye nigba naa lọhun-un yoo sọ fun Israeli pe: “Ọlọgbọ́n ati amòye eniyan nitootọ ni orilẹ-ede ńlá yii.” (Deuteronomi 4:6) Awọn Kristian tootọ bakan-naa nilati jẹ́ ẹni ti o ni ìmọ̀. Wọn nilati jẹ́ akẹkọọ titayọ ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ní fifi ète iru ikẹkọọ bẹẹ hàn, aposteli Paulu kọwe pe: “Awa . . . kò sinmi lati maa gbadura ati lati maa bẹ̀bẹ̀ fun yin pe ki ẹyin ki o lè kún fun [ìmọ̀ pípéye, NW] ifẹ rẹ̀ ninu ọgbọ́n ati ìmòye gbogbo tíí ṣe ti ẹmi; ki ẹ lè maa rìn ní yíyẹ niti Oluwa sí ìwù gbogbo, ki ẹ maa so eso ninu iṣẹ rere gbogbo, ki ẹ sì maa pọ̀ sii ninu [ìmọ̀ pípéye, NW] Ọlọrun.”—Kolosse 1:9, 10.

2. (a) Ki ni ó pọndandan ki a baa lè gba ìmọ̀ pipeye nipa Ọlọrun? (b) Bawo ni Ẹgbẹ́ Oluṣakoso ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe bojuto ọ̀ràn yii?

2 Ikẹkọọ pẹlu èrò gbigba ìmọ̀ pípéye nipa Ọlọrun ati awọn ète rẹ̀ beere fun ó keretan ìwọ̀n ẹkọ-iwe kikere julọ. Ṣugbọn ọpọlọpọ eniyan ti wọn ti wá mọ otitọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń gbé ni awọn orilẹ-ede nibi ti wọn ti ní anfaani ti kò tó nǹkan tabi ki o má tilẹ sí rara lati gba ẹkọ-iwe ayé tí ó jíire. Eyi fi wọn si ipo ti kò dara tó. Lati borí iṣoro yii, Ẹgbẹ Oluṣakoso ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti funni ni itọni fun ọpọlọpọ ọdun nisinsinyi pe, nibi ti ó bá ti pọndandan, ile-ẹkọ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ni a nilati ṣeto laaarin ijọ. Ni ohun ti ó ju 30 ọdun lọ sẹhin, iwe irohin Brazil naa Diário de Mogi tẹ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan jade tí ó ni akọle naa “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Gbógun Ti Àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà.” Ó sọ pe: “Olukọni kan tí ó tootun bẹrẹ . . . lati fi suuru kọ́ awọn miiran lati mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. . . . Awọn ọmọ ile-ẹkọ naa, nitori ipo naa gan-an tí ń sún wọn gẹgẹ bi ojiṣẹ Ọlọrun, gbọdọ mú ìmọ̀ wọn gbèrú nipa èdè naa ki wọn baa lè sọ awọn ọ̀rọ̀-àwíyé.” Ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan ni gbogbo ayé ni o ti tipa bayii ṣeeṣe fun lati di akẹkọọ rere ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Wọn dáwọ́lé ẹkọ-iwe pataki yii pẹlu ète giga lọ́kàn.

Ìjáfáfá Ni A Nilo Lati Di Ojiṣẹ Ti Ó Gbéṣẹ́

3, 4. (a) Eeṣe ti awọn Kristian tootọ fi ni ọkàn-ìfẹ́ ninu ẹkọ-iwe? (b) Bawo ni ipo ọ̀ràn ti rí ni Israeli, ẹkọ-iwe ipilẹ wo ni ó sì jẹ́ kòṣeémánìí laaarin awọn ijọ wa lonii?

3 Awọn Kristian tootọ ni ọkàn-ìfẹ́ ninu ẹkọ-iwe, kìí ṣe nititori níní ìmọ̀ lasan, ṣugbọn ki wọn baa lè di iranṣẹ Jehofa tí ó tubọ gbéṣẹ́. Kristi fun gbogbo awọn Kristian ni iṣẹ-ijihin naa lati “sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, . . . ki ẹ maa kọ́ wọn lẹkọọ lati fiṣọra kiyesi ohun gbogbo ti mo ti palaṣẹ.” (Matteu 28:19, 20, NW) Lati kọ́ awọn ẹlomiran, awọn funraawọn gbọdọ kọ́kọ́ kẹkọọ, eyi sì ń beere fun ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ rere. Wọn gbọdọ ní agbara lati ṣayẹwo Iwe Mimọ tiṣọratiṣọra. (Iṣe 17:11) Lati mú iṣẹ-aṣẹ wọn ṣẹ, wọn tún nilati lè kàwé geerege.—Wo Habakkuku 2:2; 1 Timoteu 4:13.

