Àwọn Èwe Tí Wọ́n Rántí Ẹlẹ́dàá Wọn
“Rántí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ nísinsìnyí ní àwọn ọjọ́ ìgbà èwe rẹ.” —ONÍWÀÁSÙ 12:1, NW.
1. Ọ̀rọ̀ tí ọmọ ọlọ́dún 11 kan sọ wo ni ó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ gidi sí i?
ẸWO bí ó ti dára tó nígbà tí àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ bá sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì gbégbèésẹ̀ lọ́nà kan tí ó fi hàn pé wọ́n ń wo Jèhófà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹni gidi, tí wọ́n gbé gẹ̀gẹ̀, tí wọ́n sì fẹ́ láti mú inú rẹ̀ dùn! Ọmọdékùnrin ọlọ́dún 11 kan sọ pé: “Nígbà tí mo bá wà ní èmi nìkan, tí mo sì yọjú láti ojú fèrèsé, mo máa ń rí i bí àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà ti jẹ́ àgbàyanu tó. Lẹ́yìn náà, mo máa ń ronú wòye bí Párádísè ẹlẹ́wà yóò ṣe rí ní ọjọ́ ọ̀la àti bí n óò ṣe lè fọwọ́ ba àwọn ẹranko nígbà náà.” (Aísáyà 11:6-9) Ó fi kún un pé: “Nígbà tí mo bá wà ní èmi nìkan, mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà. Mo mọ̀ pé kì yóò kanra mọ́ mi pé mo ń bá òun sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo. Mo mọ̀ pé ìgbà gbogbo ni ó máa ń wò mí.” Ẹlẹ́dàá wa ha jẹ́ gidi sí ọ gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ sí ọmọdékùnrin yìí bí?
Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Jẹ́ Gidi sí Ọ Tó?
2. (a) Báwo ni Ẹlẹ́dàá rẹ ṣe lè jẹ́ gidi sí ọ? (b) Ipa wo ni àwọn òbí lè kó ní ríran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi kan?
2 Kí Jèhófà àti àwọn ìlérí rẹ̀ tó lè jẹ́ gidi sí ọ, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ àti nípa ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu nínú ayé tuntun òdodo tí Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀, tí òún nawọ́ rẹ̀ sí ọ. (Ìṣípayá 21:3, 4) Bí àwọn òbí rẹ bá ti kọ́ ọ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí, o ní ìdí láti kún fún ìmoore nítorí èyí ń mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti kọbi ara sí àṣẹ àtọ̀runwá náà pé: “Rántí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ nísinsìnyí.” (Oníwàásù 12:1, NW) Èwe kan sọ nípa ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn òbí rẹ̀ fún un ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ pé: “Ohun gbogbo nínú ìgbésí ayé jẹ́ ti Jèhófà. Èyí ni kọ́kọ́rọ́ fún mi láti rántí Ẹlẹ́dàá mi.” Ọ̀dọ́bìnrin mìíràn sọ pé: “Títí láé ni n óò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mi fún kíkọ́ mi pé Jèhófà jẹ́ ẹni gidi. Wọ́n fi bí mo ṣe lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn mi, wọ́n sì sọ fún mi nípa ìdùnnú tí ṣíṣiṣẹ́ sìn ín ní àkókò kíkún jẹ́.”
3, 4. Kí ni ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ronú nípa Jèhófà bí ẹni gidi kan?
3 Síbẹ̀, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ láti finú wòye pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi tí ó ní ọkàn-ìfẹ́ nínú wọn. Ó ha rí bẹ́ẹ̀ fún ọ bí? A ran ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ láti ronú nípa Ọlọ́run lọ́nà tí ó jẹ́ ti ara ẹni, nípasẹ̀ gbólóhùn yìí nínú Ile-Iṣọ Na, pé: “Bi Jehofa Ọlọrun ti tobi to ni irisi titobi ara rẹ̀, awa ko mọ.” Dájúdájú, ọlá ògo Ọlọ́run kò sinmi lé bí ó ti tóbi tó tàbí ìrísí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e nínú Ile-Iṣọ Na yẹn ṣe sọ: “Titobi rẹ̀ gan wa ninu iru Ọlọrun ti o jẹ,” ní tòótọ́, ó jẹ́ Ọlọ́run olóòótọ́, oníyọ̀ọ́nú, onífẹ̀ẹ́, ó sì ń dárí jini.a (Ẹ́kísódù 34:6; Diutarónómì 32:4; Orin Dáfídì 86:5; Jákọ́bù 5:11) Ìwọ́ ha ń wo Jèhófà bí irú ẹnì kan bẹ́ẹ̀, ọ̀rẹ́ kan tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tí o lè bá ní ipò ìbátan ṣíṣeyebíye bí?—Aísáyà 41:8; Jákọ́bù 2:23.
