Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 28
Orin 5 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 18 ìpínrọ̀ 10 sí 18 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́sítérì 1-5 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Sọ Ohun Tó Ṣàǹfààní. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 202. Fi ìwé tá a máa lò lóde ẹ̀rí lóṣù tó ń bọ̀ ṣe àṣefihàn àbá tó wà ní ìpínrọ̀ tó gbẹ̀yìn.
10 min: Jàǹfààní Látinú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Ìjíròrò tá a gbé ka ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ ti ọdún 2011. Fún àwọn ará ní ìṣírí láti máa ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́. Ní kí àwọn ará sọ àkókò tí wọ́n ti yà sọ́tọ̀ láti máa fi ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti àǹfààní tí wọ́n ti rí nínú rẹ̀. Ní ṣókí sọ̀rọ̀ lórí Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2011. Jíròrò àpilẹ̀kọ náà “A Ò Ní Máa Jíròrò Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ojoojúmọ́ Ní Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Mọ́.”
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn ní Oṣù March. Ìjíròrò. Láàárín ìṣẹ́jú kan sí méjì, mẹ́nu ba ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Lẹ́yìn náà, yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta nínú àwọn ìwé ìròyìn náà, kó o wá ní kí àwùjọ sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà.
Orin 33 àti Àdúrà