ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/98 ojú ìwé 7
  • Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Akọ̀wé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Akọ̀wé
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Òjíṣẹ́ Tó Ń Wàásù Ìhìn Rere
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ṣé Ò Ń Ṣe Ipa Tìrẹ Ká Lè Ṣàkójọ Ìròyìn Tó Pé Pérépéré?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 10/98 ojú ìwé 7

Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Akọ̀wé

1 Akọ̀wé ìjọ ń kó ipa pàtàkì láti rí i dájú pé ‘ohun gbogbo ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.’ (1 Kọ́r. 14:40) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ, ó ń bójú tó àwọn lẹ́tà ìjọ àti àwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ lè má hàn sí gbogbo ènìyàn bí ti àwọn alàgbà yòókù, a nílò iṣẹ́ rẹ̀ gidigidi, a sì mọrírì iṣẹ́ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀.

2 Nígbà tí a bá gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ Society tàbí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, akọ̀wé ni ó máa ń bójú tó o tí yóò sì rí sí i pé a fèsì nígbà tí ó bá pọndandan. Ó máa ń rí i dájú pé àwọn lẹ́tà tí a rí gbà lọ yí ká láàárín àwọn alàgbà yóò sì wá fi wọ́n sínú fáìlì fún ìtọ́kasí. Ó máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn fọ́ọ̀mù tí a fi ń béèrè fún ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Society. Ní tààràtà, òun ni ó máa ń ṣe kòkáárí àwọn tí ń bójú tó àkáǹtì àti àsansílẹ̀ owó títí kan gbogbo ọ̀ràn tí ó bá jẹ mọ́ àpéjọpọ̀.

3 Níwọ̀n bí akọ̀wé ti gbọ́dọ̀ fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ìjọ lóṣooṣù ránṣẹ́ sí Society ní ọjọ́ kẹfà oṣù, ó pọndandan pé kí gbogbo wa máa ròyìn ìgbòkègbodò pápá wa lọ́gán ní ìparí oṣù kọ̀ọ̀kan. Yóò wá kọ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn náà sínú káàdì Congregation’s Publisher Record. Akéde èyíkéyìí lè béèrè pé òun fẹ́ rí àkọsílẹ̀ ìgbòkègbodò tòun.

4 Nígbà tí akéde kan bá ṣí wá sí ìjọ kan tàbí bí ó bá ṣí lọ, akọ̀wé ni ó máa ń béèrè fún lẹ́tà ìfinimọni àti káàdì Congregation’s Publisher Record ẹni yẹn lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ tí ẹni yẹn ti wá, akọ̀wé náà sì ni ó máa ń kó wọn ránṣẹ́ sí ìjọ tí ẹnì kan bá ṣí lọ.—Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 104 àti 105.

5 Akọ̀wé ni ó máa ń ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò àwọn aṣáájú ọ̀nà, òun ni ó máa ń sọ fún àwọn alàgbà, pàápàá alábòójútó iṣẹ́ ìsìn nípa àwọn ìṣòro èyíkéyìí tí àwọn aṣáájú ọ̀nà bá ń dojú kọ. Ó máa ń pe àfiyèsí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ sí àwọn akéde tí wọn kò bá ṣe déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn máa ń mú ipò iwájú ní ṣíṣe kòkáárí àwọn ìsapá láti bójú tó àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́.—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, February 1989, ojú ìwé 1.

6 Bí a ṣe túbọ̀ ń mọrírì àwọn iṣẹ́ akọ̀wé, ẹ jẹ́ kí a ṣe ohun tí a lè ṣe láti mú kí iṣẹ́ ìríjú rẹ̀ túbọ̀ rọrùn fún un láti ṣe láṣeparí.—1 Kọ́r. 4:2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́