ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Dáníẹ́lì 7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Dáníẹ́lì

      • Ìran àwọn ẹranko mẹ́rin (1-8)

        • Ìwo kékeré kan tó ń gbéra ga jáde (8)

      • Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé mú ìjókòó ní kọ́ọ̀tù (9-14)

        • Wọ́n fi ọmọ èèyàn ṣe ọba (13, 14)

      • A fi ìtumọ̀ han Dáníẹ́lì (15-28)

        • Ọba mẹ́rin ni àwọn ẹranko mẹ́rin náà (17)

        • Àwọn ẹni mímọ́ máa gba ìjọba (18)

        • Ìwo mẹ́wàá, tàbí ọba mẹ́wàá, máa dìde (24)

Dáníẹ́lì 7:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 5:1, 30
  • +Da 2:19; 8:1
  • +Ais 30:8; Hab 2:2; Ifi 1:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 129

Dáníẹ́lì 7:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 57:20; Ifi 17:15

Dáníẹ́lì 7:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 130

Dáníẹ́lì 7:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 2:37, 38
  • +Di 28:49, 50; Jer 48:40; Ida 4:19; Hab 1:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 131-132

Dáníẹ́lì 7:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 2:39; 5:28; 8:3, 20
  • +Ais 13:17, 18; Da 11:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 132-134

Dáníẹ́lì 7:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 2:39; 8:5; 11:3
  • +Da 8:8; 11:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2012, ojú ìwé 10-11

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 134-135

Dáníẹ́lì 7:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 2:40; 7:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2012, ojú ìwé 11, 14-15

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 135-137

Dáníẹ́lì 7:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó ń fọ́nnu.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:24
  • +Da 7:20; Ifi 13:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    5/2020, ojú ìwé 4

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2012, ojú ìwé 11, 14-15

    11/1/1993, ojú ìwé 9

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 137-141

Dáníẹ́lì 7:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 90:2; Da 7:13, 22; Hab 1:12
  • +Ais 6:1, 2; Ifi 4:2, 3
  • +Sm 104:1, 2
  • +Di 9:3; Heb 12:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 36

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 6 2016 ojú ìwé 5-6

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2012, ojú ìwé 18

    8/15/2008, ojú ìwé 17

    10/15/1995, ojú ìwé 19-20

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 144

Dáníẹ́lì 7:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 50:3; 97:3
  • +Di 33:2; 1Ọb 22:19; Sm 68:17; Heb 12:22; Jud 14; Ifi 5:11
  • +1Sa 2:10; Sm 50:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 36

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 6 2016 ojú ìwé 5-6

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2012, ojú ìwé 18

    11/15/1998, ojú ìwé 4-5

    10/15/1995, ojú ìwé 20

    10/1/1994, ojú ìwé 11

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 144

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 141-142

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 28-29

Dáníẹ́lì 7:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìfọ́nnu.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:8, 25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 145

Dáníẹ́lì 7:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 145

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 141-142

Dáníẹ́lì 7:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọsánmà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 24:30; Lk 21:27; Jo 3:13; Iṣe 7:56; Ifi 14:14
  • +Sm 90:2; Da 7:9, 22; Hab 1:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 145-146

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/1998, ojú ìwé 17-18

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 142

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 176

Dáníẹ́lì 7:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 2:6; 110:1, 2; Mt 28:18; 1Kọ 15:25; Ef 1:22; Ifi 3:21
  • +Flp 2:9-11
  • +Jẹ 49:10
  • +Sm 45:6; Ais 9:6, 7; Da 2:44; Lk 1:32, 33; Ifi 11:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 31

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 23

    2/1/1998, ojú ìwé 17-18

    Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 100

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 146

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 142

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 176

Dáníẹ́lì 7:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 8:27

Dáníẹ́lì 7:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:3
  • +Da 2:39, 40

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 130-131

Dáníẹ́lì 7:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:25, 27
  • +Mt 19:28; 2Ti 2:12; Ifi 3:21; 5:9, 10
  • +Da 7:21, 22; Lk 22:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 146-148

