ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/15 ojú ìwé 2
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • “Ó Dí Àlàfo Tó Wà Lọ́kàn Mi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Lè Mú Kó O Fara Da Ìṣòro
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
km 9/15 ojú ìwé 2

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn

1. Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ October 19, ìwé wo la ó máa kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ?

1 Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ October 19, 2015, ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn ni a ó máa kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Ìtẹ̀jáde yìí sọ ìtàn nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin mẹ́rìnlá tí Bíbélì sọ pé wọ́n lo ìgbàgbọ́. Ìwé náà sọ ìtàn àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ yìí bíi pé a wà níbẹ̀, tí à ń rí bí wọ́n ṣe dojú kọ ìṣòro tí wọ́n sì sin Jèhófà. Ìwé yìí tún kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ tó máa wúlò fún wa lóde òní láti inú ìtàn àwọn olóòótọ́ yìí.​—Héb. 6:12.

2. Sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó wà nínú ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn.

2 Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí: Ìwé yìí ní àtẹ ìsọfúnni nípa àwọn ọdún tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú rẹ̀ wáyé àti àwòrán ilẹ̀ tó máa jẹ́ ká mọ ìgbà tí ẹni tá a sọ ìtàn rẹ̀ gbé ayé àti ibi tó gbé. Láfikún sí i, orí kọ̀ọ̀kàn ní apá tá a pè ní “Ohun Tó Yẹ Kó O Ronú Lé . . . ,” tó máa jẹ́ ká lè ṣàṣàrò lórí ìtàn tá a kà, ká sì fi àwọn ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nínú rẹ̀ sílò. Ìwé yìí tún ní àwọn àwòrán mèremère tá a fara balẹ̀ yà, tó sì ní ìsọfúnni kíkún táá jẹ́ kó dà bíi pé a wà níbẹ̀ nígbà tí ìtàn náà wáyé.

3. Kí ló yẹ ká ṣe láti lè jàǹfààní nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí?

3 Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní: Nínú Lẹ́tà látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé yìí, wọ́n gbà wá níyànjú pé: “Jẹ́ kó dà bíi pé o wà níbẹ̀; má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà. Gbìyànjú láti mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀, kó o sì rí ohun tí wọ́n rí. Kíyè sí ohun tí wọ́n ṣe lábẹ́ ipò pàtó kan, kó o sì wò ó bóyá ohun tí ìwọ náà máa ṣe nìyẹn.” Ti pé a ní ká jẹ́ kó dà bíi pé a wà níbẹ̀ kò túmọ̀ sí pé ká wá máa méfò láì nídìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ká máa fojú inú wo bí ìtàn tí Ọlọ́run mí sí yìí ṣe wáyé, ká sì fi ọ̀rọ̀ àwọn tí ìtàn náà kàn ro ara wa wò. Èyí gba pé ká lo àkókò láti fi ṣàṣàrò. (Neh. 8:8) Kí olùdarí kọ́kọ́ fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan ṣe àtúnyẹ̀wò ohun tẹ́ ẹ jíròrò gbẹ̀yìn, ìyẹn tí kì í bá ṣe àwọn ìpínrọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ orí náà lẹ máa jíròrò. Olùdarí lè béèrè ìbéèrè kan tàbí méjì láti fi ṣàtúnyẹ̀wò tí ibi tẹ́ ẹ jíròrò kò bá ní apá tá a pè ní “Ohun Tó Yẹ Kó O Ronú Lé . . . ”

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn?

4 À ń gbé nínú ayé tó jẹ́ pé ojoojúmọ́ là ń dojú kọ ohun tó lè mú kí ìgbàgbọ́ wa yìnrìn tàbí kó di ahẹrẹpẹ lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìwé yìí jẹ́ àti ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó ṣì ń jáde nínú Ilé Ìṣọ́ tá a ti mú u jáde, á sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. (Ják. 1:17) A máa jàǹfààní ìwé yìí lẹ́kùn ún rẹ́rẹ́ tá a bá ń pésẹ̀ déédéé sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, tá a sì ń lóhùn sí i bó bá ti lè ṣeé ṣe tó nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pa pọ̀!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́