Bí Ẹ̀mí Ọlọrun Ṣe Lè Nípalórí Rẹ
“NÍ ÀTÈTÈKỌ́ṢE Ọlọrun dá ọ̀run oun ayé. Aye si wa ni júujùu, o si ṣófo; òkùnkùn si wa loju ibu: Ẹmi Ọlọrun si ńràbàbà loju omi.” (Jẹnẹsisi 1:1, 2) Gbolohun-ọrọ Iwe Mimọ yii tẹnumọ ọna ti o han gbangba ninu eyi ti olukuluku ẹni ti o walaaye ti janfaani lati inu ẹmi mimọ. Ẹmi yẹn gbékánkánṣiṣẹ́ nigba iṣẹda, ọpẹ́ si ni fun iṣẹ rẹ̀, ilẹ-aye di ile onídùnnú fun araye.
Awọn eniyan le jàǹfààní pupọ sii lati ọwọ ẹmi mimọ. Owe onímìísí kan wipe: “Ẹ yipada ni ibawi mi; kiyesi i, emi o da ẹmi mi sinu yin, emi o fi ọrọ mi han fun yin.” (Owe 1:23) Ni ọjọ wa “ọrọ” Ọlọrun ti a kójọ wà larọwọọto ninu Bibeli Mimọ, ti a kọ lati ọwọ awọn ọkunrin ti ‘a dari lati ọwọ́ ẹmi mimọ wá.’ (2 Peteru 1:21; Maaku 12:36; 2 Timoti 3:16) Nigbakugba ti ẹni oninu tutu kan ba ka Bibeli, oun jàǹfààní lati ọdọ ẹmi mimọ.
Ẹmi Mimọ Ati Iṣẹ Iwaasu
Nigbati ọkan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa ba kesi ọ ninu ile rẹ lati ba ọ sọrọ nipa ihinrere ijọba naa, ẹmi mimọ le nipalori igbesi-aye rẹ ni ọna miiran. Bawo ni a ṣe mọ? O dara, nigbati Jesu Kristi bẹrẹ sii waasu ihinrere, oun fisilo fun ara rẹ awọn ọrọ Wolii Aisaya, ti o wipe: “Ẹmi Oluwa [“Jehofa,” NW] nbẹ lara mi: nitori o ti fi àmì ororo yan mi lati wàásù ihinrere fun awọn otoṣi; . . . lati kede ọdun ìtẹ́wọ́gbà Oluwa [“Jehofa,” NW].” (Luku 4:18, 19; Aisaya 61:1, 2) Bẹẹni, Jesu ni a fami-ororo-yan nipasẹ ẹmi mimọ lati wàásù ihinrere.
Ju bẹẹ lọ, Jesu sọtẹlẹ pe iwaasu ihinrere yoo maa baalọ lẹhin iku rẹ. Oun sọtẹlẹ pe: “A o si wàásù ihinrere ijọba yii ni gbogbo aye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigbanaa ni opin yoo si de.” (Matiu 24:14) Ni igba kukuru ṣaaju ki Jesu to goke re ọ̀run, oun fun awọn ọmọlẹhin rẹ ni isẹ-aṣẹ yi: “Ẹ lọ, . . . ẹ maa kọ orilẹ-ede gbogbo, ki ẹ si maa baptisi wọn ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti ẹmi mimọ: ki ẹ maa kọ wọn lati maa kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa ni aṣẹ fun yin.” (Matiu 28:19, 20) Lẹhin igoke re ọrun Kristi, awọn ọmọ-ẹhin rẹ nba iṣẹ wiwaasu ati kikọni ti a fi ẹmi palaṣẹ naa lọ. Awọn Ẹlẹrii Jehofa loni nṣafarawe awọn ọmọ-ẹhin ijimiji wọnni ninu wiwaasu ihinrere naa yika-aye.
Baptism ati Ẹmi Mimọ
Nigbati ẹnikan ba finúdídùn dahunpada si ihinrere naa, Jesu wipe oun ni a nilati baptisi “ni orukọ Baba, ati niti ọmọ, ati niti ẹmi mimọ.” Nitorinaa awọn ọmọ-ẹhin titun ni ẹmi mimọ nípalórí wọn siwaju si. Ọ̀rọ̀ naa “ni orukọ ti” tumọ niti gidi si “nipa ọla-aṣẹ ti” tabi “mimọyi ipo ti.”a Fun idi yii, jijẹ ẹni ti a baptisi ni orukọ Baba tumọsi titẹwọgba ipo-ọba-alaṣẹ Ọlọrun ninu igbesi-aye wa laiṣiyemeji. Baptism ni orukọ Ọmọkunrin tumọsi titẹwọgba Jesu gẹgẹbi Olùtúnràpadà, awofiṣapẹrẹ, ati Ọba. Baptism ni orukọ ẹmi mimọ si wemọ gbígbójúlé ẹmi naa ati jijuwọsilẹ fun agbara rẹ.b
Ẹmi Mimọ ninu Igbesi-aye Rẹ
Lọna ti o banininujẹ, àbòsí, iwa-palapala, iwa-ipa, ati iwa-ailofin nibi gbogbo ti a nri ninu awọn ilẹ “Kristian” taṣiri otitọ naa pe ọpọjulọ awọn wọnni ti wọn nfẹnujẹwọ jijẹ Kristian ndena ẹmi mimọ niti gidi. Ṣugbọn awọn wọnni ti wọn juwọsilẹ fun un ni a bukun fun gidigidi. Fun ìdí kan, wọn gba ohun ti wọn ka ninu Bibeli ti a fi ẹmi misi lọna ṣiṣepataki wọn si fi silo ninu igbesi-aye wọn. Nipa bayi, wọn ni ọgbọn, ijinlẹ-oye, agbára idajọ, igbọnfefe, imọ, ati agbara ironu. (Owe 1:1-4) Awọn wọnyi jẹ ọrọ̀-ìní ṣiṣeyebiye ni awọn akoko onijangbọn wa.
