Orin 133
Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Gbogbo ọba ayé
Ńta ko Ọmọ Jèhófà.
Ọlọ́run sọ pé àkókò
Ìjọba èèyàn dópin.
Èyí tí wọ́n ṣe tó;
Ìjọba Ọlọ́run dé.
Kristi yóò run ọ̀tá rẹ̀ láyé.
Kò ní pẹ́ kò ní jìnnà.
(ÈGBÈ)
Wá Ọlọ́run kóo rígbàlà.
Kóo gbẹ́kẹ̀ lée pátápátá.
Wá òdodo rẹ̀,
Jẹ́ olóòótọ́ síi,
Gbà á ní Ọba Aláṣẹ.
Kóo rí bí yóò ṣe fagbára
Ńlá rẹ̀ gbà ọ́ là.
2. Aráyé ńṣèpinnu
Nípa ìhìn rere náà.
A ńjẹ́ kí kálukú wọn yàn
Láti gbọ́ tàbí ṣàìgbọ́.
A lè rí àdánwò.
Ẹ má ṣe jẹ́ ká bẹ̀rù.
Jèhófà ńṣọ́ àwọn olóòótọ́;
Yóò gbọ́ wa báa bá ké pèé.
(ÈGBÈ)
Wá Ọlọ́run kóo rígbàlà.
Kóo gbẹ́kẹ̀ lée pátápátá.
Wá òdodo rẹ̀,
Jẹ́ olóòótọ́ síi,
Gbà á ní Ọba Aláṣẹ.
Kóo rí bí yóò ṣe fagbára
Ńlá rẹ̀ gbà ọ́ là.
(Tún wo 1 Sám. 2:9; Sm. 2:2, 3, 9; Òwe 2:8; Mát. 6:33.)