4 Gẹgẹ bi a ti rí i ninu ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti iṣaaju, idi rere wà lati gbagbọ pe, ni gbogbogboo, awọn ọ̀dọ́ ni Israeli igbaani paapaa mọ bi a tií kà ati bi a tií kọ. (Onidajọ 8:14; Isaiah 10:19) Awọn Kristian ojiṣẹ lonii nilati kọ awọn akọsilẹ ti ó wà letoleto bi wọn ti ń jẹrii lati ile de ile. Wọn ń kọ lẹta, ń ṣe akọsilẹ ni awọn ipade, wọn sì ń kọ àlàyé ṣoki sẹ́bàá akojọpọ-ọrọ ikẹkọọ wọn. Gbogbo eyi ń beere fun ìfọwọ́kọ̀wé ti ó ṣeékà. Pípa awọn akọsilẹ mọ́ laaarin ijọ Kristian sọ ìmọ̀ ipilẹ nipa iṣiro di dandan ó keretan.

Awọn Anfaani Nínímọ̀-ẹ̀kọ́ Tí Ó Jíire

5. (a) Ki ni orisun ọ̀rọ̀ naa “ile-ẹkọ”? (b) Anfaani wo ni awọn ọ̀dọ́ nilati gbámú?

5 Lọna ti o fanilọkanmọra, ọ̀rọ̀ naa “ile-ẹkọ” wá lati inu ọ̀rọ̀ Griki naa skho·leʹ, eyi tí ó tumọ ni ipilẹ si “ọwọ́dilẹ̀” tabi lílo ìgbà ọwọ́ dilẹ̀ fun awọn igbokegbodo pataki kan, iru bii kikẹkọọ. Ó wá duro fun ibi ti a ti ń ṣe iru ikẹkọọ bẹẹ. Eyi fihàn pe, ni akoko kan, kìkì awọn awujọ ti wọn lanfaani—Greece ati ọpọ julọ awọn ilẹ miiran—ni ọwọ wọn dilẹ̀ lati kẹkọọ. Awujọ tí ń ṣiṣẹ ni gbogbogboo wà gẹgẹ bi alaimọkan. Lonii, ní ọpọ julọ awọn orilẹ-ede awọn ọmọde ati awọn ọ̀dọ́ eniyan ni a fun lakooko lati kẹkọọ. Awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí dajudaju nilati ra akoko anfaani pada lati di ẹni ti ó ni ìmọ̀ ati lati di iranṣẹ titootun ti Jehofa.—Efesu 5:15, 16.

6, 7. (a) Ki ni diẹ lara awọn anfaani níní ẹkọ-iwe ti ó jíire? (b) Ni awọn ọ̀nà wo ni kíkọ́ èdè ajeji lè gbà wulo? (c) Bawo ni ipo nǹkan ti rí lonii laaarin ọpọ awọn ọ̀dọ́ eniyan nigba ti wọn bá pari ile-ẹkọ?

6 Ipilẹ ìmọ̀ nipa ìtàn, geography [ẹ̀kọ́ nipa ayé ati gbogbo ohun ti ó wà ninu rẹ̀] imọ-ijinlẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ yoo jẹ ki awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí di ojiṣẹ ti o ní èrò gígúnrégé. Lilọ ti wọn lọ si ile-ẹkọ yoo kọ́ wọn ní kìí ṣe kìkì ọpọ kókó-ẹ̀kọ́ nikan ni ṣugbọn ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ pẹlu. Awọn Kristian tootọ kìí dawọ níní ìmọ̀ ati kíkẹ́kọ̀ọ́ duro nigba ti wọn bá fi ile-ẹkọ silẹ. Bi o ti wu ki o ri, ohun ti wọn bá rí fàyọ lati inu kíkẹ́kọ̀ọ́ wọn, yoo fi pupọpupọ sinmi lori mimọ bi a tií kẹkọọ. Nínímọ̀-ẹ̀kọ́ ayé papọ pẹlu ti ijọ lè ràn wọ́n lọwọ lati mú agbara ironu wọn dagba. (Owe 5:1, 2) Nigba ti wọn bá kàwé yoo tubọ lè ṣeeṣe fun wọn lati foyemọ ohun ti ó ṣe pataki, ohun ti ó yẹ ní kikiyesi ati kíkọ́ sórí.