Dáníẹ́lì 7:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 2:40; 7:7

Dáníẹ́lì 7:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó ń fọ́nnu.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:24
  • +Da 7:8

Dáníẹ́lì 7:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 8:23, 24; 12:7; Ifi 13:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 141-144

Dáníẹ́lì 7:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 90:2; Da 7:9, 13; Hab 1:12
  • +Da 7:18, 27
  • +Mt 19:28; Lk 22:29; Ifi 1:6; 3:21; 5:9, 10; 20:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/1998, ojú ìwé 17-18

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 142-143

Dáníẹ́lì 7:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 2:40; 7:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 140

Dáníẹ́lì 7:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 135-141

Dáníẹ́lì 7:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:8
  • +Da 12:7; Ifi 13:5-7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 141-144, 177

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    8/1/1994, ojú ìwé 31

    11/1/1993, ojú ìwé 9-10

Dáníẹ́lì 7:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:10, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 145

Dáníẹ́lì 7:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:22; Mt 19:28; Lk 22:29; Ifi 20:4
  • +Ifi 11:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2005, ojú ìwé 16

    2/1/1998, ojú ìwé 17-18

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 146-148

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 142-143

    Ayọ, ojú ìwé 156

Dáníẹ́lì 7:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìrísí mi yí pa dà.”

Àwọn míì

Dán. 7:1Da 5:1, 30
Dán. 7:1Da 2:19; 8:1
Dán. 7:1Ais 30:8; Hab 2:2; Ifi 1:11
Dán. 7:2Ais 57:20; Ifi 17:15
Dán. 7:3Da 7:17
Dán. 7:4Da 2:37, 38
Dán. 7:4Di 28:49, 50; Jer 48:40; Ida 4:19; Hab 1:8
Dán. 7:5Da 2:39; 5:28; 8:3, 20
Dán. 7:5Ais 13:17, 18; Da 11:2
Dán. 7:6Da 2:39; 8:5; 11:3
Dán. 7:6Da 8:8; 11:4
Dán. 7:7Da 2:40; 7:19
Dán. 7:8Da 7:24
Dán. 7:8Da 7:20; Ifi 13:5
Dán. 7:9Sm 90:2; Da 7:13, 22; Hab 1:12
Dán. 7:9Ais 6:1, 2; Ifi 4:2, 3
Dán. 7:9Sm 104:1, 2
Dán. 7:9Di 9:3; Heb 12:29
Dán. 7:10Sm 50:3; 97:3
Dán. 7:10Di 33:2; 1Ọb 22:19; Sm 68:17; Heb 12:22; Jud 14; Ifi 5:11
Dán. 7:101Sa 2:10; Sm 50:6
Dán. 7:11Da 7:8, 25
Dán. 7:12Da 7:3
Dán. 7:13Mt 24:30; Lk 21:27; Jo 3:13; Iṣe 7:56; Ifi 14:14
Dán. 7:13Sm 90:2; Da 7:9, 22; Hab 1:12
Dán. 7:14Sm 2:6; 110:1, 2; Mt 28:18; 1Kọ 15:25; Ef 1:22; Ifi 3:21
Dán. 7:14Flp 2:9-11
Dán. 7:14Jẹ 49:10
Dán. 7:14Sm 45:6; Ais 9:6, 7; Da 2:44; Lk 1:32, 33; Ifi 11:15
Dán. 7:15Da 8:27
Dán. 7:17Da 7:3
Dán. 7:17Da 2:39, 40
Dán. 7:18Da 7:25, 27
Dán. 7:18Mt 19:28; 2Ti 2:12; Ifi 3:21; 5:9, 10
Dán. 7:18Da 7:21, 22; Lk 22:29
Dán. 7:19Da 2:40; 7:7
Dán. 7:20Da 7:24
Dán. 7:20Da 7:8
Dán. 7:21Da 8:23, 24; 12:7; Ifi 13:7
Dán. 7:22Sm 90:2; Da 7:9, 13; Hab 1:12
Dán. 7:22Da 7:18, 27
Dán. 7:22Mt 19:28; Lk 22:29; Ifi 1:6; 3:21; 5:9, 10; 20:4
Dán. 7:23Da 2:40; 7:7
Dán. 7:24Da 7:20
Dán. 7:25Da 7:8
Dán. 7:25Da 12:7; Ifi 13:5-7
Dán. 7:26Da 7:10, 11
Dán. 7:27Da 7:22; Mt 19:28; Lk 22:29; Ifi 20:4
Dán. 7:27Ifi 11:15
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Dáníẹ́lì 7:1-28