4 Jésù ran àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ìjímìjí lọ́wọ́ láti gbádùn ipò ìbátan ara ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run. Nípa báyìí, nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé nípa àjíǹde rẹ̀ sí ìyè ti ọ̀run tí òún fojú sọ́nà fún, Jòhánù sọ pé: “Àwa yóò dà bí [Ọlọ́run], nítorí àwa yóò rí i gan-an gẹ́gẹ́ bí òún ti rí.” (Jòhánù Kìíní 3:2; Kọ́ríńtì Kìíní 15:44) A lè ran àwọn èwe tòní lọ́wọ́ pẹ̀lú láti wo Ọlọ́run bí ẹni gidi, ẹnì kan tí wọ́n lè mọ̀ dáradára bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò lè fojú ara wọn rí i. Ọ̀dọ́kùnrin kan sọ pé: “Àwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ láti rántí Jèhófà nípa bíbéèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè, irú bíi, ‘Kí ni Jèhófà yóò sọ? Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé rẹ̀ ní ọ̀rọ̀ ara rẹ? Kí ni ìyẹ́n túmọ̀ sí?’” Àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí kò ha mú wa ronú nípa ipò ìbátan ara ẹni wa pẹ̀lú Ọlọ́run?
Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Láti Rántí
5. Àwọn àpẹẹrẹ Bíbélì wo ni ó fi hàn pé láti rántí ẹnì kan ní nínú ju rírántí orúkọ rẹ̀?
5 Kíkọbi ara sí àṣẹ náà, “Rántí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ nísinsìnyí,” túmọ̀ sí ju wíwulẹ̀ ronú nípa Jèhófà. Ó kan gbígbégbèésẹ̀, ṣíṣe ohun tí inú rẹ̀ dùn sí. Nígbà tí ọ̀dáràn náà bẹ Jésù pé, “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ,” ó fẹ́ kí Jésù ṣe ju rírántí orúkọ òun lọ. Ó fẹ́ kí Jésù gbégbèésẹ̀, kí ó jí òun dìde. (Lúùkù 23:42) Bákan náà, Jósẹ́fù tí a fi sẹ́wọ̀n fojú sọ́nà pé kí a gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan nítorí òun nígbà tí ó sọ fún agbọ́tí Fáráò láti rántí sọ nípa òun fún Fáráò. Nígbà tí Jóòbù sì bẹ Ọlọ́run pé, “Rántí mi,” Jóòbù ń béèrè pé ní àkókò kan ní ọjọ́ iwájú, kí Ọlọ́run gbégbèésẹ̀ láti jí òun dìde.—Jóòbù 14:13, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; Jẹ́nẹ́sísì 40:14, 23.
6. Báwo ni ọ̀rọ̀ èdè Hébérù fún “rántí” ṣe dọ́gbọ́n túmọ̀ sí ìfẹ́ni fún ohun tí a rántí, tàbí fún ẹni tí a rántí?
6 Orísun kan sọ pé ọ̀rọ̀ èdè Hébérù náà tí a túmọ̀ sí “rántí” sábà máa ń dọ́gbọ́n túmọ̀ sí “ìsopọ̀ onífẹ̀ẹ́ni ti èrò inú àti ìgbésẹ̀ tí ń bá rírántí rìn.” Ìbátan tí “ìfẹ́ni” ní nínú ọ̀rọ̀ náà, “rántí,” ni a lè rí nínú àròyé tí “àdàlù ọ̀pọ̀ ènìyàn” ṣe nínú aginjù pé: “Àwá rántí ẹja, tí àwá ti ń jẹ ní Íjíbítì.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jóòbù ti bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọ́run rántí òun sí rere, bẹ́ẹ̀ náà ni Hesekáyà, Nehemáyà, Dáfídì, àti onísáàmù kan tí a kò dárúkọ rẹ̀ bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà fi ìfẹ́ni rántí wọn ní kíka ìṣòtítọ́ wọn sí.—Númérì 11:4, 5; Àwọn Ọba Kejì 20:3; Nehemáyà 5:19; 13:31; Orin Dáfídì 25:7; 106:4.