7 Fun apẹẹrẹ, kìí ṣe pe kíkọ́ èdè ajeji kan yoo mú ki agbara ero-ori awọn ọ̀dọ́ dagbasoke nikan ni ṣugbọn yoo tun mú ki wọn tubọ wulo fun eto-ajọ Jehofa. Ninu diẹ lara awọn ẹ̀ka Watch Tower Society, ọpọ awọn arakunrin ti wọn jẹ ọ̀dọ́ ti rí i pe ó ṣanfaani lati lè sọ tabi ka èdè Gẹẹsi geerege. Ju bẹẹ lọ, gbogbo awọn Kristian ojiṣẹ nilati saakun lati mọ èdè àbínibí sọ ketekete. Ó jẹ́ ohun ti o yẹ lati ṣalaye ihinrere Ijọba naa lọna ṣiṣe kedere, ti o bá ọ̀nà ti a gbà ń sọ èdè mu. Awọn otitọ fihàn pe ninu ayé lonii, ọpọlọpọ awọn ọdọlangba nigba ti wọn bá ń pari ile-ẹkọ ṣì maa ń ní iṣoro ninu kíkọ ati kíkà lọna títọ́ ati ninu ṣiṣe iṣiro ti ó rọ̀ julọ paapaa; wọn sì ní kìkì ìmọ̀ ti kò já gaara nipa ìtàn ati geography.

Ẹkọ-iwe Tí Ó Pọ̀ Tó

8. Awọn ẹsẹ iwe mimọ wo ni wọn tanmọ́ kókó-ẹ̀kọ́ ti ẹkọ-iwe ayé ati agbara-iṣe ẹnikan lati ṣetilẹhin fun araarẹ̀?

8 Nitori naa, eyi jọbi akoko ti o baamu lati gbé iṣarasihuwa Kristian si ẹkọ-iwe ayé yẹwo. Awọn ilana Bibeli wo ni wọn tanmọ́ kókó-ẹ̀kọ́ yii? Lakọọkọ, ni ọpọ julọ awọn orilẹ-ede itẹriba bibojumu fun “Kesari” beere lọwọ awọn Kristian òbí lati rán ọmọ wọn lọ si ile-ẹkọ. (Marku 12:17; Titu 3:1) Niti awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí, ninu iṣẹ ile-ẹkọ wọn wọ́n nilati ranti Kolosse 3:23, eyi ti ó sọ pe: “Ohunkohun ti ẹyin bá ń ṣe, ẹ maa fi tọkantọkan ṣe é, gẹgẹ bii fun Oluwa, kìí sìí ṣe fun eniyan.” Ilana keji ti ó ní ninu ni pe awọn Kristian nilati lè ṣetilẹhin fun araawọn, àní bi wọn bá tilẹ jẹ́ ojiṣẹ aṣaaju-ọna alakooko kikun paapaa. (2 Tessalonika 3:10-12) Bi ó bá ti gbeyawo, ọkunrin kan nilati lè pese lọna bibojumu fun aya ati awọn ọmọ eyikeyii ti o lè bí, pẹlu iwọnba àlékún diẹ lati fifun awọn wọnni ti wọn ṣalaini ati lati fi ti iṣẹ iwaasu adugbo ati ti agbaye lẹhin.—Efesu 4:28; 1 Timoteu 5:8.

9, 10. (a) Ki ni itẹsi kan ti o farahan ni ọpọlọpọ ilẹ? (b) Ki ni ojiṣẹ aṣaaju-ọna kan lè gbeyẹwo gẹgẹ bi owó-iṣẹ́ kan ti ó pọ̀ tó?

