ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/11 ojú ìwé 2
  • “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Lọ, Kí Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn . . . Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • “Títí Dé Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 2/11 ojú ìwé 2

“Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run

1. Ìwé wo la máa bẹ̀rẹ̀ sí í kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ March 14?

1 Ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní March 14 2011, a máa bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Ìwé náà ṣe àrúnkúnná ìwé Ìṣe lọ́nà tó ń múni lórí yá nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pípabanbarì tó wà níbẹ̀. Ìwé Jíjẹ́rìí kúnnákúnná kò jíròrò àwọn ẹsẹ tó wà nínú ìwé Ìṣe ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, àmọ́, ó sọ àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ látinú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣe, ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti rí bá a ṣe lè fí àwọn ohun tá a bá kọ́ sílò nígbèésí ayé wa.—Róòmù 15:4.

2. Sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó wà nínú ìwé Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná.

2 Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Náà: Ọ̀rọ̀ ìṣáájú tó wà lójú ìwé 2 jẹ́ lẹ́tà látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ṣàlàyé bí wọ́n ṣe fẹ́ ká jàǹfààní látinú ìwé náà. Bẹ̀rẹ̀ láti orí kejì, gbólóhùn kan wà tó sọ ohun tí orí náà dá lé, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tá a tọ́ka sí á sì jẹ́ ká mọ apá tá a máa jíròrò nínú ìwé Ìṣe. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn orí náà ní àwọn àpótí tá a kọ àfikún ìsọfúnni tó wúlò sí. Ó sọ nípa àwọn èèyàn, ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti wáyé àti irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ́. Àwọn àlàfo fífẹ̀ wà létí ìwé náà téèyàn lè máa kọ nǹkan sí bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn àwòrán mèremère tó ṣàlàyé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ fífani lọ́kàn mọ́ra tó wà nínú ìwé Ìṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti fojú inú yàwòrán ohun tó ń ṣẹlẹ̀ bá a ṣe ń ronú lórí àkọsílẹ̀ Bíbélì náà, atọ́ka àwòrán sì wà lójú ìwé tó kẹ́yìn tó ṣàlàyé ohun tí àwòrán kọ̀ọ̀kàn ń sọ. Èèpo iwájú àti ẹ̀yìn ìwé ní àwòrán ilẹ̀ tó máa jẹ́ ká lè máa fojú yàwòrán ìtẹ̀síwájú àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà ní ọ̀rúndún kìíní, bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìhìn rere lọ sí “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8.

3. Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo la máa rí ìdáhùn sí tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìṣe?

3 Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì: Tá a bá jíròrò ìwé Ìṣe, ó máa jẹ́ ká rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ àti ìhìn wo la fi ń dá àwọn ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Jésù Kristi mọ̀? Ta ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé, ọ̀nà wo ló sì ń gbà darí rẹ̀? Àǹfààní wo ni inúnibíni àti àtakò ṣí sílẹ̀ fún àwọn òjíṣẹ́? Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

4. Báwo la ṣe máa jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná?

4 Kó o lè jàǹfààní tó pọ látinú ìwé yìí, máa múra ibi tá a máa kà sílẹ̀, kó o sì múra tán láti kópa nígbà tá a bá ń jíròrò rẹ̀ ní ìpàdé. Máa wá sí gbogbo ìpàdé, kó o sì ronú lórí bó o ṣe lè fi àwọn ohun tó o kọ́ sílò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Àdúrà wa ni pé kí kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí sún wa láti túbọ̀ máa jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run!—Ìṣe 28:23.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́