7. Bí a bá rántí Ọlọ́run tìfẹ́nitìfẹ́ni, báwo ni èyí yóò ṣe nípa lórí ìwà wa?
7 Nítorí náà, a lè béèrè pé, ‘A ha ń rántí Ẹlẹ́dàá wa tìfẹ́nitìfẹ́ni bí, tí a sì ń yẹra fún ṣíṣe ohunkóhun tí yóò mú un banú jẹ́ tàbí mú un kérora?’ Èwe kan wí pé: “Màmá ràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Jèhófà ń ní ìmọ̀lára, nígbà tí mo ṣì kéré, mo mọ̀ pé ìgbésẹ̀ mi ń nípa lórí rẹ̀.” (Orin Dáfídì 78:40-42) Òmíràn ṣàlàyé pé: “Mo mọ̀ pé àwọn ìgbésẹ̀ mi yóò ṣe ìrànwọ́ tàbí ṣe ìdíwọ́ láti dáhùn pípè tí Sátánì pe Jèhófà níjà. Mo fẹ́ mú ọkàn-àyà Jèhófà láyọ̀, nítorí náà, ìyẹ́n ràn mí lọ́wọ́, ó sì ń bá a nìṣó láti máa ràn mí lọ́wọ́ lónìí.”—Òwe 27:11.
8. (a) Ìlépa wo ni yóò fi hàn pé a rántí Jèhófà tìfẹ́nitìfẹ́ni? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni àwọn èwe yóò fọgbọ́n gbé yẹ̀ wò?
8 Láìṣeé sẹ́, nínú ayé búburú yìí, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti rántí Jèhófà nípa lílọ́wọ́ ní kíkún nínú ìgbòkègbodò tí inú rẹ̀ dùn sí. Síbẹ̀, wo bí yóò ti dára tó bí o bá lè fara wé Tímótì ti ọ̀rúndún kìíní—kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èwe olùbẹ̀rù-Ọlọ́run lónìí—nípa lílépa iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ti Kristẹni gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà! (Ìṣe 16:1-3; Tẹsalóníkà Kìíní 3:2) Ṣùgbọ́n, a lè béèrè pé, Yóò ha ṣeé ṣe fún ọ láti gbọ́ bùkátà ara rẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà bí? Bí o bá sì ṣègbéyàwó, ìwọ́ yóò ha ní òye iṣẹ́ láti pèsè fún àwọn tí ń bẹ nínú ìdílé rẹ bí? (Tímótì Kìíní 5:8) Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìbéèrè pàtàkì, ó sì ṣe kókó pé kí o ronú jinlẹ̀ nípa wọn.
Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Tí Ó Ní Ète
9. Ìpinnu wo ni ó dojú kọ àwọn èwe nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé?
9 Bí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, o lè nílò ìmọ̀ ẹ̀kọ́ púpọ̀ sí i láti rí iṣẹ́ tí ó tó láti gbọ́ bùkátà ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. O ti lè ṣàkíyèsí pé ó ti wá pọn dandan fún àwọn kan tí wọ́n ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yunifásítì pàápàá láti lọ gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ sí i kí wọ́n baà lè ní òye iṣẹ́ tuntun tí àwọn agbanisíṣẹ́ ń fẹ́ lónìí. Nítorí náà, báwo ni ó ṣe yẹ kí ẹ̀yin èwe tí ń fẹ́ láti mú inú Ọlọ́run dùn kàwé tó? A ní láti ṣe ìpinnu náà lọ́nà títọ́ ní níní àṣẹ onímìísí náà lọ́kàn pé: “Rántí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ nísinsìnyí.”