9 Bawo ni ẹkọ-iwe tí Kristian ọ̀dọ́ kan nilo ki o baa lè bọwọ fun awọn ilana Bibeli wọnyi ki ó sì kaju awọn iṣẹ-aigbọdọmaṣe Kristian rẹ̀ ti nilati pọ̀ tó? Eyi yatọsira lati orilẹ-ede si orilẹ-ede. Bi o ti wu ki o ri, ó dabii ẹni pe itẹsi gbogbogboo ni ọpọ ilẹ ni pe ìwọ̀n ìmọ̀-ẹ̀kọ́ ti a nilo lati gba owó-iṣẹ́ ti ó jọjú ti ga sii nisinsinyi ju bi o ti rí ni iwọnba ọdun diẹ sẹhin lọ. Awọn irohin ti a rí gbà lati awọn ẹ̀ka Watch Tower Society ni awọn ibi ọtọọtọ ninu ayé fihàn pe, ni ibi pupọ ó ṣoro lati rí iṣẹ ti ó ní owó-iṣẹ́ ti ó jọjú lẹhin wiwulẹ pari ìwọ̀n nínímọ̀-ẹ̀kọ́ ti ó kere julọ ti ofin beere fun tabi ni awọn orilẹ-ede kan àní lẹhin pipari ile-ẹkọ giga paapaa.

10 Ki ni a ní lọ́kàn pẹlu “owó-iṣẹ́ ti ó jọjú”? Kò tọka si awọn iṣẹ olówó gọbọi. Iwe atumọ ede naa Webster’s Dictionary tumọ “jọjú” ni ayika-ọrọ yii gẹgẹ bii “pọ̀ tó, tẹnilọrun.” Ki ni a lè pè ni ohun ti ó “pọ̀ tó,” fun apẹẹrẹ, fun awọn wọnni ti wọn fẹ lati di ojiṣẹ aṣaaju-ọna ihinrere? Iru awọn bẹẹ ni gbogbogboo nilo iṣẹ́-àbọ̀ọ̀ṣẹ́ lati yẹra fun gbígbé “ẹrù-ìnira anánilówó” karí awọn arakunrin wọn tabi idile wọn. (1 Tessalonika 2:9, NW) Owó-iṣẹ́ wọn ni a lè pè ní eyi ti ó “pọ̀ tó,” tabi “tẹnilọrun,” bi iye ti wọn bá ń gbà bá fun wọn láàyè lati gbé lọna yiyẹ nigba ti ó ń fun wọn ni akoko ati okun ti ó pọ̀ tó lati ṣaṣepari iṣẹ-ojiṣẹ Kristian wọn.

11. Eeṣe ti awọn ọ̀dọ́ kan fifi iṣẹ-isin aṣaaju-ọna silẹ, ibeere wo ni a sì gbé dide?

11 Bawo ni ipo ọ̀ràn naa ti sábà maa ń rí lonii? A ti rohin rẹ̀ pe ni awọn orilẹ-ede kan ọpọ awọn ọdọlangba ti wọn ni èrò rere ti fi ile-ẹkọ silẹ lẹhin pipari ìwọ̀n ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kikere julọ ti a beere fun ki wọn baa lè di aṣaaju-ọna. Wọn kò ní iṣẹ́-òwò tabi awọn itootun ti ayé kankan. Bi awọn òbí wọn kò bá ràn wọ́n lọwọ, wọn nilati wá iṣẹ́-àbọ̀ọ̀ṣẹ́. Awọn kan ti nilati tẹwọgba iṣẹ ti ń beere pe ki wọn lo wakati gigun lati jẹ́ ki awọ kájú ìlù. Bi a ti tán wọn lókun nipa ti ara-ìyára, wọn fi iṣẹ-ojiṣẹ aṣaaju-ọna silẹ. Ki ni iru awọn bẹẹ lè ṣe lati ṣetilẹhin fun araawọn ki wọn sì pada sẹnu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna?

Oju-iwoye Gígúnrégé Nipa Ẹkọ-iwe

12. (a) Nipa ti ẹkọ-iwe, oju-iwoye rírékọjá-ààlà meji wo ni Kristian kan nilati yẹra fun? (b) Fun awọn iranṣẹ oluṣeyasimimọ ti Jehofa ati awọn ọmọ wọn, ète wo ni ẹkọ-iwe nilati ṣiṣẹ fun?

