Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 21
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 21
Orin 61 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 4 ìpínrọ̀ 9 sí 14 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Mátíù 12-15 (10 min.)
No. 1: Mátíù 14:23–15:11 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọlọ́run Ń Gbà Wá Là Nípasẹ̀ Ẹbọ Ìràpadà Jésù—td 18A (5 min.)
No. 3: Ẹ̀kọ́ Wo La Lè Rí Kọ́ Látinú Bí Ísákì Ṣe Jẹ́ Èèyàn Àlàáfíà?—Jẹ́n. 26:19-22 (5 min.)
□ Ìpàdé Ìṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Máa Wàásù Ìhìn Rere Láìdábọ̀. (Ìṣe 5:42) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kí ló mú kí wọ́n máa fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn sí ipò àkọ́kọ́? Báwo ni wọ́n ṣe máa ń múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù? Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń fún wọn lókun nípa tẹ̀mí?
10 min: Ìwa Rere Wa Máa Ń Jẹ́rìí fún Àwọn Èèyàn. (1 Pét. 2:12) Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ April 15, 2010, ojú ìwé 6, ìpínrọ̀ 16 àti Ilé Ìṣọ́ July 15, 2012, ojú ìwé 24, ìpínrọ̀ 11. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: “Ṣé Wàá Fẹ́ Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tìrẹ?” Ìbéèrè àti Ìdáhùn.
Orin 96 àti Àdúrà