10. Kí ni ẹ̀kọ́ dídára jù lọ tí a lè rí gbà?
10 Dájúdájú, ìwọ yóò fẹ́ láti lépa ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn orísun ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ti ayé pàápàá kà sí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó dára jù lọ—èyí tí a ń ní nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀. Òǹkọ̀wé ará Germany náà, Johann Wolfgang von Goethe, wí pé: “Bí ìtẹ̀síwájú nínú ọgbọ́n orí [àwọn ènìyàn] bá ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò túbọ̀ rọrùn dáradára tó láti lo Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ àti irinṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀kọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò mú ọ gbára dì lọ́nà tí ó sàn jù fún ìgbésí ayé ju bí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ èyíkéyìí mìíràn yóò ti ṣe lọ!—Òwe 2:6-17; Tímótì Kejì 3:14-17.
11. (a) Kí ni iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí a lè ṣe? (b) Èé ṣe tí èwe kan fi yàn láti gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ dé ìwọ̀n kan?
11 Níwọ̀n bí ìmọ̀ Ọlọ́run ti ń fúnni ní ìyè, iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí o lè ṣe lónìí ni láti ṣàjọpín ìmọ̀ yẹn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Òwe 3:13-18; Jòhánù 4:34; 17:3) Ṣùgbọ́n, láti ṣe èyí lọ́nà gbígbéṣẹ́, o ní láti gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní àwọn ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì. O ní láti lè ronú ni kedere, kí o sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó lọ́gbọ́n nínú, kí o sì mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà dáradára—òye iṣẹ́ tí a ń kọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́. Nítorí náà, fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ rẹ ní ilé ẹ̀kọ́, gẹ́gẹ́ bí Tracy, èwe kan ní Florida, U.S.A., ti ṣe, ẹni tí ó gboyè jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga lọ́nà tí ó fakọ yọ. Ó sọ ìrètí rẹ̀ jáde pé: “Ìgbà gbogbo ni mo ń fi jíjẹ́ ìránṣẹ́ alákòókò kíkún fún Jèhófà Ọlọ́run mi ṣe góńgó, mo sì retí pé ìmọ̀ ẹ̀kọ́ mi yóò ràn mí lọ́wọ́ láti lé góńgó yìí bá.”
12. Bí a bá yan àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé, ète wo ni ó lè ṣèrànwọ́ láti ṣàṣeparí?
12 O ha ti ronú nípa ìdí tí o fi ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ bí? Ó ha jẹ́, ní pàtàkì, láti gbára rẹ dì láti di òjíṣẹ́ tí ó gbéṣẹ́ fún Jèhófà bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò fẹ́ láti ronú jinlẹ̀ lórí bí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ ṣe ń ṣàṣeparí èyí dáradára tó. Lẹ́yìn fífikùnlukùn pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, ẹ lè pinnu pé o ní láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ju ohun tí ó kéré jù lọ tí òfin béèrè fún. Irú àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara rẹ, kí ó sì tún fún ọ láyè àti agbára láti nípìn-ín ní kíkún nínú ìgbòkègbodò Ìjọba.—Mátíù 6:33.
13. Báwo ni àwọn Kristẹni méjì tí wọ́n jẹ́ ará Rọ́ṣíà, tí wọ́n gba àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́, ṣe ṣàfihàn ète wọn ní ìgbésí ayé?
13 Àwọn kan tí wọ́n lépa àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ pàápàá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nígbà tí wọ́n ń gba àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́. Ronú ná nípa Nadia àti Marina, àwọn ọmọdébìnrin ọ̀dọ́langba méjì ní Moscow, Rọ́ṣíà. A batisí àwọn méjèèjì ní April 1994, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n gboyè jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, wọ́n sì forúkọ sílẹ̀ fún ètò ẹ̀kọ́ ìṣirò owó ọlọ́dún méjì. Ní May 1995, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà, síbẹ̀ wọ́n ń mú ipò iwájú ní kíláàsì ẹ̀kọ́ ìṣirò owó tí wọ́n wà. Síwájú sí i, ó ṣeé ṣe fún wọn láti darí ìpíndọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì 14 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láàárín ara wọn nígbà tí wọ́n ṣì ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Àwọn ọmọdébìnrin náà retí pé ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wọn nínú ìṣirò owó yóò jẹ́ kí wọ́n rí iṣẹ́ tí ó tó ṣe, kí wọ́n baà lè gbọ́ bùkátà ara wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
14. Láìka iye ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé tí a yàn sí, kí ni ó yẹ kí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa?
