Orin 30
Jèhófà Bẹ̀rẹ̀ Ìṣàkóso Rẹ̀
1. Ọjọ́ ológo nìyí. Ìṣàkóso Jáà bẹ̀rẹ̀.
Ó fi Kristi rẹ̀ jọba ní Síónì.
Ẹ jẹ́ ká kọrin ayọ̀
Sókè sí Ọlọ́run wa
Tó gbé Kristi,
Olúwa wa sórí ìtẹ́.
(ÈGBÈ)
Kí lo ńmú bọ̀, ’jọba Jèhófà?
Òótọ́, òdodo yóò borí.
Àti kí ni, ’jọba Jèhófà?
Ìyè láéláé àti ayọ̀.
Ẹ fìyìn f’Ọ́ba Aláṣẹ
Fún ’fẹ́ àtòdodo rẹ̀.
2. Kristi dé ń’nú agbára, Amágẹ́dọ́nì dé tán.
Ètò Sátánì yóò dópin láìpẹ́.
Ká wàásù nísinsìnyí. Ọ̀pọ̀ ló ṣì yẹ kó gbọ́.
Káwọn ọlọ́kàn tútù dúró tìí báyìí.
(ÈGBÈ)
Kí lo ńmú bọ̀, ’jọba Jèhófà?
Òótọ́, òdodo yóò borí.
Àti kí ni, ’jọba Jèhófà?
Ìyè láéláé àti ayọ̀.
Ẹ fìyìn f’Ọ́ba Aláṣẹ
Fún ’fẹ́ àtòdodo rẹ̀.
3. Àwa ń júbà Ọba Tí Ọlọ́run yàn fún wa.
A wólẹ̀ fọ́ba tó wá lóókọ Jáà.
Wọnú tẹ́ńpìlì ńlá rẹ̀; Wá ojúure Ọlọ́run.
Láìpẹ́ yóò máa ṣe àkóso ohun gbogbo.
(ÈGBÈ)
Kí lo ńmú bọ̀, ’jọba Jèhófà?
Òótọ́, òdodo yóò borí.
Àti kí ni, ’jọba Jèhófà?
Ìyè láéláé àti ayọ̀.
Ẹ fìyìn f’Ọ́ba Aláṣẹ
Fún ’fẹ́ àtòdodo rẹ̀.
(Tún wo 2 Sám. 7:22; Dán. 2:44; Ìṣí. 7:15.)