Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 28
Orin 73 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 31 ìpínrọ̀ 1 sí 12 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 23-25 (8 min.)
No. 1: 2 Àwọn Ọba 23:8-15 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ibo Ni Èṣù Ti Wá?—wp13 2/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
No. 3: Kí Nìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Yẹra fún “Ìṣègbè”?—Ják. 2:1-4 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.”—Ìṣe 20:24.
10 min: Pọ́ọ̀lù Àtàwọn Alábàákẹ́gbẹ́ Rẹ̀ Jẹ́rìí Kúnnákúnná ní Ìlú Fílípì. Ìjíròrò. Ẹ ka Ìṣe 16:11-15. Ẹ jíròrò bí ìtàn yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
20 min: “Bá A Ṣe Lè Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 3, ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn tó ti múra sílẹ̀ dáadáa. Akéde náà ń fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lọ ẹnì kan, ó sì jíròrò ìpínrọ̀ kan pẹ̀lú ẹni náà.
Orin 114 àti Àdúrà