Dáníẹ́lì

7 Ní ọdún kìíní Bẹliṣásárì+ ọba Bábílónì, Dáníẹ́lì lá àlá, ó sì rí àwọn ìran nígbà tó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀.+ Ó wá kọ àlá náà sílẹ̀;+ ó kọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 2 Dáníẹ́lì sọ pé:

“Mò ń wò nínú ìran tí mo rí ní òru, sì wò ó! atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run ń ru alagbalúgbú òkun sókè.+ 3 Ẹranko ńlá mẹ́rin+ sì jáde látinú òkun, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra.

4 “Èyí àkọ́kọ́ dà bíi kìnnìún,+ ó sì ní ìyẹ́ idì.+ Mò ń wò ó títí a fi fa ìyẹ́ rẹ̀ tu, a sì gbé e sókè lórí ayé, a mú kó fi ẹsẹ̀ méjì dúró bí èèyàn, a sì fún un ní ọkàn èèyàn.

5 “Wò ó! ẹranko míì, èkejì, ó dà bíi bíárì.+ A gbé e sókè lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, egungun ìhà mẹ́ta sì wà ní ẹnu rẹ̀ láàárín eyín rẹ̀; a sì sọ fún un pé, ‘Dìde, jẹ ẹran púpọ̀.’+

6 “Lẹ́yìn èyí, mò ń wò, sì wò ó! ẹranko míì tó dà bí àmọ̀tẹ́kùn,+ àmọ́ tó ní ìyẹ́ mẹ́rin bíi ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ẹranko náà ní orí mẹ́rin,+ a sì fún un ní àṣẹ láti ṣàkóso.

7 “Lẹ́yìn èyí, mò ń wò nínú ìran òru, mo sì rí ẹranko kẹrin, ó ń bani lẹ́rù, ó sì ń dáyà jáni, agbára rẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì ní eyín ńlá tó jẹ́ irin. Ó ń jẹ nǹkan run, ó ń fọ́ nǹkan túútúú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ ohun tó ṣẹ́ kù mọ́lẹ̀.+ Ó yàtọ̀ sí gbogbo ẹranko yòókù tó wà ṣáájú rẹ̀, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. 8 Bí mo ṣe ń ronú nípa àwọn ìwo náà, wò ó! ìwo míì tó kéré  + jáde láàárín wọn, a sì fa mẹ́ta lára àwọn ìwo àkọ́kọ́ tu kúrò níwájú rẹ̀. Wò ó! ojú tó dà bíi ti èèyàn wà lára ìwo yìí, ó sì ní ẹnu tó ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.*+

9 “Mò ń wò títí a fi gbé àwọn ìtẹ́ kalẹ̀, tí Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé+ sì jókòó.+ Aṣọ rẹ̀ funfun bíi yìnyín,+ irun orí rẹ̀ sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ọwọ́ iná ni ìtẹ́ rẹ̀; iná tó ń jó ni àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀.+ 10 Iná ń ṣàn jáde lọ níwájú rẹ̀.+ Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró níwájú rẹ̀.+ Kọ́ọ̀tù+ jókòó, a sì ṣí àwọn ìwé.

11 “Mò ń wò nígbà yẹn torí bí mo ṣe ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga* tí ìwo náà ń sọ;+ mò ń wò ó títí a fi pa ẹranko náà, tí a pa ara rẹ̀ run, a sì jù ú sínú iná kó lè jó o. 12 Àmọ́ ní ti àwọn ẹranko yòókù,+ a gba àkóso lọ́wọ́ wọn, a sì mú kí ẹ̀mí wọn gùn sí i fún ìgbà kan àti àsìkò kan.