14 Bí o bá ń gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ju ohun tí òfin béèrè fún, fọgbọ́n ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tí o fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ha jẹ́ láti ṣe orúkọ fún ara rẹ, kí o sì kó ọrọ̀ jọ bí? (Jeremáyà 45:5; Tímótì Kìíní 6:17) Tàbí, góńgó rẹ ha jẹ́ láti lo àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ láti nípìn-ín ní kíkún sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bí? Lydia, èwe kan tí ó yàn láti gba àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́, fi pípe àfiyèsí dáradára sórí àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí hàn, ní ṣíṣàlàyé pé: “Àwọn mìíràn ń lépa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ gíga, wọ́n sì jẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì dí wọn lọ́wọ́, wọ́n sì ti gbàgbé Ọlọ́run. Ní tèmi, ipò ìbátan mi pẹ̀lú Ọlọ́run ni ó ṣe pàtàkì jù lọ fún mi.” Ẹ wo irú ẹ̀mí ìrònú tí ó yẹ kí a gbóríyìn fún tí èyí jẹ́ fún gbogbo wa!
15. Irú onírúurú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àtilẹ̀wá wo ni ó wà láàárín àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?
15 Lọ́nà tí ó gba àfiyèsí, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní onírúurú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àtilẹ̀wá tí ó pọ̀ jáǹtìrẹrẹ. Fún àpẹẹrẹ, a ka àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù sí ‘aláìmọ̀wé àti gbáàtúù’ nítorí pé a kò kọ́ wọn ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì. (Ìṣe 4:13) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba ohun tí a lè fi wé ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yunifásítì lónìí. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù kò lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yẹn láti pe àfiyèsí sí ara rẹ̀; kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ohun èlò kan nígbà tí ó wàásù fún àwọn ènìyàn ní onírúurú ipò ìgbésí ayé. (Ìṣe 22:3; Kọ́ríńtì Kìíní 9:19-23; Fílípì 1:7) Bákan náà, Manaen, tí ó “gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú Hẹ́rọ́dù olùṣàkóso àgbègbè náà,” wà lára àwọn tí wọ́n mú ipò iwájú nínú ìjọ Áńtíókù.—Ìṣe 13:1.
Èé Ṣe Tí O Fi Ní Láti Fọgbọ́n Bójú Tó Ìṣúnná Owó Rẹ?
16. (a) Èé ṣe tí ó fi túbọ̀ lè ṣòro láti rántí Ẹlẹ́dàá wa bí a bá tọrùn bọ gbèsè? (b) Báwo ni ọ̀kan nínú àwọn àkàwé Jésù ṣe fi ìjẹ́pàtàkì ríronú ṣáájú kí a tó náwó hàn?
16 Bí o bá kùnà láti fọgbọ́n bójú tó ìṣúnná owó rẹ, ó lè túbọ̀ ṣòro láti rántí Ẹlẹ́dàá rẹ nípa ṣíṣe ohun tí inú rẹ̀ dùn sí. Nítorí bí o bá tọrùn bọ gbèsè, a lè sọ pé o ti ní ọ̀gá mìíràn. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Yá owó, ìwọ yóò sì di ẹrú olówó.” (Òwe 22:7, Today’s English Version) Ọ̀kan nínú àwọn àkàwé Jésù tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ríronú ṣáájú kí a tó náwó. Jésù wí pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òún bá ní tó láti parí rẹ̀? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ṣùgbọ́n kí ó má lè parí rẹ̀, gbogbo àwọn òǹwòran sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í yọ ṣùtì sí i.”—Lúùkù 14:28, 29.
