ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/98 ojú ìwé 1
  • Ẹ̀mí Jèhófà Wà Pẹ̀lú Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀mí Jèhófà Wà Pẹ̀lú Wa
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ni Orukọ Ẹmi Mímọ́’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Kristẹni ní Ọ̀rúndún Kìíní ó Sì Ń Darí Àwa Náà Lónìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí Kó O Sì Mú Ẹ̀jẹ́ Ìyàsímímọ́ Rẹ Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Bí Ẹ̀mí Ọlọrun Ṣe Lè Nípalórí Rẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 5/98 ojú ìwé 1

Ẹ̀mí Jèhófà Wà Pẹ̀lú Wa

1 Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a ní ẹrù iṣẹ́ bàǹtàbanta tí a yàn fún wa. Jésù wí pé: “A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10) Bí a bá fi ojú ìwòye ènìyàn wò ó, èyí yóò dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀. Ipá tí ó lágbára jù lọ lágbàáyé ni ó ń tì wá lẹ́yìn—ẹ̀mí Ọlọ́run.—Mát. 19:26.

2 Ẹ̀rí Ọ̀rúndún Kìíní: Nígbà tí Jésù ń sọ bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe ní ìmúṣẹ sí òun lára, ó wí pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi . . . láti polongo ìhìn rere.” (Lúùkù 4:17, 18) Ṣáájú kí ó tó gòkè re ọ̀run, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ yóò fún àwọn pẹ̀lú lágbára láti jẹ́rìí “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” Lẹ́yìn ìgbà náà, ẹ̀mí mímọ́ darí Fílípì láti wàásù fún òṣìṣẹ́ láàfin kan tí ó jẹ́ ará Etiópíà, ó rán Pétérù sí olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó jẹ́ ará Róòmù, ó sì tún rán Pọ́ọ̀lù àti Bánábà jáde láti wàásù fún àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí. Ta ní ti lè ronú pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ní irú ipò àtilẹ̀wá bẹ́ẹ̀ yóò dáhùn padà sí òtítọ́? Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 1:8; 8:29-38; 10:19, 20, 44-48; 13:2-4, 46-48.

3 Ẹ̀rí Òde Òní: Ìwé Ìṣípayá tẹnu mọ́ ipa tí ẹ̀mí mímọ́ yóò kó nínú iṣẹ́ ìwàásù lónìí nípa sísọ pé: “Ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’ . . . Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣí. 22:17) Ẹ̀mí náà ti sún ẹgbẹ́ ìyàwó Kristi àti “àwọn àgùntàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn láti wàásù ìhìn rere náà fún gbogbo ènìyàn. (Jòh. 10:16) Ó yẹ kí a jẹ́ onígboyà nínú bí a ṣe ń wàásù, kí a má ṣe lọ́ tìkọ̀ láé láti tọ onírúurú ènìyàn lọ, kí a máa ní ìgbọ́kànlé nígbà gbogbo pé ẹ̀mí Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́. Ìwé 1998 Yearbook pèsè ẹ̀rí dídánilójú pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń wà nìṣó pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ẹ wo bí a ṣe ṣàṣeyọrí tó! Ní àwọn ọdún iṣẹ́ ìsìn méjì tó kọjá, ó ju ìpíndọ́gba 1,000 ènìyàn tí a batisí lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.

4 Ẹ ní ìdánilójú pé ẹ̀mí Ọlọ́run yóò máa bá wa lọ bí a ti ń wàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà dé àyè tí Jèhófà fẹ́. Mímọ èyí yẹ kí ó fún wa níṣìírí kí ó sì sún wa láti máa bá a nìṣó láti lo ara wa tokunratokunra nínú iṣẹ́ Ìjọba náà tí ó ṣe pàtàkì gidigidi yìí.—1 Tím. 4:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́