12 Oju-iwoye gígúnrégé nipa ẹkọ-iwe lè ṣeranwọ. Fun ọpọlọpọ ọ̀dọ́ eniyan ninu ayé, ẹkọ-iwe jẹ́ àmì ipo-ọla, ohun kan lati ràn wọn lọwọ lati gun àkàbà ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, kọkọrọ naa si ọ̀nà-ìgbésí-ayé aláásìkí, onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì. Fun awọn miiran, rírelé ẹ̀kọ́ jẹ́ iṣẹ kan ti kò gbadunmọni ti a nilati pari ni kiakia bi o bá ti le ṣeeṣe tó. Eyikeyii ninu awọn oju-iwoye yii kò tọna fun awọn Kristian tootọ. Ki ni, nigba naa, ni a lè pè ni “oju-iwoye gígúnrégé”? Awọn Kristian nilati ka ẹkọ-iwe si ọ̀nà àtirí iyọrisi kan. Ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi, ète wọn ni lati ṣiṣẹsin Jehofa gidigidi ati bi ó bá ti lè ṣeeṣe ki ó gbéṣẹ́ tó. Bi ó bá jẹ́ pe, ni orilẹ-ede nibi ti wọn ń gbé, ẹkọ-iwe mimọniwọn tabi ti ile-ẹkọ giga yoo wulẹ fun wọn láàyè kìkì lati wá iṣẹ ti ń pese owó tí ń wọlé ti kò tó lati ṣetilẹhin fun araawọn gẹgẹ bi aṣaaju-ọna, nigba naa ẹkọ-iwe afikun tabi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ni a lè gbeyẹwo. Eyi yoo jẹ́ pẹlu gongo pàtó ti iṣẹ-isin alakooko kikun.

13. (a) Bawo ni ó ṣe ṣeeṣe fun arabinrin kan ni Philippines lati maa ba iṣẹ-isin aṣaaju-ọna rẹ̀ lọ nigba ti ó ń kájú awọn iṣẹ-aigbọdọmaṣe idile rẹ̀? (b) Ikilọ wo ni o ṣe kòńgẹ́?

13 Awọn kan ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti o ti ṣí anfaani iṣẹ silẹ tí o sì ń mú ki o ṣeeṣe fun wọn lati lọwọ ninu tabi pada sẹnu iṣẹ-isin alakooko kikun. Arabinrin kan ni Philippines ni ó ń gbọ́ bùkátà idile, ṣugbọn ó fẹ́ lati ṣe aṣaaju-ọna. Ẹ̀ka naa rohin pe: “Ó ti ṣeeṣe fun un lati ṣe eyi nitori pe ó ti gba afikun ẹkọ-iwe lati tootun gẹgẹ bii olùṣèṣirò-owó ti o níwèé ẹ̀rí.” Irohin ẹ̀ka kan-naa sọ pe: “A ní ọpọ iye awọn ti wọn ń kẹ́kọ̀ọ́ ti wọn sì lè ṣeto itolẹsẹẹsẹ wọn lati ṣe aṣaaju-ọna lakooko kan-naa. Ni gbogbogboo wọn di akede sísàn jù gẹgẹ bi wọn ti jẹ́ ẹni ti ó tubọ nifẹẹ iwe kíkà, niwọn bi wọn kò bá ti di ẹni ti ó ni ifẹ àníjù ti o lagbara fun awọn ìlépa ayé.” Àlàyé-ọ̀rọ̀ ti ó gbẹhin yii nilati fun wa ni idi lati ronu síwá-sẹ́hìn. Ète títúbọ̀ relé ẹ̀kọ́ sii nibi ti eyi bá ti jọbi ohun ti ó pọndandan, ni a kò gbọdọ gbagbe tabi yipada si gongo ti ifẹ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì.

14, 15. (a) Eeṣe ti a kò fi lè ṣe ilana ti kò ṣeé yipada nipa ẹkọ-iwe? (b) Ẹkọ-iwe ayé wo ni awọn arakunrin kan ti wọn ní ẹrù-iṣẹ́ ti gbà, ṣugbọn ki ni ó ti rọ́pò eyi?

14 Ni awọn orilẹ-ede diẹ, ile-ẹkọ girama pese ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àfiwọṣẹ́ ti ó lè mura Kristian ọ̀dọ́ kan silẹ fun iṣẹ́-òwò tabi iṣẹ-àjókòótì nigba ti ó bá fi maa di ìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́yege. Àní nigba ti ọ̀ràn kò bá rí bi eyi paapaa, ni awọn ilẹ̀ kan awọn ọ̀dọ́langba ti wọn jẹ́ alákíkanjú ti wọn ní kìkì ẹkọ-iwe ti o ṣekoko maa ń rí iṣẹ́-àbọ̀ọ̀ṣẹ́ ti ń fun wọn láàyè lati rí owó tí ó tó gbà lati ṣe aṣaaju-ọna. Nitori naa kò sí ilana ti kò ṣeé yipada ti a nilati ṣe yala ni itilẹhin fun tabi lodisi àníkún ẹkọ-iwe.

