ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/99 ojú ìwé 1
  • Lílọ sí Ilé Ìwé àti Àwọn Góńgó Rẹ Nípa Tẹ̀mí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lílọ sí Ilé Ìwé àti Àwọn Góńgó Rẹ Nípa Tẹ̀mí
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹkọ-iwe Pẹlu Ète Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bíbélì Ha Ṣàìfún Ẹ̀kọ́ Ìwé Níṣìírí Bí?
    Jí!—1998
  • Jàǹfààní Dídára Jù Lọ ní Ilé Ẹ̀kọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ojú Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wo Ẹ̀kọ́ Ìwé?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 8/99 ojú ìwé 1

Lílọ sí Ilé Ìwé àti Àwọn Góńgó Rẹ Nípa Tẹ̀mí

1 Níní ẹ̀kọ́ ìwé tó ṣe kókó nígbà tóo wà léwe lè pèsè òye ẹ̀kọ́ tóo nílò láti lè kàwé kí o sì lè kọ̀wé dáadáa kí o sì ní ìmọ̀ nípa oríṣiríṣi nǹkan bí ìmọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀, ìtàn, ìṣirò, àti sáyẹ́ǹsì. Níbi tóo ti ń ṣe èyí, o lè kẹ́kọ̀ọ́ bí a ṣe ń ronú jinlẹ̀, bí a ṣe ń ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àwọn òkodoro òtítọ́, bí a ṣe ń yanjú àwọn ìṣòro, àti bí a ṣe ń gbé àwọn àbá gbígbéṣẹ́ kalẹ̀. Irú ẹ̀kọ́ ìwé yẹn yóò ṣe ọ́ láǹfààní jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ. Báwo ni ẹ̀kọ́ ìwé rẹ ṣe lè tan mọ́ àwọn góńgó rẹ nípa tẹ̀mí nínú ìgbésí ayé kí ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jèrè “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú”?—Òwe 3:21, 22.

2 Di Ẹni Tó Wúlò Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run: Nígbà tí o ṣì wà ní ilé ìwé, máa fiyè sílẹ̀ ní kíláàsì, kí o sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ dáadáa. Bí o bá di ògbóṣáṣá nínú ìwé kíkà àti kíkẹ́kọ̀ọ́, yóò túbọ̀ rọrùn fún ọ láti máa ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí o sì máa jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí. (Ìṣe 17:11) Ìmọ̀ kíkúnrẹ́rẹ́ yóò mú kí o lè bá àwọn èèyàn tí wọ́n ní onírúurú ipò àtilẹ̀wá, ìfẹ́-ọkàn, àti ìgbàgbọ́ lò bí o ṣe ń bá wọn pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹ̀kọ́ ìwé tí o bá kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yóò wúlò bí o ṣe ń ṣe ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni nínú ètò àjọ Ọlọ́run.—Fi wé 2 Tímótì 2:21; 4:11.

3 Kọ́ Bóo Ṣe Lè Gbọ́ Bùkátà Ara Rẹ: Bóo bá sapá, o tún lè kọ́ iṣẹ́ tóo nílò láti lè máa gbọ́ bùkátà ara rẹ lẹ́yìn tóo bá gboyè jáde. (Fi wé 1 Tímótì 5:8.) Fara balẹ̀ yan àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tí o fẹ́ kọ́. Dípò kíkọ́ ẹ̀kọ́ tí a kì í tètè fi ríṣẹ́, ronú nípa kíkọ́ iṣẹ́ òwò tàbí iṣẹ́ ọwọ́ tí yóò mú kí o lè rí iṣẹ́ tó bójú mu ṣe níbikíbi. (Òwe 22:29) Irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ yóò mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti máa gbọ́ bùkátà ara rẹ bóo bá pinnu láti sìn níbi tí àìní gbé pọ̀.—Fi wé Ìṣe 18:1-4.

4 Kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìwé tó ṣe kókó tó dáa nígbà tóo ṣì wà nílé ìwé lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i. Ṣiṣẹ́ kára láti jèrè òye iṣẹ́ tóo nílò láti gbọ́ bùkátà ara rẹ bóo ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nípa báyìí, ilé ìwé tí o ń lọ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn góńgó rẹ nípa tẹ̀mí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́