Máa “Jẹ́rìí Kúnnákúnná”
1. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?
1 “Má ṣe fi ohunkóhun sílẹ̀ láìṣe ninu iṣẹ́ iranṣe rẹ.” (2 Tím. 4:5, Ìròhìn Ayọ̀) Ẹnu àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà á láti fún Tímótì ní ìmọ̀ràn yìí. Ó ṣe tán, ìrìn àjò míṣọ́nnárì mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Pọ́ọ̀lù alára rìn láàárín ọdún 47 sí 56 Sànmánì Kristẹni. Ìwé Ìṣe tún sọ léraléra nípa bí Pọ́ọ̀lù ṣe “jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 23:11; 28:23) Báwo làwa náà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lóde òní?
2. Báwo la ṣe lè jẹ́rìí kúnnákúnná tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé?
2 Láti Ilé Dé Ilé: Ó lè gba pé ká jáde òde ẹ̀rí láwọn àkókó tó yàtọ̀ sí ìgbà tá a máa ń jáde tẹ́lẹ̀, ká lè bá àwọn èèyàn tí wọn kò tíì gbọ́ ìwàásù wa. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ tàbí òpin ọ̀sẹ̀ la máa lè bá baálé ilé fúnra rẹ̀ nílé. Ó yẹ ká sapá láti bá gbogbo àwọn tó bá wà nínú ilé sọ̀rọ̀, ká sì tún rí i pé a pa dà lọ síbi tí a kò ti bá àwọn èèyàn nílé tẹ́lẹ̀. Tí a kò bá rí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ lẹ́yìn gbogbo ìsapá tá a ti ṣe ńkọ́? A lè kọ lẹ́tà sí i tàbí ká wàásù fún un lórí fóònù.
3. Àǹfààní wo lo ní láti wàásù fáwọn èèyàn ní gbangba àti láìjẹ́ bí àṣà?
3 Ní Gbangba àti Láìjẹ́ bí Àṣà: Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní ń sọ̀rọ̀ nípa “ọgbọ́n tòótọ́” fún gbogbo èèyàn tó fẹ́ gbọ́. Nígbà míì, a máa ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ “lójú pópó” tàbí “ní ojúde ìlú.” (Òwe 1:20, 21) Ǹjẹ́ a máa ń lo àǹfààní tá a bá ní lẹ́nu ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ láti wàásù fáwọn èèyàn? Ǹjẹ́ a lè sọ pé ‘ọwọ́ wa dí jọjọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà’? (Ìṣe 18:5) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé à ń ṣe ipa tiwa láti máa “jẹ́rìí kúnnákúnná.”—Ìṣe 10:42; 17:17; 20:20, 21, 24.
4. Báwo ni àdúrà àti àṣàrò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa jẹ́rìí kúnnákúnná?
4 Nígbà míì, àìpé tàbí ìtìjú lè fẹ́ mú ká máa fà sẹ́yìn láti wàásù. Àmọ́ ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà mọ ibi tá a kù sí. (Sm. 103:14) Ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká lè fìgboyà sọ̀rọ̀ nígbàkigbà tí kò bá yá wa lára láti wàásù. (Ìṣe 4:29, 31) Nígbà tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí tí à ń ṣàṣàrò, a tún lè ronú nípa bá a ṣe lè túbọ̀ mọyì bí ìhìn rere náà ti níye lórí tó. (Fílí. 3:8) Èyí á jẹ́ ká lè máa fìtara wàásù fáyé gbọ́!
5. Báwo ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ṣe kàn wá?
5 Wòlíì Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé kí ọjọ́ ìbínú ńlá Jèhófà tó dé, àwọn èèyàn Jèhófà á máa “lọ ṣáá” láì jẹ́ kí ohunkóhun dá wọn dúró láti wàásù. (Jóẹ́lì 2:2, 7-9) Iṣẹ́ ńlá niṣẹ́ yìí, a ò sì ní tún un ṣe mọ́! Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa rí i pé a kópa tó jọjú nínú rẹ̀!