Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 8
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 8
Orin 6 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 17 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 1-5 (10 min.)
No. 1: Jóṣúà 1:1-18 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Wọ́n Fi Kórìíra Àwọn Kristẹni Tòótọ́—td 6A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣiṣẹ́—lr orí 42 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Máa Mú àwọn “ohun rere” jáde láti inú ìṣúra rere tá a fi sí ìkáwọ́ wa.—Mát.12:35á.
10 min: “Àwọn Ohun Rere” Tá A Máa Gbádùn Lóṣù Yìí. Àsọyé. Tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí. (Mát. 12:35á) Ọ̀dọ̀ ẹni tó kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ la ti gba àwọn ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ìṣúra tẹ̀mí yìí. (Wo Ilé Ìṣọ́ April 1, 2002, ojú ìwé 16 àti 17, ìpínrọ̀ 5 sí 7.) Ó yẹ kí àwa náà sọ “àwọn ohun rere” tí a mọ̀ fún àwọn ẹlòmíì. (Gál. 6:6) Ṣe iṣẹ́ yìí lọ́nà tí “àwọn ohun rere” tí a ó gbádùn ní àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsín tá a máa ṣe lóṣù yìí á fi wu àwọn ará. A ó kọ́ nípa bí a ṣe lè mú ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa sunwọ̀n sí i, a ó sì tún kọ́ àwọn orin tuntun.
20 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Nínú Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Han Àwọn Èèyàn.” Ìjíròrò. Kí akéde kan tàbí aṣáájú-ọ̀nà kan tó tóótun ṣe àṣefihàn kan, kó fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni han ẹni tó wàásù fún.
Orin 96 àti Àdúrà