Ojú Ìwòye Bíbélì
Bíbélì Ha Ṣàìfún Ẹ̀kọ́ Ìwé Níṣìírí Bí?
“Aláìmọ̀kan nìkan ní ń gan ẹ̀kọ́.”—Publilius Syrus, Moral Sayings, ti ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa.
BÍBÉLÌ rọ̀ wá láti “fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú.” (Òwe 3:21) Jèhófà, Ọlọ́run ìmọ̀, fẹ́ kí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. (1 Sámúẹ́lì 2:3; Òwe 1:5, 22) Síbẹ̀, àwọn gbólóhùn kan nínú Bíbélì lè gbé ìbéèrè dìde. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí àwọn ìlépa rẹ̀ àtijọ́, títí kan ẹ̀kọ́ gíga tí ó kọ́, ó kọ̀wé pé: “Mo ka gbogbo rẹ̀ sí pàǹtírí lásánlàsàn.” (Fílípì 3:3-8, Today’s English Version) Nínú lẹ́tà onímìísí mìíràn, ó tẹnu mọ́ ọn pé: “Ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ nǹkan òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 3:19.
Nígbà náà, Bíbélì ha ṣàìfún ẹ̀kọ́ ìwé níṣìírí ni bí? Báwo ló ṣe yẹ kí Kristẹni kan kàwé tó? Èyí tí òfin béèrè pé ó kéré jù ha tó bí, àbí ó ha yẹ kí a kàwé sí i bí?
Ẹ̀kọ́ Ìwé ní Ọ̀rúndún Kìíní
Láàárín àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, ẹ̀kọ́ ìwé tí àwọn ènìyàn ní yàtọ̀ síra. Àwọn gbajúmọ̀ ọkùnrin kan ka àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù tí wọ́n jẹ́ ará Gálílì sí “àwọn ènìyàn tí kò kàwé àti gbáàtúù.” (Ìṣe 4:5, 6, 13) Èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn ọkùnrin méjì wọ̀nyí jẹ́ púrúǹtù tàbí ẹni tí kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ni bí? Rárá. Ó wulẹ̀ túmọ̀ sí pé wọn kò kàwé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ti àwọn Hébérù tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn ìwé tí àwọn alágbàwí aláìfòyà ti ìsìn Kristẹni wọ̀nyí kọ wá jẹ́rìí sí òtítọ́ náà pé ẹni tó kàwé dáadáa, tí ó ní làákàyè, tí ó dáńgájíá nínú ṣíṣàlàyé Ìwé Mímọ́ lọ́nà tí ó yéni yékéyéké ni wọ́n. Wọ́n ti ní ẹ̀kọ́ ìwé tí ó kan ìtọ́ni tí ó gbéṣẹ́ nínú pípèsè àwọn ohun tí àwọn ìdílé wọn nílò ní ti ara. Alájọṣiṣẹ́ ni wọ́n nínú iṣẹ́ tí ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ òwò ẹja pípa tí ń mówó wọlé.—Máàkù 1:16-21; Lúùkù 5:7, 10.
Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, ọmọlẹ́yìn Lúùkù, tí ó kọ ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere àti ìwé Ìṣe, kàwé tí ó pọ̀ díẹ̀. Ó jẹ́ oníṣègùn kan. (Kólósè 4:14) Ìgbésí ayé àtilẹ̀wá rẹ̀ bí oníṣègùn jẹ́ kí ọ̀nà ìkọ̀wé onímìísí rẹ̀ dá yàtọ̀.—Wo Lúùkù 4:38; 5:12; Ìṣe 28:8.
Kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ó kẹ́kọ̀ọ́ òfin Júù, lábẹ́ àbójútó ọ̀kan lára àwọn ọ̀mọ̀wé tí ó ní làákàyè jù lọ nígbà náà, Gàmálíẹ́lì. (Ìṣe 22:3) A lè fi ẹ̀kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ́ wé ẹ̀kọ́ yunifásítì lónìí. Síwájú sí i, ní àwùjọ àwọn Júù, a kà á sí ohun ẹ̀yẹ fún àwọn ọ̀dọ́ láti kọ́ iṣẹ́ kan, kódà tí a bá ní láti lọ kàwé sí i ní ilé ẹ̀kọ́ gíga lọ́jọ́ iwájú. Ẹ̀rí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù kọ́ iṣẹ́ àgọ́ pípa nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́mọdé. Irú òye iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí ó lè ṣètìlẹ́yìn fún ara rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún rẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé bí a bá fi wé ìníyelórí gígadabú tí ìmọ̀ Ọlọ́run ní, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìwé—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ kòṣeémánìí—ní ìníyelórí tí ó láàlà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Bíbélì fi ìjẹ́pàtàkì gíga jù lọ sórí jíjèrè ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Kristi. Àwọn Kristẹni lónìí ṣe dáradára láti ṣàmúlò ojú ìwòye bíbọ́gbọ́nmu yìí nípa ẹ̀kọ́ ìwé.—Òwe 2:1-5; Jòhánù 17:3; Kólósè 2:3.
