Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 15
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 15
Orin 1 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 17 ìpínrọ̀ 9 sí 16 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 6-8 (10 min.)
No. 1: Jóṣúà 8:18-29 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Aya Kò Gbọ́dọ̀ Gba Ọkọ Láyè Láti Mú Kó Pa Ìjọsìn Ọlọ́run Tì—td 6B (5 min.)
No. 3: Àwọn Wo Ni Arákùnrin àti Arábìnrin Wa?—lr orí 43 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Máa Mú àwọn “ohun rere” jáde láti inú ìṣúra rere tá a fi sí ìkáwọ́ wa.—Mát. 12:35á.
15 min: “Bí A Ṣe Lè Máa Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́nà Tó Múná Dóko.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 3, ṣe àṣefihàn alápá méjì tó dá lórí bí akéde kan ṣe ń bá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ jíròrò ìpínrọ̀ 8 nínú orí 15 ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Nínú àṣefihàn àkọ́kọ́, akéde náà sọ̀rọ̀ púpọ̀ jù. Nínú àṣefihàn kejì, akéde náà béèrè ìbéèrè tó jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí akéde náà mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.
15 min: Apá Tó O Lè Fi Múra Bí Wàá Ṣe Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìjíròrò. Sọ fún àwọn ará pé apá kan wà lórí ìkànnì jw.org/yo tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni?” (Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́.) Jíròrò bí ẹ ṣe lè lo ohun tó wà ní apá yìí láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó gbẹ́ṣẹ́ pẹ̀lú onírúurú èèyàn yálà ọmọdé tàbí àgbàlagbà. Báwo làwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀ ṣe lè jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? Ṣe àṣefihàn akéde kan tó ń dá sọ̀rọ̀ bó ṣe ń lo ọ̀kan lára àwọn ìwé àjákọ tó ní ìbéèrè àti àlàfo nínú láti múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀, ó ń ronú nípa àwọn ìbéèrè tó gbéṣẹ́ tó máa bi ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, èyí táá jẹ́ kó lè ràn án lọ́wọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, fún gbogbo àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n sapá láti di olùkọ́ tó sunwọ̀n sí i, nípa fífi àwọn ohun rere tá a ní ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, kí òtítọ́ Bíbélì lè wọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn lọ́kàn.—Òwe 20:5.
Orin 99 àti Àdúrà