15 Ọpọlọpọ tí ń ṣiṣẹsin nisinsinyi ninu awọn ipo ẹrù-iṣẹ́ gẹgẹ bi alaboojuto arinrin-ajo, ni orile-iṣẹ Society, tabi ni ọ̀kan lara awọn ẹ̀ka ní kìkì ẹkọ-iwe ti o ṣekoko. Wọn jẹ́ aṣaaju-ọna oluṣotitọ, wọn kò dáwọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ duro, wọn ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́, a sì ti gbé ẹrù-iṣẹ́ titobi ju lé wọn lọwọ. Wọn kò kábàámọ̀. Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, diẹ lara awọn ẹlẹgbẹ wọn yàn lati gba ẹkọ-iwe yunifasiti wọn sì ṣubu kuro loju ọ̀nà, awọn ọgbọ́n-ìmọ̀-ọ̀ràn ati “ọgbọ́n ayé yii” tí ń pa igbagbọ run ti bori wọn.—1 Korinti 1:19-21; 3:19, 20; Kolosse 2:8.

Ṣíṣírò Iye Ti Yoo Náni

16. (a) Ta ni ń pinnu yala ẹkọ-iwe siwaju sii dara, kí sì ni a nilati fi si ọkàn julọ? (b) Ki ni a nilati gbayẹwo?

16 Ta ni yoo pinnu yala Kristian ọ̀dọ́ kan nilati dawọle ẹkọ-iwe tabi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ siwaju sii? Nibi yii gan-an ni ọ̀ràn ti kan ilana Bibeli nipa ipò-orí. (1 Korinti 11:3; Efesu 6:1) Lori ipilẹ yii awọn òbí dajudaju yoo fẹ́ lati tọ́ awọn ọmọ wọn sọna ninu yíyan iṣẹ́-òwò tabi iṣẹ́-àjókòótì kan ati fun idi eyi iye ẹkọ-iwe ti wọn yoo nilo. Ni ọpọlọpọ orilẹ-ede awọn yíyàn ẹkọ-iwe ati ti iṣẹ́-àjókòótì ni a nilati ṣe ni kutukutu ni akoko ẹkọ-iwe girama. Iyẹn ni akoko ti awọn Kristian òbí ati awọn ọ̀dọ́ nilati wá idari Jehofa ninu ṣiṣe yíyàn ti ó lọ́gbọ́n, pẹlu awọn ire Ijọba ni ipo iwaju julọ lọ́kàn. Awọn ọ̀dọ́ eniyan ní ìtẹ̀sí àdánidá ati agbara-iṣe àdánidá ọtọọtọ. Awọn ọlọgbọn òbí yoo gbé iwọnyi yẹwo. Gbogbo iṣẹ ailabosi jẹ́ ọlọ́lá, ìbáà jẹ́ ti iṣẹ́-òpò aláfọwọ́ṣe tabi ti onígègé. Nigba ti ayé lè gbé iṣẹ ọfiisi larugẹ ki wọn sì bẹ̀tẹ́lu ṣiṣiṣẹ kára pẹlu ọwọ́ ẹni, dajudaju Bibeli kò ṣe bẹẹ. (Iṣe 18:3) Nitori naa nigba ti awọn òbí ati awọn Kristian ọ̀dọ́ lonii, lẹhin fifi tiṣọratiṣọra ati taduratadura gbé anfaani ati àdánù yẹwo, bá pinnu ní itilẹhin tabi lodisi ikẹkọọ ti ó ju ti ile-ẹkọ girama lọ, awọn miiran ninu ijọ kò gbọdọ ṣàríwísí wọn.

