Gbogbo Ènìyàn Gbọ́dọ̀ ‘Gba Ọ̀rọ̀ Náà Tọkàntọkàn’!
1 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láti tóótun fún ìyè àìnípẹ̀kun, wọ́n gbọ́dọ̀ ‘gba ọ̀rọ̀ náà tọkàntọkàn,’ gẹ́gẹ́ bí àwọn 3,000 tí ó ronú pìwà dà tí wọ́n sì ṣe batisí ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa ti ṣe. (Ìṣe 2:41) Ẹrù iṣẹ́ wo ni èyí gbé lé wa léjìká lóde òní?
2 A gbọ́dọ̀ ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ láti mú ìfọkànsìn fún Jèhófà dàgbà. (1 Tím. 4:7-10) Láti ṣe èyí, àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, ìpínrọ̀ 20, dábàá pé: “Jálẹ̀ àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, wá àyè láti mú ìmọrírì rẹ̀ dàgbà fún àwọn ànímọ́ Jèhófà. Sọ ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí o ní fún Ọlọ́run jáde. Ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti ronú nípa mímú ipò ìbátan ọlọ́yàyà, ti ara ẹni, dàgbà pẹ̀lú Jèhófà.”
3 Ìpèníjà Tí A Dojú kọ: Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ìsìn èké nípa lé lórí ni ìjọsìn tí ń gba àkókò àti ìsapá díẹ̀, tí kò sì béèrè fún ojúlówó ìyípadà kankan nínú ìgbésí ayé wọn, tẹ́ lọ́rùn. (2 Tím. 3:5) Ìpèníjà tí ó dojú kọ wá ni láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ láti rí i pé ìjọsìn tòótọ́ ní nínú ju jíjẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan. Wọ́n gbọ́dọ̀ fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò nínú ìgbésí ayé wọn. (Ják. 1:22-25) Bí ohun kan nípa ìwà àwọn fúnra wọn kò bá ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó di dandan gbọ̀n fún wọn láti “yí padà” kí wọ́n sì ṣe ohun tí ó tọ́ láti wù ú. (Ìṣe 3:19) Láti jèrè ìyè ayérayé, wọ́n gbọ́dọ̀ “tiraka tokuntokun” kí wọ́n sì mú ìdúró ṣinṣin wọn fún òtítọ́.—Lúùkù 13:24, 25.
4 Nígbà tí ẹ bá ń jíròrò oríṣiríṣi ọ̀nà ìwà rere, bi akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ léèrè ojú ìwòye tí ó ní nípa ọ̀ràn náà ní ti gidi àti ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣe bí ó bá rí ìdí láti ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Darí àfiyèsí rẹ̀ sí ètò àjọ tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kí o sì gbà á níyànjú láti máa wá sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé.—Héb. 10:25.
5 Ẹ jẹ́ kí mímú kí ẹ̀kọ́ wa wọ akẹ́kọ̀ọ́ lọ́kàn jẹ́ ìfojúsùn wa. Inú wa yóò mà dùn o, bí a ti ń mú kí àwọn ẹni tuntun gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọkàntọkàn kí wọ́n sì ṣe batisí!—1 Tẹs. 2:13.