Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 16
Orin 17 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
ia orí 2 ìpínrọ̀ 13 sí 23, àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 24 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 26-29 (8 min.)
No. 1: 1 Kíróníkà 29:20-30 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Nìdí Tí Jésù Fi Ń Pa Dà Bọ̀?—wp13 12/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Fi Ń Pa Àṣẹ Tó Wà Nínú Róòmù 12:19 Mọ́ (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Oṣù Yìí: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà.”—1 Kọ́r. 3:6.
10 min: Máa ‘Bomi Rin’ Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Wa. (1 Kọ́r. 3:6-8) Fi ọ̀rọ̀ wá aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan àti akéde kan lẹ́nu wò. Ètò wo ni wọ́n ti ṣe kí wọ́n lè máa ṣé ìpadàbẹ̀wò? Báwo ni wọ́n ṣe máa ń múra sílẹ̀? Kí làwọn nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe kí wọ́n lè bá ẹni tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ nílé tí wọ́n bá padà lọ? Àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni wo ni wọ́n ní?
20 min: “Bí A Ṣe Lè Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Gbohùn Wọn Sílẹ̀.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ bí àwọn ará ṣe lè rí àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ìkànnì jw.org/yo. Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn ìrírí tó wà ní ìparí àpilẹ̀kọ náà, “Máa Lo Ìkànnì Wa Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ—‘Ohun Tí Bíbélì Sọ’” èyí tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2014.
Orin 108 àti Àdúrà