Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 19
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 19
Orin 131 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 7 ìpínrọ̀ 9 sí 17 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 30-33 (10 min.)
No. 1: Ẹ́kísódù 32:1-14 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ṣé Gbogbo Ìsìn Ló Dáa?—td 5B (5 min.)
No. 3: Ǹjẹ́ O Máa Ń Rántí Láti Dúpẹ́?—lr orí 18 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Ìdí Tá A Fi Jẹ́ Òjíṣẹ́ Ìhìn Rere. Àsọyé tó ń tani jí tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 77 sí 78, ìpínrọ̀ 2. Ní kí àwọn ará sọ ohun tó mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti máa jáde òde ẹ̀rí.
10 min: Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ ní Àkókò Ìsinmi? Ìjíròrò. Ní ṣókí, jíròrò àwọn ohun tí à ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ bó ṣe wà nínú ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 113 ìpínrọ̀ 1. Ní kí àwọn tó ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní àkókò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tàbí ilé ẹ̀kọ́ sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n ti rí. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n sapá láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní àkókò ìsinmi wọn tó ń bọ̀.
10 min: “Jẹ́ Kó Mọ́ Ẹ Lára Láti Máa Dé Lásìkò.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ní kí àwọn ará sọ ohun tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n fi máa ń dé lásìkò.
Orin 44 àti Àdúrà