Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù December
“À ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ìdílé láti bá wọn jíròrò kókó pàtàkì kan tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ òbí fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ẹ rò pé ó yẹ kí àwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àbí ṣe ló yẹ kí àwọn ọmọ kọ́ bí wọ́n á ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run fúnra wọn?” Jẹ́ kó fèsì. Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ December 1 han onílé, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ó kéré tán, ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ December 1
“À ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ká lè bá wọn sọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa Ọlọ́run. A mọ̀ pé kálukú ló ní èrò tirẹ̀ nípa Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ẹ rò pé ọ̀pọ̀ èèyàn ka Ọlọ́run sí ọ̀rẹ́ àti ẹni tó bìkítà nípa wọn àbí wọ́n kà á sí ẹni tí wọn ò lè bá ṣọ̀rẹ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ irú àjọṣe tí Ọlọ́run fẹ́ ká ní pẹ̀lú òun. [Ka Jákọ́bù 4:8(á)] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn nǹkan mẹ́ta tí a lè ṣe ká lè sún mọ́ Ọlọ́run.”
Ji! November–December
“À ń ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn láti jíròrò àwọn ìbéèrè pàtàkì kan tó dá lórí kókó ọ̀rọ̀ kan nínú ìwé ìròyìn yìí. [Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 8 hàn án.] Ǹjẹ́ ẹnì kan tiẹ̀ wà tó ń gbọ́ àdúrà wa? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká mọ Ọlọ́run, ká sì mọ̀ nípa àdúrà. [Ka Aísáyà 55:6.] A lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ fàlàlà nínú àdúrà torí kò jìnnà sí ẹnikẹ́ni nínú wa. Àmọ́ kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa, báwo ló ṣe yẹ ká gbàdúrà? Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn nǹkan tó yẹ ká mọ̀ nípa àwọn àdúrà tí Ọlọ́run máa ń gbọ́.”