17. Yíyàn wo ni awọn òbí Ẹlẹ́rìí kan ṣe fun awọn ọmọ wọn?

17 Bi awọn Kristian òbí bá fi ẹtọ wọn lati ṣe yiyan pinnu lati pese ẹkọ-iwe siwaju sii fun awọn ọmọ wọn lẹhin ile-ẹkọ giga, ẹ̀tọ́ tiwọn niyẹn. Akoko ikẹkọọ wọnyi yoo yatọsira ni ibamu pẹlu iru iṣẹ́-òwò tabi iṣẹ́-àjókòótì ti a yàn. Fun awọn idi ti o jẹ mọ iṣunna-owo ati ki ó baa lè ṣeeṣe fun awọn ọmọ wọn lati kowọnu iṣẹ-isin alakooko kikun ní kiakia bi o bá ti lè ṣeeṣe tó, ọpọlọpọ awọn Kristian òbí ti yan itolẹsẹẹsẹ ikẹkọọ onigba kukuru fun wọn ni awọn ile-ẹkọ àfiwọṣẹ́ ati ti iṣẹ́-ọwọ́. Ninu awọn ọ̀ràn kan awọn ọ̀dọ́ ti nilati jẹ́ ọmọ-ẹ̀kọ́ṣẹ́ nidii iṣẹ́-òwò kan ṣugbọn niye ìgbà pẹlu igbesi-aye kikun ti iṣẹ-isin si Jehofa gẹgẹ bii gongo.

18. Bi a bá ṣe afikun itolẹsẹẹsẹ ẹ̀kọ́, ki ni a nilati fi sọ́kàn?

18 Bi o bá lọwọ ninu awọn itolẹsẹẹsẹ afikun ẹ̀kọ́, dajudaju isunniṣe naa kò níí jẹ́ lati gbé ẹkọ-iwe yọ tabi lati lakaka fun iṣẹ igbesi-aye ti ayé ti o lọ́lá. Awọn itolẹsẹẹsẹ ẹ̀kọ́ ni a nilati fi iṣọra yàn. Iwe-irohin yii ti gbé itẹnumọ kari awọn ewu ti ẹ̀kọ́ giga, ó sì tọ́ bẹẹ, nitori àpọ̀jù ẹkọ-iwe giga tako “ẹ̀kọ́ afunni nilera” ti Bibeli. (Titu 2:1, NW; 1 Timoteu 6:20, 21) Siwaju sii, lati awọn ọdun 1960, ọpọlọpọ ile-ẹkọ ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìwé giga ti di ibi ti ó dẹjú fun iwa-ailofin ati iwa-palapala. “Ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa” ti fi tagbaratagbara ṣaifun wíwọnú iru ayika-ipo yẹn niṣiiri. (Matteu 24:12, 45, NW) A gbọdọ gbà, bi o ti wu ki o ri, pe lode ìwòyí awọn ọdọlangba ń dojukọ awọn ewu wọnyi kan-naa ni ile-ẹkọ ati awọn kọlẹẹji iṣẹ́-ọwọ́ ati ni awọn ibi iṣẹ paapaa.—1 Johannu 5:19.a

19. (a) Ki ni awọn wọnni ti wọn pinnu lati ṣe itolẹsẹẹsẹ ẹ̀kọ́ aláfikún nilati ṣọra fun? (b) Bawo ni awọn kan ṣe lo ẹkọ-iwe wọn lọna rere?

19 Bi ó bá nilati pinnu nipa afikun ẹkọ-iwe, ó dara ki ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan, bi ó ba ṣeeṣe, ṣe eleyii nigba ti ó wà ni ile, kí ó lè tipa bayii pa aṣa ikẹkọọ Kristian deedee, lílọ si awọn ipade, ati igbokegbodo iwaasu mọ́. Lati ibẹrẹ, iduro bibojumu ni o nilati mú fun awọn ilana Bibeli pẹlu. Ó gbọdọ ranti rẹ̀ pe Danieli ati awọn Heberu ẹlẹgbẹ rẹ̀ mẹta jẹ́ òǹdè ni igbekun nigba ti a sọ ọ́ di dandan fun wọn lati gba ikẹkọọ siwaju sii ni Babiloni, ṣugbọn wọn fi iṣedeedee délẹ̀ pa iwatitọ wọn mọ́. (Danieli, ori 1) Nigba ti wọn ń fi ire tẹmi si ipo akọkọ, awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ni ọpọ orilẹ-ede ti ń nawọ́gán itolẹsẹẹsẹ awọn ẹ̀kọ́ kíkọ́ ti ó lè mura wọn silẹ fun iṣẹ́-àbọ̀ọ̀ṣẹ́ gẹgẹ bii oluṣeṣiro-owo, ọkunrin olówò, olukọ, olutumọ, ògbùfọ̀ tabi ninu awọn iṣẹ́-àjókòótì miiran ti ó ń ṣetilẹhin fun wọn lọna ti ó pọ̀ tó ninu iṣẹ igbesi-aye wọn akọkọ ti ṣiṣe aṣaaju-ọna. (Matteu 6:33) Ọpọ awọn ọ̀dọ́ wọnyi ti di alaboojuto arinrin-ajo tabi oluyọnda ara-ẹni ni Beteli lẹhin naa.