13 “Mò ń wò nínú ìran òru, sì wò ó! ẹnì kan bí ọmọ èèyàn+ ń bọ̀ pẹ̀lú ìkùukùu* ojú ọ̀run; a jẹ́ kó wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,+ wọ́n sì mú un wá sún mọ́ iwájú Ẹni yẹn. 14 A sì fún un ní àkóso,+ ọlá+ àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà máa sìn ín.+ Àkóso rẹ̀ jẹ́ àkóso tó máa wà títí láé, tí kò ní kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ ò sì ní pa run.+

15 “Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, ìdààmú bá ẹ̀mí mi nínú mi, torí àwọn ìran tí mo rí dẹ́rù bà mí.+ 16 Mo sún mọ́ ọ̀kan lára àwọn tó dúró síbẹ̀, kí n lè bi í ní ohun tí èyí túmọ̀ sí gan-an. Ó dá mi lóhùn, ó sì sọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan yìí fún mi.

17 “‘Ẹranko ńlá mẹ́rin+ yìí ni ọba mẹ́rin tó máa dìde ní ayé.+ 18 Àmọ́ àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ+ máa gba ìjọba,+ ìjọba náà sì máa jẹ́ tiwọn+ títí láé, àní títí láé àti láéláé.’

19 “Mo fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹranko kẹrin, tó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn yòókù; ó ń bani lẹ́rù lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó ní eyín irin àti èékánná bàbà, ó ń jẹ nǹkan run, ó ń fọ́ nǹkan túútúú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ ohun tó ṣẹ́ kù mọ́lẹ̀;+ 20 àti nípa ìwo mẹ́wàá+ tó wà ní orí rẹ̀ àti ìwo míì tó jáde, tí mẹ́ta sì ṣubú níwájú rẹ̀,+ ìwo tó ní ojú àti ẹnu tó ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga,* tí ìrísí rẹ̀ sì tóbi ju ti àwọn yòókù.

21 “Mò ń wò ó bí ìwo yẹn ṣe bá àwọn ẹni mímọ́ jagun, ó sì ń borí wọn,+ 22 títí Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé+ fi dé, tí a sì dá àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ láre,+ àkókò tí a yàn pé kí àwọn ẹni mímọ́ gba ìjọba sì dé.+

23 “Ohun tó sọ nìyí: ‘Ní ti ẹranko kẹrin, ìjọba kẹrin máa wà ní ayé. Ó máa yàtọ̀ sí gbogbo ìjọba yòókù, ó máa jẹ gbogbo ayé run, ó máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, ó sì máa fọ́ ọ túútúú.+ 24 Ní ti ìwo mẹ́wàá náà, ọba mẹ́wàá máa dìde látinú ìjọba yẹn, òmíràn tún máa dìde lẹ́yìn wọn, ó máa yàtọ̀ sí àwọn ti àkọ́kọ́, ó sì máa rẹ ọba mẹ́ta wálẹ̀.+ 25 Ó máa sọ̀rọ̀ sí Ẹni Gíga Jù Lọ,+ á sì máa fòòró àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ. Ó máa gbèrò láti yí àwọn àkókò àti òfin pa dà, a sì máa fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún àkókò kan, àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò.*+ 26 Àmọ́ Kọ́ọ̀tù jókòó, wọ́n gba àkóso lọ́wọ́ rẹ̀, kí wọ́n lè pa á rẹ́, kí wọ́n sì pa á run pátápátá.+

27 “‘A sì fún àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ ní ìjọba, àkóso àti títóbi àwọn ìjọba lábẹ́ gbogbo ọ̀run.+ Ìjọba tó máa wà títí láé ni ìjọba wọn,+ gbogbo ìjọba á máa sìn wọ́n, wọ́n á sì máa ṣègbọràn sí wọn.’

28 “Òpin ọ̀rọ̀ náà nìyí. Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, èrò ọkàn mi dẹ́rù bà mí gan-an, débi pé ara mi funfun;* àmọ́ mo fi ọ̀rọ̀ náà pa mọ́ sínú ọkàn mi.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́