ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/99 ojú ìwé 1
  • Gbé Orúkọ Rírẹwà Jèhófà Ga Gidigidi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbé Orúkọ Rírẹwà Jèhófà Ga Gidigidi
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • “Kí Orúkọ Rẹ Di Mímọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Jèhófà Gbé Orúkọ Rẹ̀ Lékè
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Sísọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 8/99 ojú ìwé 1

Gbé Orúkọ Rírẹwà Jèhófà Ga Gidigidi

1 Sátánì ba orúkọ Ọlọ́run jẹ́ nígbà tó sún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀. Èṣù dọ́gbọ́n sọ pé irọ́ ni Jèhófà pa fún Ádámù. (Jẹ́n. 3:1-5) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé orúkọ Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú agbára tó ní láti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Ọlọ́run ló tíì burú jù lọ. Nípa mímú ète àtọ̀runwá rẹ̀ ṣẹ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, Jèhófà ti mú ẹ̀gàn kúrò lára orúkọ rẹ̀, ó sì ti mú kí ó lẹ́wà.—Aísá. 63:12-14.

2 Àwa ni Jèhófà ‘fi orúkọ rẹ̀ pè.’ (Ìṣe 15:14, 17) Èyí fún wa láǹfààní láti fi ìmọ̀lára tí a ní nípa sísọ ọ́ di mímọ́ hàn. A rí i pé orúkọ Jèhófà lẹ́wà ní tòótọ́, níwọ̀n bó ti dúró fún gbogbo nǹkan dáadáa, onínúure, onífẹ̀ẹ́, aláàánú, àti olódodo. A ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún ìtóbilọ́lá orúkọ ológo Ọlọ́run. (Sm. 8:1; 99:3; 148:13) Kí ló yẹ ká sún wa láti ṣe?

3 Sọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ́: A ò tún lè sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ ju bó ṣe wà yìí. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìwà mímọ́ wa àti ìwàásù Ìjọba náà, a lè fi hàn pé a ń gbé orúkọ Ọlọ́run ga gidigidi. Ẹ jẹ́ ká polongo pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà! Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀. Ẹ sọ àwọn ìbánilò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Ẹ mẹ́nu kàn án pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé ga.” (Aísá. 12:4) Báwo la ṣe lè ṣe èyí?

4 A lè lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti pòkìkí orúkọ Jèhófà àti gbogbo ohun tí orúkọ náà ń ṣàpẹẹrẹ. Ì báà jẹ́ lọ́nà àṣà tàbí lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà, láti ilé dé ilé tàbí láti ilé ìtajà dé ilé ìtajà, ní òpópónà tàbí lórí tẹlifóònù, iṣẹ́ ìwàásù tí a ń ṣe ń bọlá fún Jèhófà. Nígbà tí a bá rí àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n tẹ́tí sílẹ̀, ó yẹ ká ṣe àdéhùn gúnmọ́ láti padà lọ láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà. Ìyẹn túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ pa àdéhùn mọ́ kí a sì máa sapá nìṣó kí a lè bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Ó múnú wa dùn pé, lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún wá ń mọ orúkọ rírẹwà Jèhófà, wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún un, wọ́n sì ń sọ ọ́ di mímọ́.

5 Fífi tí a bá ń fi tọkàntọkàn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ ń fi ìhà tí a wà nínú ọ̀ràn àríyànjiyàn tí Sátánì gbé dìde ní ọgbà Édẹ́nì hàn ní kedere. Èyí ni iṣẹ́ tó wúni lórí jù lọ, tó sì lọ́lá jù lọ tí a lè ṣe. Ẹ jẹ́ kí a máa gbé orúkọ rírẹwà Jèhófà ga gidigidi kí a sì máa fi ìtara yin orúkọ náà!—1 Kíró. 29:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́