ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/09 ojú ìwé 5
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 8/09 ojú ìwé 5

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 31, 2009. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ July 6 sí August 31, 2009, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.

1. Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé ìyà ikú ni kí wọ́n fi jẹ ẹnikẹ́ni tó bá “pe ibi wá sórí” àwọn òbí rẹ̀? (Léf. 20:9) [w04-YR 5/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 6]

2. Níwọ̀n bí òfin ti kàn-ń-pá pé kí gbogbo àwọn ọkùnrin lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wà níbi Àjọyọ̀ Àwọn Àkàrà Aláìwú, ta ló máa lọ kórè àkọ́so ọkà báálì tí wọ́n máa mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ? (Léf. 23:5, 11) [w07-YR 7/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 3]

3. Kí ni ọdún Júbílì ṣàpẹẹrẹ? (Léf. 25:10, 11) [w04-YR 7/15 ojú ìwé 26 sí 27]

4. Ǹjẹ́ àwọn “àmì” tí a mẹ́nu bà nínú Númérì 2:2 ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú ìjọsìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? [w02-YR 9/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 4]

5. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, irú ẹ̀mí táwọn Násírì ní wo làwọn olùpòkìkí Ìjọba alákòókò kíkún náà ní lákòókò wa yìí? (Núm. 6:3, 5, 6) [w04-YR 8/1 ojú ìwé 24 sí 25]

6. Ìlànà wo nínú òfin ìfẹ̀yìntì àwọn ọmọ Léfì ló ṣeé múlò fáwa èèyàn Jèhófà lónìí? (Núm. 8:25, 26) [w04-YR 8/1 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1]

7. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi “ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan” hàn, ẹ̀kọ́ wo làwa Kristẹni sì lè rí kọ́ lára ìyẹn lóde òní? (Núm. 11:4) [w01-YR 6/15 ojú ìwé 14 sí 15; w95-YR 3/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 10]

8. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Míríámù nìkan ni ẹ̀tẹ̀ bò, ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la sì lè rí kọ́ látinú èyí? (Núm. 12:9-11) [w04-YR 8/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 2]

9. Kí ni Jóṣúà àti Kálébù ní lọ́kàn nígbà tí wọ́n pe àwọn olùgbé Kénáánì ní “oúnjẹ”? (Núm. 14:9) [w06-YR 10/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 5]

10. Ìkìlọ̀ wo ni Númérì 21:5 fún wa? [w99-YR 8/15 ojú ìwé 26 sí 27]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́