Ǹjẹ́ ó Yẹ Kí Ọmọ Mi Lọ Sílé Ẹ̀kọ́?
ǸJẸ́ o lè fojú inú wo bí ì bá ṣe rí lára rẹ ká sọ pé o ò lè ka àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí? Ká sọ pé o ò gbọ́ èdè tó jẹ́ àjùmọ̀lò ní orílẹ̀-èdè rẹ ńkọ́? Báwo ni ì bá ti rí ká ní o ò lè nawọ́ sí ibi tí orílẹ̀-èdè rẹ wà nínú àwòrán àgbáyé? Àìmọye àwọn ọmọ ló máa dàgbà lọ́nà tá a sọ yìí. Ọmọ tìrẹ ńkọ́?
Ǹjẹ́ ó yẹ kí ọmọ rẹ lọ sílé ẹ̀kọ́? Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ti pọn dandan kéèyàn lọ sílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama, ọ̀fẹ́ sì ni wọ́n sábà máa ń jẹ́. Àdéhùn Nípa Ẹ̀tọ́ Ọmọdé sọ pé lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ jẹ́ ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ. Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé pàápàá tún sọ ohun kan náà. Àmọ́ láwọn ilẹ̀ kan, ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lè máà sí kí èyí sì wá gbé ẹrù ìnáwó ka àwọn òbí lórí. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀ràn náà látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni òbí tí wọ́n fẹ́ káwọn ọmọ wọn kàwé, bóyá nípa lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gbogbo gbòò ni o tàbí lọ́nà mìíràn.
Àpẹẹrẹ Ìwé Kíkọ́ Látinú Bíbélì
Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tá a dárúkọ wọn nínú Bíbélì ló mọ̀wéé kà tó sì mọ̀ọ́kọ. Apẹja ni Pétérù àti Jòhánù tí wọ́n jẹ́ àpọ́sítélì Jésù, àmọ́ èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ ìwé tí wọ́n kọ nínú Bíbélì, wọn ò fi èdè àwọn ará Gálílì tí í ṣe èdè ìbílẹ̀ wọn kọ ọ́.a Ó dájú pé àwọn òbí wọn sapá láti rí i pé àwọn ọmọ àwọn kàwé débi tó yẹ. Àwọn akọ̀wé Bíbélì mìíràn tí ọ̀ràn wọn tún rí bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, Ámósì tó jẹ́ àgbẹ̀ àti Júúdà tí í ṣe iyèkan Jésù, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà.
Jóòbù mọ̀wéé kà ó sì mọ̀ọ́kọ, ìwé tá a sì fi orúkọ rẹ̀ pè nínú Bíbélì fi hàn pé ó mọ̀ nípa sáyẹ́ǹsì dé àyè kan. Ó ṣeé ṣe kó tún nímọ̀ nípa béèyàn ṣe ń fi ewì dá bírà, nítorí pé èdè ewì ló fi sọ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó kọ sínú ìwé Jóòbù. A sì tún mọ̀ pé àwọn Kristẹni ìjímìjí kàwé nítorí pé àwọn èèyàn ti rí àwọn àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n kọ sára àwọn àfọ́kù apẹ tàbí sára àwọn àpáàdì.
Ẹ̀kọ́ Ìwé Ṣe Pàtàkì Fáwọn Kristẹni
Gbogbo Kristẹni pátá ló gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ Bíbélì tí wọ́n bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn. (Fílípì 1:9-11; 1 Tẹsalóníkà 4:1) Fífi ìtara lo Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a gbé karí Bíbélì lè mú kéèyàn tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Nígbà tó sì jẹ́ pé Ọlọ́run ti fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀, ó ń retí pé káwọn olùjọ́sìn òun mọ̀wéé kọ kí wọ́n sì mọ̀ọ́kà débi tó bá ṣeé ṣe. Ó máa rọrùn láti fi àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì sílò téèyàn bá ń kà á tó sì ń lóye rẹ̀. Àmọ́ ó lè gba pé ká ka àwọn ibì kan nínú rẹ̀ léraléra ká tó lè mọ ìtumọ̀ wọn dáadáa ká sì lè ṣàṣàrò lórí wọn.—Sáàmù 119:104; 143:5; Òwe 4:7.
