ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ojú ìwé 2-3
  • Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Ohun Tó O Kọ́ Ní Apá 2
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Àwọn Wo Ló Ń ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀
    Jí!—2019
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ojú ìwé 2-3
Ìdílé kan ń lo Bíbélì bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì pa pọ̀

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ẹ̀yin Ará Wa Ọ̀wọ́n Tá A Jọ Ń Sin Jèhófà:

Gbogbo àwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà la nífẹ̀ẹ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó dá wa lójú pé àwọn ìtàn inú Bíbélì pé pérépéré, a gbà pé àwọn ìtọ́ni inú ẹ̀ lè ṣe wá láǹfààní, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. (Sáàmù 119:105; Lúùkù 1:3; 1 Jòhánù 4:19) Ó wù wá gan-an pé ká ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn òtítọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Torí náà, inú wa dùn láti mú ìwé tuntun yìí jáde, ìyẹn “Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì.” Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa ìwé náà.

Òótọ́ ni pé àwọn ọmọdé la dìídì ṣe ìwé yìí fún, síbẹ̀ a lè lò ó láti ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Torí pé gbogbo èèyàn ni Bíbélì wà fún, a máa jàǹfààní tó pọ̀ gan-an tá a bá gbé àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ yẹ̀ wò. Ìdí sì ni pé àwọn ẹ̀kọ́ náà máa ń fúnni láyọ̀.

Àwọn ìtàn inú Bíbélì ló wà nínú ìwé yìí, bẹ̀rẹ̀ látorí ohun tó ṣẹlẹ̀ látìgbà tí Ọlọ́run ti dá àwa èèyàn. A kọ àwọn ìtàn náà lọ́nà tó rọrùn tó sì ṣe kedere, a sì gbìyànjú láti sọ àwọn ìtàn náà bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra.

Yàtọ̀ síyẹn, a kọ ọ́ lọ́nà tó fi máa dùn-ún kà. A fi àwòrán mèremère kún un, a sì ṣe é lọ́nà téèyàn á fi lè fojú inú wo bí nǹkan ṣe rí lára àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn, èyí á lè jẹ́ kó dà bíi pé a wà níbẹ̀ nígbà tó ń ṣẹlẹ̀.

Ìwé yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tí Bíbélì mẹ́nu kàn, ìyẹn àwọn tó ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn tí kò ṣègbọràn sí i. Ó sì tún sọ àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ lára wọn. (Róòmù 15:4; 1 Kọ́ríńtì 10:6) Apá mẹ́rìnlá (14) ni ìwé yìí pín sí. Níbẹ̀rẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan, a máa rí àkópọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tá a máa kọ́ nínú apá náà.

Ẹ̀yin òbí, tẹ́ ẹ bá ń ka àwọn ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan fáwọn ọmọ yín, ẹ máa ṣàlàyé àwòrán inú ẹ̀. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ jọ ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n ti mú ẹ̀kọ́ náà jáde. Rí i pé o ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè mọ bí ohun tó ń kà nínú àwọn ẹ̀kọ́ yẹn ṣe tan mọ́ ohun tó wà nínú Bíbélì. A lè lo ọ̀nà kan náà tá a bá ń kọ́ àgbàlagbà nípa ohun tí Bíbélì dá lé.

A nírètí pé ìwé yìí á ran tèwetàgbà tó lọ́kàn rere lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì fi àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ sílò nígbèésí ayé wọn. Èyí á jẹ́ káwọn náà lè dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn àtàtà tó ń jọ́sìn Jèhófà.

Àwa arákùnrin yín,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́