Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Wá Àwọn Tí Wàá Máa Fún Ní Ìwé Ìròyìn Déédéé
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó máa ń gbádùn kíka àwọn ìwé ìròyìn wa ni kì í fẹ́ ká máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n lè sọ pé ẹ̀sìn táwọn ń ṣe ti tẹ́ àwọn lọ́rùn tàbí kí wọ́n sọ pé àwọn ò ráyè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, bí wọ́n ṣe ń ka àwọn ìwé ìròyìn wa déédéé, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìyánhànhàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Pét. 2:2) Àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n kà lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an tàbí kí ipò wọn yí pa dà. Tá a bá ń ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ wọn déédéé, èyí á mú kí ara tù wọ́n nígbà tá a bá wà pẹ̀lú wọn, àwa náà á sì lè mọ ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àtàwọn ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a lè wá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Ṣàkọsílẹ̀ orúkọ àwọn tó o lè máa fún ní ìwé ìròyìn déédéé. Fún wọn ní àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, kó o sì sọ fún wọn pé wàá wá fún wọn ní èyí tó máa jáde tẹ̀ lé e.