‘Fífúnrúgbìn Ìjọba’ ní Ipa Ọ̀nà Ìwé Ìròyìn
1 Orin 133 nínú ìwé Kọrin Ìyìn sí Jehofah ni a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Fifunrugbin Ijọba.” Orí àkàwé Jésù tí ó fi iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn wé fífúnrúgbìn ni a gbé e kà. (Mát. 13:4-8, 19-23) Ọ̀rọ̀ orin náà kà pé: “Melo ninu irugbin rẹ ló bọ́ silẹ rere/Ọwọ́ rẹ leyi wà púpọ̀.” Báwo ni a ṣe lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbéṣẹ́ sí i? Bíbẹ̀rẹ̀ ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn àti bíbá a nìṣó jẹ́ ọ̀nà kan.
2 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn lè ṣe àṣeparí rẹ̀. (1) Ìbẹ̀wò déédéé ní ọ̀sẹ̀ méjì-méjì yóò mú kí o lè ní ipò ìbátan ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ẹni tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn. (2) O ń bá a nìṣó láti máa fún ẹni yẹn ní ìsọfúnni agbẹ̀mílà déédéé, èyí tí ó wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! (3) Nípasẹ̀ ìjíròrò rẹ, o lè ran ẹni náà lọ́wọ́ láti máa ní ìyánhànhàn fún òtítọ́ Ìwé Mímọ́, tí ó lè ṣamọ̀nà sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—1 Pét. 2:2.
3 Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ipa Ọ̀nà Ìwé Ìròyìn: Nígbàkígbà tí ẹnì kan bá fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú àwọn ìwé ìròyìn wa, ṣàlàyé pé àwọn àpilẹ̀kọ tí ó tayọ máa ń jáde nínú ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan àti pé inú rẹ yóò dùn láti máa mú wọn wá fún un ní ọ̀sẹ̀ méjì-méjì. Nígbà tí o bá kúrò níbẹ̀, kọ orúkọ àti àdírẹ́sì ẹni náà sílẹ̀, kọ ọjọ́ tí o ṣe ìkésíni náà, déètì àwọn ìtẹ̀jáde tí o fi sóde, àpilẹ̀kọ tí ó sọ̀rọ̀ lé, àti kókó ẹ̀kọ́ tí ẹni náà lọ́kàn-ìfẹ́ sí ní pàtàkì.
4 O lè bẹ̀rẹ̀ ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn pẹ̀lú ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀. Lẹ́yìn náà, sakun láti mú kí wọ́n pọ̀ sí i nípa fífi àwọn mìíràn tí wọ́n bá gba àwọn ìwé ìròyìn lọ́wọ́ rẹ kún un. Bí ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ ṣe ń pọ̀ sí i, o lè pín in sí ìpínlẹ̀-ìpínlẹ̀ kí ó lè rọrùn fún ọ láti kárí. Máa fara balẹ̀ ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde tí o bá fi sóde nígbàkígbà tí o bá ṣe ìkésíni kí o sì kọ àkókò tí o ṣe é. Tún ṣàkọsílẹ̀ ohun tí ẹ jíròrò àti bí o ṣe lè máa bá a nìṣó láti mú kí ọkàn-ìfẹ́ ẹni náà nínú òtítọ́ pọ̀ sí i nígbà ìbẹ̀wò tí yóò tẹ̀ lé e.
5 Fi Àwọn Oníṣòwò àti Oníṣẹ́ Ọwọ́ Kún Un: Ìrírí ti fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn oníṣòwò àti àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ mìíràn máa gba ìwé ìròyìn wa déédéé. Alàgbà kan tilẹ̀ ní ẹnì kan tí ó jẹ́ olórí ìlú lára ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ̀. Akéde kan bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹni 80 ọdún kan, tí ó ń ta ohun èlò ìkọ́lé lẹ́yìn tí ó ti fún un ní àwọn ìwé ìròyìn fún ọdún mẹ́wàá tẹ̀lératẹ̀léra!