Ẹmi mimọ tun nran iru awọn ẹni bẹẹ lọwọ lati ṣẹpa awọn iṣoro lilekoko. Ni igba atijọ, Ọlọrun fi han awọn eniyan rẹ̀ bi wọn yoo ṣe le ṣaṣepari iṣẹ kan ti o lekoko gan-an. Jehofa wipe a o ṣee “kii ṣe nipa ipá, kii ṣe nipa agbara, bikose nipa ẹ̀mí [rẹ̀].” (Sẹkaraya 4:6) Bi awa ba juwọsilẹ fun Ọlọrun ati ẹ̀mí rẹ, a o tun ran wa lọwọ lati ṣaṣepari awọn iṣẹ a o si bori awọn ohun-ìdinà ti ìbá ti tobiju fun wa ni ọna miiran.—Matiu 6:33; Filippi 4:13.
Siwaju sii, ẹmi Ọlọrun ńràn wa lọwọ lati gbadun ominira ti aye ko mọ nigbogbogboo. Apọsteli Pọọlu kọwe: “Nibiti ẹmi Oluwa [“Jehofa,” NW] ba si wa, nibẹ ni ominira gbe wa.” (2 Kọrinti 3:17) Awọn wọnni ti wọn juwọsilẹ fun ẹmi Ọlọrun ngbadun ominira kuro ninu isin èké, igbagbọ ninu ohun asán, ibẹru ọjọ iwaju, ati ọpọlọpọ ohun amúnilẹ́rú miiran. Ẹmi Ọlọrun nitootọ jẹ agbara fun rere o tilẹ le yi awọn eniyan pada. Bibeli sọ eyi nigbati o wipe: “Eso ti ẹmi ni ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwa pẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, ìwà tutu, ati ikora-ẹni-nijaanu, ofin kan ko lodi si iru wọnni.” (Galatia 5:22, 23) Bawo ni aye yii yoo ti yatọ to bi gbogbo eniyan ba juwọsilẹ fun ẹmi Ọlọrun lati nipalori wọn!
Gẹgẹbi awujọ kan, awọn ojulowo Kristian tun gbadun ‘iṣọkan ẹmi ninu ìdè alaafia ti nsonipọṣọkan.’ (Efesu 4:3, NW) Iṣọkan ati alaafia jẹ awọn ohun koṣeemanii ṣiṣọwọn lonii. Ṣugbọn wọn wa nibiti ẹmi Ọlọrun ti ngbekankanṣiṣẹ. Nitootọ, láàárín awọn Ẹlẹrii Jehofa ìdè ẹmi mimọ ti nsonipọṣọkan ti mu awọn eniyan gbogbo ẹya-iran, ede, ati orilẹ-ede-ìbí wa sinu ojulowo “ẹgbẹ awọn ara.”—1 Peteru 2:17, NW.
Ẹmi Ọlọrun ati Iwọ
Njẹ iwọ ri ere ti níní ọgbọn ti Ọlọrun fifunni ati ti gbigbadun ominira tootọ? Ki yoo ha jẹ agbayanu lati ni iranlọwọ atọrunwa ninu yiyanju awọn iṣoro ati mimu ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwa pẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwa tutu, ati ikora-ẹni-nijaanu dagba bi? Nigba naa juwọsilẹ fun agbara ẹmi mimọ Ọlọrun. Ṣugbọn bawo ni ẹnikan ṣe lè ṣe eyi?
Jẹki Ọrọ Ọlọrun, Bibeli, lo agbara idari lori ero-inu ati ọkan-aya rẹ. Kẹgbẹpọ pẹlu awọn wọnni ti wọn jẹ ki ẹmi mimọ lo agbara idari lori igbesi-aye wọn. Gbe awọn igbesẹ nisinsinyi lati kẹkọọ ki o si ṣe ifẹ-inu Ọlọrun. Nigbanaa, “njẹ ki Ọlọrun ireti ki o fi gbogbo ayọ ohun alaafia kun yin ni gbigbagbọ, ki ẹyin ki o le pọ ni ireti nipa agbara ẹmi mimọ.”—Romu 15:13.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fiwera pẹlu ọrọ Gẹẹsi naa “in the name of the law” [“ni orukọ ofin”]. Tun wo Matiu 10:41 ninu King James Version, nibiti Jesu ti lo awọn ọrọ naa “ni orukọ wolii” ati “ni orukọ olododo.”
b Wo asọye Peteru fun awọn Júù ni Pentecost 33 C.E. nigbati oun ṣalaye ọpọlọpọ apa-iha ninu ipa ti Jesu ati ẹmi mimọ kó ninu igbesi-aye awọn onigbagbọ ti a ti baptisi. Lẹhin asọye rẹ, 3,000 ni a baptisi ni orukọ Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mimọ.—Iṣe 2:14-42.