Ṣé Ò Ń Ṣe Ipa Tìrẹ Ká Lè Ṣàkójọ Ìròyìn Tó Pé Pérépéré?
1 Ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ Bíbélì ló ní àwọn nọ́ńbà pàtó nínú, èyí tó mú kí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ túbọ̀ ṣe kedere sí wa. Bí àpẹẹrẹ, Gídíónì ṣẹ́gun àgọ́ Mídíánì pẹ̀lú kìkì ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin péré. (Oníd. 7:7) Áńgẹ́lì Jèhófà pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ọmọ ogun Ásíríà. (2 Ọba 19:35) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn ló ṣe batisí, kété lẹ́yìn náà sì ni nọ́ńbà àwọn onígbàgbọ́ ròkè sí ẹgbẹ̀rún márùn-ún. (Ìṣe 2:41; 4:4) Ó hàn gbangba látinú àwọn àkọsílẹ̀ yìí pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ayé ọjọ́un sapá gidigidi láti ṣàkójọ àkọsílẹ̀ pípé pérépéré.
2 Lóde òní, ètò àjọ Jèhófà fún wa ní ìtọ́ni pé ká máa ròyìn ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá wa ní oṣooṣù. Bí a ti ń fi ìṣòtítọ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò yìí ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà di èyí tí à ń bójú tó lọ́nà gbígbéṣẹ́. Àwọn ìròyìn náà lè jẹ́ ká rí i pé apá ibì kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà nílò àfiyèsí tàbí pé a máa nílò àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i ní àgbègbè kan. Nínú ìjọ, ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá máa ń jẹ́ kí àwọn alàgbà mọ àwọn tó lè ṣeé ṣe fún láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i àtàwọn tó lè nílò ìrànlọ́wọ́. Bákan náà, àwọn ìròyìn nípa bí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ṣe ń tẹ̀ síwájú máa ń fún gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ará lápapọ̀ níṣìírí. Ṣé ò ń ṣe ipa tìrẹ kó lè ṣeé ṣe láti ṣàkójọ ìròyìn tó pé pérépéré?
3 Ojúṣe Tìrẹ: Nígbà tí oṣù bá dé ìlàjì àti nígbà tó bá parí, ǹjẹ́ ó máa ń ṣòro fún ọ láti rántí ohun tó o ti ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé wàá kúkú máa kọ ìgbòkègbodò rẹ sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà tó o bá ti kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá? Àwọn kan máa ń lo kàlẹ́ńdà tàbí ìwé àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́. Àwọn mìíràn sì máa ń mú ìwé pélébé tá a fi ń kọ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́wọ́ lọ sí òde ẹ̀rí. Tí oṣù bá ti dé ìlàjì àti nígbà tó bá parí, mú ìròyìn rẹ fún alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ ní kánmọ́. Tàbí kẹ̀, bó o bá fẹ́, o lè lọ fi ìròyìn rẹ sínú àpótí tí à ń fi ìròyìn sí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó o bá gbàgbé láti fi ìròyìn rẹ sílẹ̀, tètè jẹ́ kí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ mọ̀ dípò tí wàá fi dúró dìgbà tó máa wá bá ọ. Fífi tọkàntọkàn ròyìn ìgbòkègbodò rẹ ń fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún ìṣètò Jèhófà àti pé o ní ìgbatẹnirò onífẹ̀ẹ́ fún àwọn arákùnrin tá a yàn láti máa gba ìròyìn kí wọ́n sì máa ṣàkójọ àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀.—Lúùkù 16:10.
4 Ojúṣe Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ: Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn tó wà lójúfò tó sì bìkítà, alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa ń kíyè sí ìgbòkègbodò àwùjọ náà jálẹ̀ oṣù. (Òwe 27:23) Ó máa ń mọ̀ bóyá akéde kọ̀ọ̀kan ń kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn, àti pé bóyá ipa tó ń kó nítumọ̀, tó sì ń fún un láyọ̀, ó sì máa ń tètè pèsè ìrànlọ́wọ́ bí àwọn kan bá wà tí wọn kò tíì jáde rárá nínú oṣù kan. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí ẹnì kan nílò látọ̀dọ̀ alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kò ju pé kó fún ní ọ̀rọ̀ ìṣírí, ìdámọ̀ràn tó lè ṣèrànwọ́, tàbí kó ké sí i pé káwọn jọ lọ sóde ẹ̀rí.
5 Tí oṣù bá ti parí, alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa ń rí i dájú pé gbogbo àwọn tó wà nínú àwùjọ náà ṣe ojúṣe wọn nípa ríròyìn iṣẹ́ wọn kó lè ṣeé ṣe fún akọ̀wé láti fi ìròyìn ìjọ tó pé pérépéré ránṣẹ́ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka ní, ó pẹ́ tán ọjọ́ kẹfà oṣù tó máa tẹ̀ lé e. Bí oṣù bá ti ń parí lọ, ó dára kí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa rán àwùjọ náà létí, pàápàá àwọn tí kò bá fi ìròyìn ìlàjì oṣù sílẹ̀, kó sì jẹ́ kí ìwé pélébé tá a fi ń kọ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó níbi tá a ti ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan máa ń gbàgbé láti ròyìn ìgbòkègbodò wọn, ó lè fún wọn ní ìránnilétí tó bójú mu àti ìṣírí.
6 Fífi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa sílẹ̀ ní kánmọ́ ń jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ṣàkójọ ìròyìn tó ń fi àwọn ohun tá a ti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn pápá hàn lọ́nà pípé pérépéré. Ṣé wàá ṣe ipa tìrẹ nípa títètè máa ròyìn iṣẹ́ ìsìn rẹ lóṣooṣù?