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìwé tá a kọ lábẹ́ ìdarí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ló máa ń dọ́wọ́ àwọn èèyàn Jèhófà lọ́dọọdún. (Mátíù 24:45-47) Àwọn ìwé yìí máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé ìdílé, àwọn àṣà, ìsìn, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ọ̀pọ̀ àwọn kókó mìíràn. Pàtàkì jù lọ ibẹ̀ ni pé àwọn ìmọ̀ràn tí Ìwé Mímọ́ fúnni lórí àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí wà nínú rẹ̀. Báwọn ọmọ rẹ ò bá sì mọ̀wéé kà, a jẹ́ pé àwọn ìsọfúnni pàtàkì pàtàkì ló ń fò wọ́n dá yẹn.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìtàn ẹ̀dá èèyàn ṣe pàtàkì nítorí pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìdí tá a fi nílò Ìjọba Ọlọ́run. Ó tún dára kéèyàn ní ìmọ̀ díẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àgbègbè tó pọ̀, irú bí Ísírẹ́lì, Íjíbítì àti Gíríìsì. Ǹjẹ́ ọmọ rẹ lè tọ́ka síbi tí wọ́n wà nínú àwòrán àgbáyé? Ǹjẹ́ ó lè tọ́ka síbi tí orílẹ̀-èdè rẹ wà níbẹ̀? Béèyàn ò bá mọ bí wọ́n ṣe ń wo àwòrán àgbáyé, olúwarẹ̀ lè máà lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe yẹ lágbègbè tí wọ́n bá yàn án sí.—2 Tímótì 4:5.
Àwọn Àǹfààní Nínú Ìjọ
Àwọn Kristẹni alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwé kíkà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìmúrasílẹ̀ wà tí wọ́n á ṣe fáwọn ìpàdé ìjọ. Wọ́n ní láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìwé tó ń dé sí ìjọ àtàwọn ọrẹ. Téèyàn ò bá kàwé dé àyè kan, ó máa ṣòro láti bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ yìí bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
Àwọn òṣìṣẹ́ tó yọ̀ǹda ara wọn ń sìn láwọn ilé Bẹ́tẹ́lì kárí ayé. Káwọn tó yọ̀ǹda ara wọn yìí lè bára wọn sọ̀rọ̀ dáadáa kí wọ́n sì lè ṣiṣẹ́ wọn bó ti yẹ, irú bíi títúmọ̀ ìwé àti ṣíṣàtúnṣe àwọn ẹ̀rọ, wọ́n ní láti mọ bí a ṣe ń ka èdè àjùmọ̀lò orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé kí wọ́n sì mọ̀ọ́kọ. Bí àwọn ọmọ rẹ yóò bá gbádùn irú àǹfààní wọ̀nyí, ó di dandan kí wọ́n kàwé dé àyè kan. Kí làwọn ìdí pàtàkì mìíràn tó fi yẹ kí ọmọ rẹ lọ sílé ìwé?
Ipò Òṣì àti Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán
Àwọn tó wà nípò òṣì lè bára wọn nínú àwọn ipò kan tí kò bára dé tí wọn ò sì ní lè ṣe ohunkóhun. Àmọ́ nígbà mìíràn, kíkàwé dé ìwọ̀n àyè tó yẹ lè gba àwa àtàwọn ọmọ wa lọ́wọ́ ìjìyà tí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Agbára káká ni ọ̀pọ̀ èèyàn tó jẹ́ púrúǹtù fi wà láàyè. Àwọn ọmọ títí kan àwọn òbí pàápàá máa ń kú nítorí pé owó táṣẹ́rẹ́ tó ń wọlé fún wọn kò jẹ́ kí wọ́n lè gba ìtọ́jú ìṣègùn tó yẹ. Àwọn tí ò kàwé rárá tàbí tí wọn ò kà á tó bó ṣe yẹ kì í sábàá rí oúnjẹ aṣaralóore jẹ, ibi tí wọ́n sì máa ń gbé pàápàá kò fi bẹ́ẹ̀ bójú mu. Ẹ̀kọ́ tó mọ́yán lórí tàbí kẹ̀ kéèyàn mọ̀ọ́kọ kó sì mọ̀ọ́kà lè ṣèrànwọ́ nínú àwọn ipò bí èyí.