Ṣíṣàyẹ̀wò Ọ̀ràn Náà Tìṣọ́ratìṣọ́ra
Àwọn Kristẹni kan ti rí i pé kíkàwé sí i, yálà ní ti ẹ̀kọ́ ìwé tàbí ti ẹ̀kọ́ṣẹ́, ti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní pípèsè àwọn ohun ti ara tí ìdílé wọn nílò. Pípèsè fún ìdílé ẹni bẹ́tọ̀ọ́ mu, nítorí pé ‘pípèsè fún agbo ilé ẹni’ jẹ́ ojúṣe mímọ́. (1 Tímótì 5:8) Jíjèrè òye iṣẹ́ tí a nílò láti ṣe èyí jẹ́ ọ̀ràn ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí wọ́n ronú pé ó yẹ láti kà ju ìwé ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ lọ láti kájú ìlépa yìí gbọ́dọ̀ gbé àwọn àǹfààní àti ìpalára rẹ̀ yẹ̀ wò. Àwọn ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àǹfààní rẹ̀ ní nínú, mímúnigbáradì láti rí iṣẹ́ tí yóò jẹ́ kí a lè pèsè fún ara ẹni àti ìdílé kan lọ́nà tí ó tó bí a ti ń fi ìtara lépa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ní àfikún, ó lè ṣeé ṣe fún un láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ti ara, kí ‘ó ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.’—Éfésù 4:28.
Àwọn ohun díẹ̀ wo ló lè wá jẹ́ ìpalára rẹ̀? Ìwọ̀nyí lè ní nínú, dídi ẹni tí ń gba àwọn ẹ̀kọ́ tí ń ba ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Bíbélì jẹ́. Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn láti ṣọ́ra fún “ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀’” àti “ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn.” (1 Tímótì 6:20, 21; Kólósè 2:8) Lọ́nà tí kò ṣeé sẹ́, gbígba irú àwọn ẹ̀kọ́ kan lè ṣèpalára fún ìgbàgbọ́ Kristẹni kan. Àwọn tí wọ́n ń ronú nípa àfikún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tàbí ìwé gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa ewu tí ó wà nínú irú agbára ìdarí bẹ́ẹ̀.
Mósè, tí wọ́n “fún ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì,” rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ lílágbára bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, láìsí àní-àní, ó gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ní nínú, àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bọlá fún Ọlọ́run, tí ń fi ìgbàgbọ́ nínú ọ̀pọ̀ ọlọ́run kọ́ni. (Ìṣe 7:22) Bákan náà, àwọn Kristẹni lónìí ń lo ìṣọ́ra láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn ìdarí tí kò gbámúṣé nínú ipò èyíkéyìí tí wọ́n bá bá ara wọn.
Ewu mìíràn tí ó lè wá ṣẹlẹ̀ nínú kíkàwé sí i ni pé ìmọ̀ máa ń wú fùkẹ̀, tàbí ó máa ń múni gbọ́n lójú ara ẹni. (1 Kọ́ríńtì 8:1) Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lo ẹ̀kọ́ ìwé láti rí ìmọ̀ fún ìmọtara-ẹni-nìkan, kódà, fífi àìlábòsí wá ìmọ̀ lè yọrí sí níní ìmọ̀lára ìyọrí ọlá àti ìjọra-ẹni-lójú. Irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú.—Òwe 8:13.
Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn Farisí. Àwọn mẹ́ńbà ẹ̀ya ìsìn tí ó gbajúmọ̀ yìí ń gbé ara wọn ga látàrí ìmọ̀ àti òdodo tí wọ́n sọ pé àwọn ní. Wọ́n mọ àkójọ ńlá ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ìwé àwọn olùkọ́ ìsìn Júù dunjú, wọ́n sì ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn gbáàtúù ènìyàn, tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé, wọ́n sì ń wò wọ́n bí aláìmọ̀kan, ẹni ẹ̀sín, kódà ẹni ègún. (Jòhánù 7:49) Ní àfikún sí èyí, wọ́n fẹ́ràn owó. (Lúùkù 16:14) Àpẹẹrẹ wọn fi hàn pé bí a bá lọ kàwé sí i nítorí ìsúnniṣe tí kò dára, ó lè mú kí ẹnì kan gbéra ga tàbí kí ó sún un di olùfẹ́ owó. Nítorí náà, ní pípinnu irú ẹ̀kọ́ tí a óò lépa àti bí yóò ṣe pọ̀ tó, yóò dára kí Kristẹni kan bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Kí ní ń sún mi sí i?’
