Orin 114
Ìwé Ọlọ́run Jẹ́ Ìṣúra
(Òwe 2:1)
1. Ìwé kan wà tọ́rọ̀ rẹ̀ ńmú ayọ̀ wá,
Àti àlàáfíà fún aráyé.
Ọ̀rọ̀ àgbàyanu
rẹ̀ lágbára gan-an;
Ó ńmú “òkú” yè, “afọ́jú” ńríran.
Bíbélì Mímọ́ nìwé àtàtà yìí.
Ọlọ́run ló
mí sí àwọn tó kọọ́,
Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wọn lóòótọ́,
Ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ló sì darí wọn.
2. Wọ́n kọ ìtàn tòótọ́ nípa ìṣẹ̀dá,
Bí Jáà ṣe dá ayé àti ọ̀run.
Àti pé tẹ́lẹ̀ rí èèyàn jẹ́ pípé
Àti bí Párádísè ṣe pòórá.
Wọ́n tún sọ nípa áńgẹ́lì tó tàpá
Sípò ọba aláṣẹ Jèhófà.
Èyí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ òun ìbànújẹ́,
Ṣùgbọ́n Jèhófà yóò ṣẹ́gun láìpẹ́.
3. Ìgbà ayọ̀ àìlẹ́gbẹ́ la wà báyìí.
Ìjọba ọ̀run dé lábẹ́ Kristi.
Ọjọ́ ìgbàlà Jèhófà fún gbogbo
Àwọn tó ńṣe ìfẹ́ rẹ̀ la wà yìí.
Ìhìn ayọ̀ yìí wà nínú ìwé rẹ̀;
Oúnjẹ tẹ̀mí tó yẹ ká máa jẹ ni.
Àlàáfíà inú rẹ̀ ju èrò wa lọ;
Ìwé Ìṣúra tó yẹ ká máa kà.
(Tún wo 2 Tím. 3:16; 2 Pét. 1:21.)