Jíjẹ́ ọ̀mọ̀wé tún máa ń dín ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kù. Òótọ́ ni pé àtàwọn ọ̀mọ̀wé àtàwọn púrúǹtù ló nígbàgbọ́ nínú ohun asán. Àmọ́ àwọn tó jẹ́ púrúǹtù làwọn èèyàn tètè máa ń rí tàn jẹ nítorí pé wọn ò lè ka àwọn nǹkan tó tú àṣírí irú àwọn ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀. Ìdí rèé tí wọ́n fi máa ń nígbàgbọ́ nínú ohun asán tí wọ́n sì máa ń gbà gbọ́ pé àwọn abẹ́mìílò lè ṣèwòsàn lọ́nà ìyanu.—Diutarónómì 18:10-12; Ìṣípayá 21:8.
Kì Í Ṣe Tìtorí Àtiríṣẹ́ Nìkan Lèèyàn Ṣe Ń Kàwé
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ronú pé tìtorí àtirówó nìkan lèèyàn ṣe ń kàwé. Àmọ́ àwọn kan wà tí wọ́n kàwé débi tó yẹ àmọ́ tí wọn ò ríṣẹ́ tàbí tí owó tó ń wọlé fún wọn ò tó ná. Èyí lè mú káwọn òbí kan bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé kò sí àǹfààní kankan nínú kéèyàn rán ọmọ lọ síléèwé. Àmọ́ kì í ṣe tìtorí àtirí owó nìkan lèèyàn ṣe ń kàwé o; ó tún máa ń mú káwọn ọmọ gbára dì fún ìgbésí ayé lọ́jọ́ iwájú. (Oníwàásù 7:12) Bí ẹnì kan bá ń sọ èdè àjùmọ̀lò orílẹ̀-èdè tó ń gbé, tó mọ̀ ọ́n kà tó sì mọ̀ ọ́n kọ, á rọrùn fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti bá àwọn oníṣègùn, àwọn aláṣẹ tàbí àwọn òṣìṣẹ́ báńkì sọ̀rọ̀ fàlàlà, ẹ̀rù wọn ò sì ní máa bà á.
Láwọn ibì kan, wọ́n lè mú àwọn ọmọ tí ò kàwé lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ láti kọ́ṣẹ́ mọlémọlé, ẹja pípa, iṣẹ́ aṣọ rírán tàbí iṣẹ́ mìíràn. Kò sóhun tó burú nínú iṣẹ́ kíkọ́, àmọ́ táwọn ọmọ wọ̀nyí ò bá lọ sílé ìwé rárá, ó ṣeé ṣe kí wọ́n má lè mọ̀wéé kọ kí wọ́n sì mọ̀ọ́kà dáadáa. Ó dájú pé tí wọ́n bá ti kọ́kọ́ kàwé díẹ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ṣẹ́, àwọn èèyàn ò ní lè tètè rí wọn rẹ́ jẹ, ìgbésí ayé wọn á sì túbọ̀ dùn.
Káfíńtà ni Jésù ti Násárétì, ó sì hàn gbangba pé ọ̀dọ̀ Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀ ló ti kọ́ṣẹ́. (Mátíù 13:55; Máàkù 6:3) Jésù tún jẹ́ ọ̀mọ̀wé nítorí nígbà tó tiẹ̀ wà lọ́mọ ọdún méjìlá péré, òun àtàwọn tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé jìjọ fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ nínú tẹ́ńpìlì. (Lúùkù 2:46, 47) Ní ti Jésù, kíkọ́ṣẹ́ kò ṣèdíwọ́ fún oríṣi ẹ̀kọ́ mìíràn tó ń gbà.
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Ọmọbìnrin Kàwé?
