Dida Ẹmi Mimọ Mọyatọ
NJẸ iwọ ha mọ pe ẹmi mimọ nipalori igbesi-aye olukuluku wa? Iwọ ha si mọ̀dájú pe o le mu igbesi-aye rẹ sunwọn si lọpọlọpọ bi? Eyi le ya ọ lẹnu. Niti tootọ, iwọ le beere pe: ‘Tani tabi kinni ẹmi mimọ naa?’
Bi iwọ ba jẹ mẹmba ọkan lara awọn ṣọọṣi Kristendom, o ṣeeṣe ki o ti gbọ ti alufa kan sàmì fun ọmọ-ọwọ kan “ni orukọ ti Baba ati ti Ọmọkunrin ati ti Ẹmi Mimọ.” (Matiu 28:19, The New English Bible) Nigbati a ba bi wọn lati sọ ohun ti ẹmi mimọ jẹ, ọpọjulọ awọn alufa nyara dahunpada pe: ‘Ẹmi mimọ jẹ ẹni kẹta ninu Mẹtalọkan, o baradọgba ni gbogbo ọna pẹlu Ọlọrun Baba naa ati Oluwa Jesu Kristi.’
Bi o ti wu ki o ri, oju-iwoye yii ni a kó dìmú ni awọn ọrundun diẹ ti ó ṣaaju Sanmanni Tiwa. Lati ṣakawe: Ni nnkan bii ọ̀rúndún mẹta lẹhin iku awọn apọsteli Jesu Kristi, Gregory ti Nazianzus kọwe pe: “Awọn kan lero pe [ẹmi mimọ naa] jẹ agbara kan (energeia), awọn kan sọ pe iṣẹda, awọn kan pe e ni Ọlọrun, awọn kan ko le pinnu eyi ti o jẹ́ ninu iwọnyi.”
Loni, ọpọjulọ ṣọọṣi Kristendom tẹwọgba oju-iwoye ẹlẹkọọ Mẹtalọkan nipa ẹmi mimọ. Ṣugbọn iyẹn ha ni ohun ti Bibeli tilẹhin bi? Tabi o wulẹ jẹ ero ti a gbekari ẹkọ atọwọdọwọ? Niti gasikia, Bibeli ko sọrọ ri nipa ẹmi mimọ ni ọna kanna ti o gba sọrọ nipa Ọlọrun tabi Jesu. Fun apẹẹrẹ, ninu Bibeli, ẹmi mimọ ko ni orukọ tirẹ funraarẹ.
Eyiini ha wulẹ jẹ kulẹkulẹ alaijamọ-nkan bi? Bẹẹkọ, orukọ ṣepataki ninu Bibeli. Ọlọrun tẹnumọ ijẹpataki orukọ oun tikaraarẹ nigbati o wipe: “Emi ni Oluwa [“Jehofah,” New World Translation]: eyi ni orukọ mi: ogo mi ni emi ki yoo fifun ẹlomiran, bẹẹni emi ki yoo fi iyin mi fun ere gbígbẹ́.” (Aisaya 42:8) Ijẹpataki orukọ Jesu Kristi ni a tẹnumọ ṣaaju ibi rẹ̀ nigbati angẹli kan sọ fun Maria pe: “Iwọ o si pe orukọ rẹ ni Jesu.” (Luku 1:31) Bi orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin ba ṣepataki tobẹẹ, eeṣe ti ẹmi mimọ ko fi ni orukọ tirẹ funraarẹ? Dajudaju, kulẹkulẹ yi nikan nilati mu ki enikan ṣe kàyééfì boya ẹmi naa baradọgba nitootọ pẹlu Baba ati Ọmọkunrin naa.
Awọn Iwe Mimọ ati Ẹmi Mimọ Naa
Ninu Iwe Mimọ lede Heberu tabi “Majẹmu Laelae,” a tọka si “ẹmi mimọ” ati si “ẹmi [Ọlọrun] mi.” (Saamu 51:11; Joẹli 2:28, 29) Awa ka pe ẹnikan le kun fun ẹmi mimọ, ó le wá sori ẹni naa ki o si ràdọ̀ bo o mọlẹ. (Ẹksodu 31:3; Onidaajọ 3:10; 6:34) Diẹ lara ẹmi mimọ Ọlọrun ni a le mu lati ara ẹnikan ki a si fun ẹlomiran. (Numeri 11:17, 25) Ẹmi mimọ le di eyi ti o bẹrẹ sii ṣiṣẹ lara ẹnikan, ni fifun un lagbara lati pitú ti o ju ti ẹda-eniyan lọ.—Onidaajọ 14:6; 1 Samueli 10:6.