17. Èé ṣe tí ó fi sábà máa ń ṣòro láti ṣèkáwọ́ ìṣúnná owó ẹni?
17 Nítorí náà, lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, ìwọ yóò gbìyànjú láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́ náà ‘láti má ṣe jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ẹyọ ohun kan, àyàfi láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kíní kejì.’ (Róòmù 13:8) Ṣùgbọ́n èyí kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, ní pàtàkì nígbà tí o bá ń rí àwọn nǹkan tuntun tí a ń mú jáde láìdáwọ́dúró, tí àwọn olùpolówó ọjà sọ pé o nílò ní ti gidi. Òbí kan, tí ó ti gbìyànjú láti ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti lo ìwòyemọ̀, sọ pé: “A ti lo àkókò púpọ̀ ní jíjíròrò ohun tí ó jẹ́ kò-ṣeé-má-nìí, àti ohun tí a fẹ́.” Ilé ẹ̀kọ́ ní gbogbogbòò ti kùnà láti fi irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ kọ́ni, ní pípèsè ìtọ́ni díẹ̀, bí ó bá tilẹ̀ wà rárá, lórí bí a ṣe ń bójú tó ìṣúnná owó lọ́nà tí ó níláárí. Òṣìṣẹ́ onípò gíga kan sọ pé: “A ń jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ní mímọ̀ nípa tirayáńgùlù ju mímọ̀ nípa bí a ti í fowó pamọ́.” Nígbà náà, kí ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fọgbọ́n náwó?
18. Kí ni kọ́kọ́rọ́ fún fífọgbọ́n bójú tó ìṣúnná owó, èé sì ti ṣe?
18 Kíkọbi ara sí ìgbaniníyànjú náà, “Rántí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ nísinsìnyí,” ni kọ́kọ́rọ́ kan sí fífọgbọ́n bójú tó ìṣúnná owó rẹ. Èyí jẹ́ nítorí pé nígbà tí o bá ṣègbọràn sí àṣẹ náà, ohun àkọ́múṣe rẹ yóò jẹ́ láti mú inú Jèhófà dùn, ìfẹ́ni rẹ fún un yóò sì nípa lórí bí o ṣe ń ná owó rẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ìwọ yóò gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tí o ń fẹ́ ṣèdíwọ́ fún fífún Ọlọ́run ní ìfọkànsìn délẹ̀délẹ̀. (Mátíù 16:24-26) Ìwọ yóò sakun láti jẹ́ kí ojú rẹ “mú ọ̀nà kan,” ìyẹn ni pé, kí o darí àfiyèsí ṣíṣe kedere sórí Ìjọba Ọlọ́run àti ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Mátíù 6:22-24) Nípa báyìí, ìwọ yóò máa wo ìṣílétí àtọ̀runwá náà láti “fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa” gẹ́gẹ́ bí àǹfààní tí ń mú ìdùnnú wá.—Òwe 3:9.
Àwọn Èwe Tí Wọ́n Yẹ Láti Fara Wé
19. Báwo ni àwọn èwe ní ìgbà àtijọ́ ṣe rántí Ẹlẹ́dàá wọn?
19 Ó múni láyọ̀ pé, ọ̀pọ̀ èwe, ní àtijọ́ àti nísinsìnyí, ti rántí Ẹlẹ́dàá wọn. Sámúẹ́lì ọ̀dọ́ dúró gbọn-in-gbọn-in nínú iṣẹ́ ìsìn àgọ́ àjọ láìka agbára ìdarí oníwà pálapàla ti àwọn tí òún bá ṣiṣẹ́ ìsìn sí. (Sámúẹ́lì Kìíní 2:12-26) Olùdẹwò tí ń fọgbọ́n fani mọ́ra náà, ìyàwó Pọ́tífárì, kò lè ré Jósẹ́fù ọ̀dọ́ lọ láti ṣe àgbèrè. (Jẹ́nẹ́sísì 39:1-12) Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “ọmọdé ni,” Jeremáyà wàásù tìgboyàtìgboyà lójú àtakò gbígbóná janjan. (Jeremáyà 1:6-8) Ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ Ísírẹ́lì kan fi ìgboyà darí olórí ọmọ ogun, ará Síríà kan, tí ó jẹ́ alágbára, láti wá ìrànlọ́wọ́ ní Ísírẹ́lì, níbi tí ó ti lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Àwọn Ọba Kejì 5:1-4) Dáníẹ́lì ọ̀dọ́ àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pa ìgbàgbọ́ wọn mọ́ nígbà tí a dán wọn wò lórí òfin Ọlọ́run nípa oúnjẹ. Àwọn èwe náà, Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò, sì yàn pé kí a gbé wọn jù sínú iná ìleru dípò fífi ìdúróṣinṣin wọn sí Ọlọ́run báni dọ́rẹ̀ẹ́ nípa jíjọ́sìn níwájú ère kan.—Dáníẹ́lì 1:8, 17; 3:16-18; Ẹ́kísódù 20:5.
