Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 28
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 28
Orin 29 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 4 ìpínrọ̀ 15 sí 20 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Mátíù 16-21 (10 min.)
No. 1: Mátíù 17:22–18:10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: “Àwọn Ọ̀rọ̀ Rere” Wo Ni Jèhófà Sọ Tó sì Ṣẹ Níṣojú Jóṣúà?—Jóṣ. 23:14 (5 min.)
No. 3: “Ìgbàlà Lẹ́ẹ̀kan, Ìgbàlà Gbogbo Ìgbà” Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu—td 18B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́. Lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù February. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn.
25 min: “Lékè Ohun Gbogbo, Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan.” Ìbéèrè àti ìdáhùn tó dá lórí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! Fi ìsọfúnni tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú Ìṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Lẹ́yìn náà, lo àwọn ìbéèrè tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ojú ìwé 31 ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! láti fi jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 20 nínú àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 28. Fi ìsọfúnni tó wà ní ìpínrọ̀ kejì Ìṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa kádìí ìjíròrò náà. Gba àwọn ará níyànjú láti wo fídíò wa tá a pe àkòrí rẹ̀ ní Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Wa.
Orin 53 àti Àdúrà