Ipari ero wo ni a le fi ilọgbọn-ninu dé lati inu iru awọn gbolohun ọrọ bẹẹ? Dajudaju ki yoo jẹ pe ẹmi mimọ jẹ ẹnikan. Bawo ni a ṣe le mu apakan ẹnikan ki a si fifun ẹlomiran? Ju bẹẹ lọ, ko si ẹri pe nigbati Jesu wa lori ilẹ-aye, awọn Júù oluṣotitọ wo ẹmi mimọ gẹgẹbi ẹnikan ti o baradọgba pẹlu Baba. Laisi àníàní wọn ko jọsin ẹmi mimọ. Kaka bẹẹ, ijọsin wọn ni a dari-taarata si Jehofa nikanṣoṣo, Ẹni naa ti Jesu funraarẹ pe ni “Baba mi” ati “Ọlọrun mi.”—Johanu 20:17.
Bi ti Majẹmu Laelae gẹgẹbi a ti npe e, apakan Bibeli ti a npe ni Iwe Mimọ Kristian lede Giriiki, tabi “Majẹmu Titun,” wipe ẹnikan le ‘kun’ fun ẹmi mimọ tabi ki o wà “lori” rẹ. (Iṣe 2:4; Luku 2:25-27) Ẹmi mimọ ni a ‘fifunni,’ ‘tú sori,’ ti a si ‘pinkiri.’ (Luku 11:13; Iṣe 10:45; Heberu 2:4, NW) Ni Pentecost 33 C.E., awọn ọmọ-ẹhin gba “diẹ lara” ẹmi Ọlọrun. (Iṣe 2:17) Iwe Mimọ tun sọ nipa baptism ati fifami-ororo-yanni pẹlu ẹmi mimọ—Matiu 3:11; Iṣe 1:5; 10:38.
Iru awọn gbolohun-ọrọ Bibeli bẹẹ fi ẹri han pe ẹmi mimọ kii ṣe ẹnikan. Ipari-ero yii ni a tubọ tilẹhin nigbati a fi ẹmi mimọ kun akọsilẹ lẹsẹẹsẹ awọn ohun alaijẹ ẹni gidi miran. Fun apẹẹrẹ-atilẹhin, Bibeli wipe Stefanu “kun fun igbagbọ ati fun ẹmi mimọ.” (Iṣe 6:5) Apọsteli Pọọlu si fi ara rẹ̀ han gẹgẹ bi ojiṣẹ Ọlọrun “nipa iwa mimọ, nipa imọ, nipa ipamọra, nipa iṣeun, nipa ẹmi mimọ, nipa ifẹ aiṣẹtan.”—2 Kọrinti 6:4-6.
Loootọ, nigba miiran Bibeli maa ńṣàkàwé ẹmi mimọ bí ẹni gidi kan. Fun apẹẹrẹ, Aisaya wipe awọn ọlọtẹ kan bayi ‘mu ẹmi mimọ rẹ binu.’ (Aisaya 63:10) Pọọlu wipe a le ‘ko ẹdun-ọkan ba a.’ (Efesu 4:30, NW) Awọn ẹsẹ Iwe mimọ kan si wipe ẹmi mimọ ńkọ́ni, tọnisọna, sọrọ, ati jẹrii. (Johanu 14:26; 16:13, 14; 1 Johanu 5:7, 8) Ṣugbọn Bibeli tun ṣakawe awọn ohun aláìlẹ́mìí miiran bi ẹni gidi kan, iru bi ọgbọn, iku, ati ẹṣẹ. (Owe 1:20; Romu 5:17, 21) Niti gidi eyi jẹ ọna kan ti ngbe àwòrán yọ sọkan ninu eyi ti awọn Iwe Mimọ nigba miiran maa nṣalaye awọn nǹkan.
Awa lonii, nsọrọ lọna kan naa nipa Bibeli nigbati a ba wipe o sọ ohun kan tabi kọni ni ekọ-igbagbọ kan. Ni lilo iru awọn ọrọ sisọ bẹẹ, awa ko ni in lọkan pe Bibeli jẹ ẹnikan, awa ha ṣe bẹẹ bi? Bẹẹ ni Bibeli ko ni lọkan pe ẹmi mimọ jẹ ẹnikan nigbati o lo awọn ọrọ aláfiwe.
Nigbanaa, kinni ẹmi mimọ jẹ? Kii ṣe ẹnikan. Kaka bẹẹ, o jẹ ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun funraarẹ, ti oun nlo lati ṣaṣepari awọn ifẹ-inu rẹ. (Jẹnẹsisi 1:2) Ṣugbọn bawo ni ẹmi mimọ ṣe nipalori igbesi-aye wa? Ati bawo ni a ṣe le jàǹfààní gẹgẹbi ẹnikan ninu iṣẹ rẹ?