MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bá A Ṣe Lè Darí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Lọ́nà Tá Ṣe Àwọn Ará Láǹfààní
Bíi tàwọn ìpàdé tó kù, ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá, torí ó máa ń fún wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere. (Heb 10:24, 25) Kò yẹ kí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá ju ìṣẹ́jú márùn-ún sí méje lọ, àárín àkókò yìí ni wọ́n máa pín àwọn ará, tí wọ́n á sọ ibi tí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́, tí wọ́n á sì gbàdúrà. (Kódà a lè má jẹ́ kó tó bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé ẹ̀yìn típàdé parí la fẹ́ ṣe ìpàdé yìí.) Ó yẹ kẹ́ni tó fẹ́ darí ìpàdé náà sọ ohun tó máa ṣe àwọn ará láǹfààní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lọ́jọ́ yẹn. Bí àpẹẹrẹ, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó máa ń wá sípàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́jọ́ Saturday ni ò kì í ráyè jáde láàárín ọ̀sẹ̀, torí náà á dáa kẹ́ni tó fẹ́ darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́jọ́ yẹn jíròrò bá a ṣe lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn nǹkan míì wo lẹni tó ń darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lè jíròrò?
Ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ látinú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
Bá a ṣe lè fi ohun tá a gbọ́ nínú ìròyìn àtàwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò
Ohun tá a lè sọ tẹ́nì kan bá sọ pé òun ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wa
Ohun tá a lè sọ tẹ́nì kan bá sọ pé òun ò gba Ọlọ́run gbọ́, tẹ́nì kan bá gbà pé kò sí Ọlọ́run, tẹ́nì kan bá ń sọ èdè míì tàbí tẹ́nì kan bá ń ṣe ẹ̀sìn tí ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ládùúgbò yín
Bá a ṣe lè lo àwọn nǹkan tó wà lórí ìkànnì jw.org, JW Library® tàbí Bíbélì
Bá a ṣe lè lo àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́
Bá a ṣe lè lo àwọn ọ̀nà míì láti wàásù, irú bíi ká fi tẹlifóònù wàásù, ká kọ lẹ́tà, ká wàásù níbi térò pọ̀ sí, ká ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Àwọn ìránnilétí nípa ọ̀rọ̀ ààbò, bá a ṣe lè yíwọ́ pa dà, bá a ṣe lè máa hùwà tó bójú mu lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bá a ṣe lè ní èrò tó dáa nípa àwọn tá à ń wàásù fún tàbí àwọn nǹkan míì tá ṣe àwọn ará láǹfààní
Ẹ̀kọ́ tàbí fídíò látinú ìwé Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni
Bá a ṣe lè ṣèrànwọ́ fún ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí àti bá a ṣe lè fún un níṣìírí
Ẹsẹ Bíbélì tá a lè lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tàbí ìrírí kan tó máa fún àwọn ará níṣìírí