Kìkì àwọn ọmọkùnrin làwọn òbí máa ń rán lọ́ sílé ẹ̀kọ́ nígbà míì, wọn kì í rán àwọn ọmọbìnrin lọ. Àwọn òbí kan lè máa ronú pé owó tàbùàtabua ló ń náni láti rán ọmọbìnrin lọ sílé ẹ̀kọ́ àti pé ìgbà táwọn ọmọbìnrin bá dúró sílé látàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni wọ́n lè wúlò fún ìyá wọn jù. Àmọ́ ńṣe ni àìkàwé máa sọ ọmọbìnrin dìdàkudà. Ìtẹ̀jáde kan látọ̀dọ̀ Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìwádìí ló ti fi hàn pé jíjẹ́ kí àwọn ọmọbìnrin kàwé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó dára jù lọ láti fòpin sí ipò òṣì.” (Poverty and Children: Lessons of the 90s for Least Developed Countries) Àwọn ọmọbìnrin tó bá kàwé máa ń mọ béèyàn ṣe ń kojú ìṣòro ìgbésí ayé, wọ́n máa ń ṣe ìpinnu tó lọ́gbọ́n nínú, wọ́n sì ń tipa báyìí ṣe gbogbo ìdílé lápapọ̀ láǹfààní.
Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Benin ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, nípa bí àwọn ọmọdé ṣe ń kú fi hàn pé mẹ́tàdínláàádọ́sàn-án [167] nínú ẹgbẹ̀rún [1000] àwọn ọmọ tí ò tíì pé ọdún márùn-ún ló ń kú mọ́ àwọn ìyálọ́mọ tí ò kàwé lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn tó ń kú mọ́ àwọn ìyálọ́mọ tí wọ́n jáde ìwé mẹ́wàá lọ́wọ́ ò ju méjìdínlógójì lọ. Àjọ UNICEF parí ọ̀rọ̀ pé: “Nítorí náà, báwọn èèyàn bá ṣe kàwé tó ló ń pinnu bí àwọn ọmọdé ṣe ń kú tó ní orílẹ̀-èdè Benin àti níbi gbogbo lágbàáyé.” Nítorí náà, àǹfààní ńláǹlà ló wà nínú jíjẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ obìnrin kàwé o.
Ṣé Kíláàsì Mọ̀ọ́kọ-Mọ̀ọ́kà Nìkan Ti Tó?
Níbi tó bá ti pọn dandan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dá kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà sílẹ̀ nítorí àwọn ará tí ò lè kàwé.b Ìpèsè gbígbéṣẹ́ yìí ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀wéé kà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń jẹ́ lédè àbínibí wọn. Ǹjẹ́ ó bójú mu ká wá fi èyí rọ́pò lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gbogbo gbòò? Ǹjẹ́ ó yẹ kó o máa retí pé ìjọ ló máa kọ́ ọmọ rẹ níwèé nígbà tí ilé ìwé ìjọba ń bẹ?
Òótọ́ ni pé ìṣètò onínúure ni kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò rẹ̀ jẹ́, síbẹ̀ àwọn àgbàlagbà tí wọn ò láǹfààní àtilọ sílé ẹ̀kọ́ nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé ló wà fún. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ńṣe làwọn òbí wọn ò mọ ìjẹ́pàtàkì lílọ sílé ìwé tàbí pé kó máà sí ilé ìwé lásìkò náà. Lílọ sáwọn kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tí ìjọ ń darí rẹ̀ á ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá, a ò ṣètò àwọn kíláàsì yìí láti fi rọ́pò ilé ìwé gbogbo gbòò tàbí ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. A kì í kọ́ àwọn èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì, ìmọ̀ ìṣirò àti ẹ̀kọ́ nípa ìtàn láwọn kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà wọ̀nyí. Àmọ́, àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí wà lára ohun tí wọ́n ń kọ́ni láwọn ilé ìwé gbogbo gbòò.
Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, èdè ìbílẹ̀ la sábà máa ń kọ́ àwọn èèyàn láwọn kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, a kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ kọ́ wọn ní èdè àjùmọ̀lò orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ tó bá jẹ́ nílé ìwé gbogbo gbòò ni, èdè àjùmọ̀lò orílẹ̀-èdè náà ni wọ́n fi n kọ́ni níbẹ̀. Àfikún àǹfààní lèyí jẹ́ fáwọn ọmọ nítorí pé ọ̀pọ̀ ìwé àtàwọn onírúurú nǹkan mìíràn tó wà fún kíkà ló jẹ́ pé èdè àjùmọ̀lò ni wọ́n fi kọ wọ́n. Òótọ́ ni pé kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà lè fi kún ẹ̀kọ́ tí ọmọ kan kọ́ nílé ìwé, síbẹ̀ kò lè rọ́pò rẹ̀. Nígbà náà, tó bá ṣeé ṣe ǹjẹ́ kò ní dára kí àwọn ọmọ lọ sílé ẹ̀kọ́ gbogbo gbòò?