Ọ̀ràn Yíyàn Ti Ara Ẹni
Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ òtítọ́ ní ọ̀rúndún kìíní, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìwé tí àwọn Kristẹni ní kò dọ́gba lónìí. Lábẹ́ ìdarí àwọn òbí wọn, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n parí ẹ̀kọ́ tí òfin fi dandan lé lè yàn láti kàwé sí i. Bákan náà, àwọn àgbàlagbà tí wọ́n lọ́kàn ìfẹ́ nínú mímú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà pèsè fún ìdílé wọn sunwọ̀n lè wo irú àfikún ẹ̀kọ́ ìwé bẹ́ẹ̀ bí ọ̀nà gbígbéṣẹ́ láti dójú ìwọ̀n yẹn.a Àwọn apá kan ẹ̀kọ́ ìwé tí ó wọ́pọ̀ tẹnu mọ́ níní agbára òye lápapọ̀ dípò òye iṣẹ́ àmọ̀dunjú tàbí ti ẹ̀kọ́ṣẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹnì kan lè rí i pé òun kò ní òye tí òun fi lè rí iṣẹ́ ṣe bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ti lo àkókò púpọ̀ láti kọ́ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. Nítorí ìdí yìí, àwọn kan yàn láti kọ́ ẹ̀kọ́ nínú àwọn ìṣètò ẹ̀kọ́ṣẹ́ tàbí ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́, pẹ̀lú èrò kíkúnjú àwọn ohun tí a ń béèrè fún ní ti gidi lágbo ìgbanisíṣẹ́.
Bí ó ti wù kí ó rí, irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti ara ẹni. Kò yẹ kí àwọn Kristẹni ṣe àríwísí ẹlòmíràn tàbí kí wọ́n dẹ́bi fún wọn lórí ọ̀ràn yìí. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ta ni ọ́ tí o fi ní láti máa ṣèdájọ́ aládùúgbò rẹ?” (Jákọ́bù 4:12) Bí Kristẹni kan bá ń ronú nípa kíkàwé sí i, yóò dára kí ó gbé ìsúnniṣe tirẹ̀ yẹ̀ wò kí ó lè rí i dájú pé àwọn ọkàn ìfẹ́ onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì, tí ó jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan kọ́ ló ń ti òun sí i.
Ó hàn gbangba pé Bíbélì fún ojú ìwòye títọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ níṣìírí. Àwọn òbí Kristẹni mọ ìníyelórí títayọ tí ó wà nínú ẹ̀kọ́ tẹ̀mí tí a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó ní ìmísí, wọ́n sì ń fún àwọn ọmọ wọn ní àmọ̀ràn tí ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa àfikún ẹ̀kọ́ ìwé. (2 Tímótì 3:16) Bí wọ́n ti ní ojú ìwòye gidi nípa ìgbésí ayé, wọ́n mọ ìníyelórí ẹ̀kọ́ ìwé nínú jíjèrè òye iṣẹ́ tí ó jẹ́ kòṣeémánìí fún àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ti dàgbà láti lè pèsè fún ara wọn àti àwọn ìdílé wọn lọ́jọ́ iwájú. Nítorí náà, ní pípinnu bóyá ó yẹ kí a kàwé sí i, àti bí a óò ṣe kàwé tó, Kristẹni kọ̀ọ̀kan lè ṣe ìpinnu ara ẹni yíyèkooro tí a gbé karí ìfọkànsìn Jèhófà Ọlọ́run, tí ó “ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.”—1 Tímótì 4:8.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni sí i lórí kókó ọ̀rọ̀ yìí, wo Ilé-Ìṣọ́nà, November 1, 1992, ojú ìwé 10 sí 21, àti ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]
“Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú.”—Òwe 3:21
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]
Nígbà tí a bá ń ronú nípa bóyá ó yẹ kí a kàwé sí i, yóò dára kí Kristẹni kan bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Kí ni ohun tí ń sún mi sí i?’