Orin 53
Ṣíṣiṣẹ́ Pa Pọ̀ ní Ìṣọ̀kan
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jáà ti mú wa wá ságbo rẹ̀.
A ńgbádùn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.
A ńlálàáfíà àtìṣọ̀kan,
Èyí ńfún wa láyọ̀.
A nífẹ̀ẹ́ ìṣọ̀kan;
Ìrẹ́pọ̀ sì dùn.
Ọlọ́run ti gbéṣẹ́ fún wa.
Ó ńtipa Ọmọ rẹ̀ tọ́ wa.
Ẹ jẹ́ ká máa ṣe ìgbọràn,
Ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀.
2. Báa ti ńgbàdúrà ìṣọ̀kan
Táa sì ńfẹ́ láti máa ṣoore,
Ìfẹ́, ìyìn yóò máa pọ̀ síi,
Yóò máa múnú wa dùn.
Àlàáfíà máa ńtura,
Ó máa ńdùn mọ́ni.
Báa ti ń lo ìfẹ́ ará,
A ó lálàáfíà Ọlọ́run.
Yóò sì fún wa ní ìṣọ̀kan,
Ká lè sìnín títí láé.
(Tún wo Míkà 2:12; Sef. 3:9; 1 Kọ́r. 1:10.)