Awọn Ọmọwe Eniyan, ti Wọn Sopọṣọkan

20. Itayọ ti ayé wo ni kò ní ààyè laaarin awọn eniyan Jehofa?

20 Laaarin awọn eniyan Jehofa, yala iṣẹ́-àjókòótì ẹnikan jẹ́ ti onígègé, aláfọwọ́ṣe, iṣẹ́-àgbẹ̀, tabi iṣẹ àgbàṣe, gbogbo wọn nilati jẹ́ olukọ ti ó gbéṣẹ́ ati akẹkọọ rere ninu Bibeli. Ìjáfáfá ti gbogbo wọn gbà ninu iwe kíkà, ẹ̀kọ́ kíkọ́, ati kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ni ó ṣeeṣe ki ó lé ìtayọ ti ayé ń fọ́nnu rẹ̀ laaarin awọn oṣiṣẹ aláfọwọ́ṣe ati ti ọfiisi lọ. Eyi ń yọrisi ìṣọ̀kan ati ọ̀wọ̀ tọ̀tún-tòsì ti o hàn kedere ni pataki laaarin awọn oṣiṣẹ oluyọnda ara-ẹni ni awọn ile Beteli ati ni awọn ibi ikọle Watch Tower Society, nibi ti awọn animọ tẹmi ti jẹ́ ohun ti ó ṣe pataki julọ ti a beere lọwọ gbogbo eniyan. Nihin-in, awọn oniruuru oṣiṣẹ ọfiisi ń fi tayọtayọ ṣiṣẹ pẹlu awọn ọ̀jáfáfá oṣiṣẹ àfọwọ́ṣe, ti gbogbo wọn ń fi ifẹ onimọriri hàn fun ẹnikinni keji.—Johannu 13:34, 35; Filippi 2:1-4.

21. Ki ni ó nilati jẹ́ ifojusọna awọn Kristian ọ̀dọ́?

21 Ẹyin òbí, ẹ tọ́ awọn ọmọ yin sọna siha gongo didi mẹmba wiwulo ti ẹgbẹ́ ayé titun! Ẹyin Kristian ọ̀dọ́, ẹ lo awọn anfaani ẹkọ-iwe yin gẹgẹ bi ọ̀nà àtimúra araayin silẹ lati tubọ gbá awọn anfaani yin ninu iṣẹ-isin Jehofa mú ni kikun! Gẹgẹ bi awọn ẹni ti a fun ni idalẹkọọ, ǹjẹ́ ki gbogbo yin jásí mẹmba ẹgbẹ́ ti iṣakoso Ọlọrun ti a ti murasilẹ daradara nisinsinyi ati titi ainipẹkun ninu “ayé titun” ti Ọlọrun ṣeleri.—2 Peteru 3:13; Isaiah 50:4; 54:13; 1 Korinti 2:13.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tún wo Ilé-Ìṣọ́nà ti May 1, 1976, oju-iwe 286 si 287.

Dán Agbara Iranti Rẹ Wò

◻ Eeṣe ti awọn Kristian tootọ fi ni ọkàn-ìfẹ́ ninu ẹkọ-iwe?

◻ Awọn oju-iwoye rírékọjá-ààlà meji wo nipa ẹkọ-iwe ni awọn Kristian tootọ yoo yẹra fun?

◻ Awọn ewu nipa afikun ẹkọ-iwe wo ni a nilati gbà rò, ki ni a sì nilati ṣọra fun?

◻ Itayọ wo ti o jẹ́ ti ayé ni kò ni ààyè kankan laaarin awọn eniyan Jehofa?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Nipa fifi taapọntaapọn kẹkọọ, awọn Kristian ọ̀dọ́ lè tubọ di mẹmba wiwulo ti ẹgbẹ́ ayé titun

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ẹkọ-iwe siwaju sii, bi a bá yàn án, ni ìfẹ́-ọkàn lati ṣiṣẹsin Jehofa lọna didara ju nilati súnniṣe

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́