Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 9
Orin 48 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
ia orí 2 ìpínrọ̀ 1 sí 12 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 21-25 (8 min.)
No. 1: 1 Kíróníkà 23:1-11 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Ríronú Lórí Ohun Tó Wà ní Róòmù 8:32 Ṣe Mú Kó Dá Wa Lójú Pé Gbogbo Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ? (5 min.)
No. 3: Báwo Ni Àjíǹde Ṣe Máa Rí?—wp13 10/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3 àti 4 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà.”—1 Kọ́r. 3:6.
10 min: “Èmi Gbìn, Àpólò Bomi Rin, Ṣùgbọ́n Ọlọ́run Ń Mú Kí Ó Máa Dàgbà.” Àsọyé tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí. (1 Kọ́r. 3:6) Bí àkókò bá ṣe wà sí, fi àlàyé tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ March 1, 1993, ojú ìwé 20 sí 23 kún ọ̀rọ̀ rẹ. Mẹ́nu ba àwọn apá kan nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti oṣù yìí, kó o sì sọ bí wọ́n ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí.
20 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fi Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Lọni.” Ìjíròrò. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn méjì. Àṣefihàn àkọ́kọ́ dá lórí ọ̀kan lára àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àṣefihàn kejì sì dá lórí ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí akéde kan ti gbà fi ìwé yìí lọni.
Orin 111 àti Àdúrà