6 Arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan wọ inú ilé ìtajà kan, ó sì pàdé tọkọtaya kan tí kò fi ọ̀yàyà tẹ́wọ́ gbà á. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí wọ́n ti gba àwọn ìwé ìròyìn, ó pinnu láti fi tọkọtaya náà kún ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ̀. Bí àkókò ti ń lọ, arábìnrin náà kò fẹ́ máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn mọ́ níwọ̀n bí wọn kò ti ní ìwà ọ̀rẹ́ tí wọn kì í sì máa ń fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ àní nígbà tí ó bá béèrè ìbéèrè tí ń wádìí ọkàn wò pàápàá. Ṣùgbọ́n arábìnrin náà gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tọkọtaya náà gba ìwé Walaaye Titilae lọ́wọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ìyàwó kà á, ó kígbe pé: “Mo rí òtítọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín!” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tọkọtaya náà sì ṣe batisí lẹ́yìn náà. Ní ti gidi, ìforítì aṣáájú ọ̀nà náà so èso rere.
7 Ṣíṣe Àwọn Ìpadàbẹ̀wò: Nígbà tí o bá gba ìwé ìròyìn tuntun, ka gbogbo àpilẹ̀kọ rẹ̀. Wá àwọn kókó tí yóò fa ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó wà ní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ mọ́ra. Nígbà tí o bá wá padà dé ọ̀dọ̀ ẹni náà, o lè sọ pé: “Bí mo ṣe ń ka àpilẹ̀kọ yìí, mo ronú nípa rẹ àti bí yóò ṣe fà ọ́ lọ́kàn-mọ́ra.” Àwọn akéde tí wọ́n jẹ́ onírúurú ọjọ́ orí lè gbádùn níní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn. Ọmọdé pàápàá lè sọ pé: “Mo láyọ̀ láti tún rí yín. Àwọn ẹ̀dà tuntun Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tiyín ti dé. Mo rò pé ẹ óò fẹ́ràn àpilẹ̀kọ yìí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní . . .”
8 Ru ìháragàgà sókè fún àwọn àpilẹ̀kọ tí ń bọ̀ nípa pípe àfiyèsí sí àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Nínú Ìtẹ̀jáde Wa Tí Ń Bọ̀.” Nígbà tí àwọn àpilẹ̀kọ bá jáde ní ọ̀wọ́-ọ̀wọ́, tọ́ka sí èyí kí o sì fún òǹkàwé níṣìírí pé kí ó má ṣe fo èyíkéyìí nínú rẹ̀. Má ṣe gbàgbé pé o lè ka ìpadàbẹ̀wò nígbàkígbà tí o bá mú ìwé ìròyìn lọ fún ẹnì kan tí ó wà ní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, rántí pé sísọ ìkésíni wọ̀nyí di ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé ni góńgó wa.
9 Máa Bẹ Àwọn Ènìyàn Tí Ó Wà ní Ipa Ọ̀nà Ìwé Ìròyìn Rẹ̀ Wò Déédéé: O lè kárí ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ ní àkókò èyíkéyìí tí ó bá gbéṣẹ́—ní àárọ̀ àwọn ọjọ́ àárín ọ̀sẹ̀, ní ọ̀sán, ní ìrọ̀lẹ́, tàbí ní òpin ọ̀sẹ̀ lẹ́yìn tí o bá ti lo àkókò nínú iṣẹ́ ilé dé ilé. Bí o kò bá lè kárí ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ nítorí pé ara rẹ kò yá tàbí nítorí pé o wà lẹ́nu ìsinmi, sọ pé kí akéde mìíràn nínú ìdílé rẹ tàbí nínú ìjọ rẹ bá ọ fún wọn ní àwọn ìwé ìròyìn náà. Lọ́nà yẹn, àwọn tí ó wà ní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ kì yóò kùnà láti rí àwọn ìwé ìròyìn wọn gbà lákòókò.
10 Mímú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ fún àwọn tí ó wà ní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ déédéé jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà fúnrúgbìn Ìjọba náà. Bí o ti ń kọ́ wọn ní òtítọ́ Ìwé Mímọ́, wọ́n lè lóye ọ̀rọ̀ Ìjọba náà, wọ́n sì lè so èso Ìjọba náà bí tìrẹ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.—Mát. 13:8, 23.