Ẹrù Iṣẹ́ Òbí Ni
Àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń mú ipò iwájú nínú pípèsè àwọn ohun tẹ̀mí fún ìjọ gbọ́dọ̀ jẹ́ Kristẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ. Wọ́n ní láti bójú tó agbo ilé wọn àtàwọn ọmọ wọn “lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” (1 Tímótì 3:4, 12) Bíbójú tó agbo ilé “lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀” yóò ní ṣíṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ kí ọjọ́ ọ̀la wọn lè dára nínú.
Ọlọ́run ti gbé ẹrù iṣẹ́ bàǹtàbanta lé àwọn Kristẹni òbí léjìká. Wọ́n gbọ́dọ̀ tọ́ àwọn ọmọ wọn níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di “olùfẹ́ ìmọ̀.” (Òwe 12:1; 22:6; Éfésù 6:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) A tún gbọ́dọ̀ fún àwọn ọmọ wa ni ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó yẹ.
Nígbà míì, àwọn ilé ẹ̀kọ́ kì í lè kọ́ àwọn ọmọ wa ní ẹ̀kọ́ tó bó ṣe yẹ nítorí àpọ̀jù akẹ́kọ̀ọ́, àìsí owó tó tó, tàbí nítorí àwọn olùkọ́ tí inú wọn ò dùn, tí wọn ò sanwó tó jọjú fún. Ìdí rèé tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn òbí máa fojú sí ohun táwọn ọmọ wọn ń kọ́ nílé ìwé. Ó dára láti di ojúlùmọ̀ àwọn olùkọ́ wọn, pàápàá níbẹ̀rẹ̀ sáà kọ̀ọ̀kan nílé ẹ̀kọ́, wọn tiẹ̀ lè wádìí lẹ́nu àwọn olùkọ́ nípa ọ̀nà táwọn ọmọ náà lè gbà di akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe dáadáa. Èyí á jẹ́ káwọn olùkọ́ mọ̀ pé àwọn òbí kà wọ́n sí á sì mú kí wọ́n túbọ̀ jára mọ́ ọ̀ràn kíkọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó túbọ̀ dára sí i.
Ẹ̀kọ́ kó ipa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè ọmọ. Òwe 10:14 sọ pé: “Àwọn ọlọ́gbọ́n ni ó ń fi ìmọ̀ ṣúra.” Òtítọ́ lọ̀rọ̀ yìí o, àgàgà ní ti ìmọ̀ Bíbélì. Àwọn èèyàn Jèhófà—yálà ọmọdé tàbí àgbà—gbọ́dọ̀ nímọ̀ dé ibi tó bá ṣeé ṣe kí wọ́n bàa lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí kí wọ́n sì lè ‘fi ara wọn hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.’ (2 Tímótì 2:15; 1 Tímótì 4:15) Nítorí náà, ṣé ó yẹ káwọn ọmọ rẹ lọ sílé ẹ̀kọ́? Ó dájú pé o ò ní jiyàn pé ó yẹ kí wọ́n lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí sinmi lórí bí nǹkan bá ṣe rí ní orílẹ̀-èdè rẹ. Àmọ́ àwọn Kristẹni òbí ní láti dáhùn ìbéèrè tó túbọ̀ ṣe pàtàkì yìí pé, ‘Ǹjẹ́ ó yẹ káwọn ọmọ mi kàwé?’ Ibikíbi tó wù kó o máa gbé, ó yẹ kí ìdáhùn rẹ pé bẹ́ẹ̀ ni máa dún ní àdúntúndún, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀kan lára àwọn èdè Árámáíkì táwọn ará Gálílì ń sọ tàbí oríṣi èdè Hébérù kan ni èdè ìbílẹ̀ àwọn èèyàn yìí. Wo ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 144 sí 146, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
TÍ KÒ BÁ ṢEÉ ṢE LÁTI LỌ SÍLÉ Ẹ̀KỌ́
Àwọn ipò kan wà tí ò ti ṣeé ṣe láti lọ sílé ẹ̀kọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Refugees sọ pé ẹyọ kan ṣoṣo nínú márùn-ún lára àwọn ọmọ tó yẹ kó lọ sílé ẹ̀kọ́ ló lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi. Láwọn ìgbà mìíràn sì rèé, ìyanṣẹ́lódì máa ń mú kí ilé ẹ̀kọ́ wà ní títìpa fún àkókò gígùn. Àwọn ibì kan sì tún wà tó jẹ́ pé ibi tí ilé ẹ̀kọ́ wà ti jìnnà jù tàbí kó tiẹ̀ máà sí rárá. Inúnibíni sáwọn Kristẹni tún máa ń mú kí wọ́n lé àwọn ọmọ wọn kúrò nílé ẹ̀kọ́.
Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ nínú irú àwọn ipò báwọ̀nyí? Kí lo lè ṣe ká ní àwọn ọmọ tó o ní pọ̀ díẹ̀ tí ọ̀ràn ìṣúnná owó níbi tó ò ń gbé kò sì jẹ́ kí gbogbo wọn lè lọ sílé ẹ̀kọ́? Ǹjẹ́ o lè rí owó láti rán ọ̀kan tàbí méjì nínú àwọn ọmọ rẹ lọ sílé ẹ̀kọ́? Ǹjẹ́ o lè rán wọn lọ sílé ẹ̀kọ́ láìní pa ipò tẹ̀mí wọn lára? Bí èyí bá ṣeé ṣe, àwọn wọ̀nyí lè kọ́ àwọn ọmọ tó kù láwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ nílé ẹ̀kọ́.
Àwọn orílẹ̀-èdè kan máa ń ní ètò ìwé àgbélékà.c Ọ̀kan nínú àwọn òbí ló sábà máa ń fi wákàtí mélòó kan kọ́ ọmọ rẹ̀ níwèé nínú ilé lójoojúmọ́. Láyé àwọn baba ńlá ìgbàanì, àwọn òbí máa ń kẹ́sẹ járí dáadáa nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ó ṣe kedere pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó múná dóko látọwọ́ òbí ló mú kí Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù lè ṣe àbójútó àwọn ẹlòmíràn nígbà tó tiẹ̀ ṣì kéré.
Ó lè máà ṣeé ṣe láti rí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ nílé ìwé ní àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi, àmọ́ àwọn òbí lè lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde láti kọ́ àwọn ọmọ wọn. Bí àpẹẹrẹ, Iwe Itan Bibeli Mi lè gbéṣẹ́ dáadáa láti fi kọ́ àwọn ọmọ wẹ́wẹ́. Ìwé ìròyìn Jí! ní àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí onírúurú ẹ̀kọ́. A lè fi ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? kọ́ wọn láwọn kókó tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì. Ìwé Yearbook of Jehovah’s Witnesses ní àwòrán àgbáyé kékeré nínú ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé àti ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù lónírúurú ilẹ̀.
Ó máa so èso rere gan-an tá a bá múra àwọn ìsọfúnni náà sílẹ̀ dáadáa tá a sì jẹ́ kó bá ibi tí òye àwọn ọmọ náà dé mu. Tí wọn ò bá ṣíwọ́ kíkàwé àti kíkọ́ ìwé, tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n láǹfààní láti lọ sílé ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ iwájú, pẹ̀lú ìrọ̀rùn ni ètò náà á fi bá wọn lára mu. Tó o bá ń lo ìdánúṣe tó o sì ń sapá, wàá lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti kàwé débi tó yẹ, èrè tó sì wà ńbẹ̀ kì í ṣe kékeré!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
c Wo àpilẹ̀kọ náà “Ìgbélékàwé—Ó Ha Wà fún Ọ Bí?” nínú Jí! ti April 8, 1993, ojú ìwé 9 sí 12.
[Àwòrán]
Kí lo lè ṣe tó o bá ń gbé níbi tí ò ti ṣeé ṣe fáwọn ọmọ rẹ láti lọ sílé ẹ̀kọ́?