20. Báwo ni ọ̀pọ̀ èwe ti ṣe rántí Ẹlẹ́dàá wọn lónìí?
20 Lónìí, èyí tí ó ju 2,000 èwe, tí wọ́n jẹ́ ẹni ọdún 19 sí ọdún 25 ń ṣiṣẹ́ sìn ní orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New York State, U.S.A. Wọ́n jẹ́ ìwọ̀nba kéréje lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá mẹ́wàá àwọn èwe tí wọ́n ń rántí Ẹlẹ́dàá wọn kárí ayé. Gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ìgbàanì, wọ́n ti kọ̀ láti fi ìjẹ́mímọ́ wọn ní ti ìwà híhù báni dọ́rẹ̀ẹ́. Ọ̀pọ̀ ti ṣègbọràn sí Ọlọ́run jù sí ènìyàn nígbà tí a fagbára mú wọn láti yan ẹni tí wọn yóò ṣiṣẹ́ sìn. (Ìṣe 5:29) Ní ọdún 1946, ní Poland, a dá ọmọ ọlọ́dún 15 náà, Henryka Zur, lóró nígbà tí ó kọ̀ láti ṣe ohun kan tí ó jẹ́ ìbọ̀rìṣà ní ti ìsìn. Ọ̀kan lára àwọn tí ó dá a lóró wí pé: “Ohunkóhun tí ó bá wù ọ́ ni kí o gbà gbọ́, kí o ṣáà ti sàmì àgbéléèbú Kátólíìkì.” Nítorí pé ó kọ̀, a wọ́ ọ lọ sínú igbó, a sì yìnbọn pa á, ìrètí ìyè ayérayé rẹ̀ dájú!b
21. Ìkésíni wo ni yóò bọ́gbọ́n mu láti tẹ́wọ́ gbà, kí ni yóò sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?
21 Ẹ wo bí àwọn èwe tí wọ́n ti rántí Jèhófà jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún yóò ti mú ọkàn-àyà rẹ̀ yọ̀ tó! Ìwọ yóò ha dáhùn sí ìkésíni yìí, “Rántí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ nísinsìnyí” bí? Ní tòótọ́, ó yẹ fún ìrántí rẹ! Máa ronú lójoojúmọ́ nípa gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún ọ, tí yóò sì ṣe síbẹ̀, kí o sì tẹ́wọ́ gba ìkésíni rẹ̀ pé: “Ọmọ mi, kí ìwọ kí ó gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn; kí èmi kí ó lè dá ẹni tí ń gàn mí lóhùn.”—Òwe 27:11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ile-Iṣọ Na, May 1954, ojú ìwé 68.
b Wo ìwé náà, 1994 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 217 àti 218, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Báwo ni a ṣe lè ran àwọn èwe lọ́wọ́ láti wo Ọlọ́run bí ẹni gidi kan?
◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti rántí Ẹlẹ́dàá rẹ?
◻ Ète wo ni ó yẹ kí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wa ṣiṣẹ́ fún?
◻ Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti fọgbọ́n bójú tó ìṣúnná owó wa?
◻ Àwọn èwe wo ni ó yẹ kí o fara wé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
O ha ti ronú nípa ìdí tí o fi ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ bí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìwọ ha ń kọ́ bí a ṣe ń fọgbọ́n bójú tó ìṣúnná owó bí?