Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I —Bí O Ṣe Lè Fi Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Lọni
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ni ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Àmọ́, ká tó lè máa fi ìwé yìí kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, ó yẹ ká ti kọ́kọ́ fún un. Torí náà, ó yẹ kí gbogbo wa sapá láti mọ bí a ṣe ń fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lọni lọ́nà tó já fáfá lóde ẹ̀rí. (Òwe 22:29) Onírúurú ọ̀nà la lè gbà fi ìwé yìí lọni, a sì lè lò ó lọ́nà kan tá a ti rí i pé ó gbéṣẹ́.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Ṣe ìdánrawò bí o ṣe lè lo ìwé yìí nígbà ìjọsìn ìdílé yín.
Tó o bá wà lóde ẹ̀rí, sọ bó o ṣe fẹ́ fi ìwé yìí lọni fún akéde tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́. (Òwe 27:17) O lè yí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ padà tó o bá rí i pé kò gbéṣẹ́ tó.