ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 7/15 ojú ìwé 10-15
  • Ìdílé Jèhófà Ń Gbádùn Ìṣọ̀kan Ṣíṣeyebíye

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdílé Jèhófà Ń Gbádùn Ìṣọ̀kan Ṣíṣeyebíye
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Wo Bí Ó Ti Dára àti Bí Ó Ti Dùn Tó!
  • Àwọn Kókó Abájọ Tí Ń Gbé Ìṣọ̀kan Lárugẹ
  • Ètò Ìṣàkóso Ọlọ́run Ṣe Kókó
  • Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gbégbèésẹ̀
  • Ṣiṣẹ́ Sìn Nínú Ìṣọ̀kan Ìṣàkóso Ọlọ́run
  • Pa Ìṣọ̀kan Mọ́ Ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Wọ̀nyí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìṣọ̀kan La Fi Ń dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìṣọ̀kan Àwa Kristẹni Ń fi Ògo Fún Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Kí Ló Ń Mú Kí Ìṣọ̀kan Tòótọ́ Láàárín Àwọn Kristẹni Ṣeé Ṣe?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 7/15 ojú ìwé 10-15

Ìdílé Jèhófà Ń Gbádùn Ìṣọ̀kan Ṣíṣeyebíye

“Kíyè sí i, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.”—ORIN DÁFÍDÌ 133:1.

1. Ipò wo ni ọ̀pọ̀ ìdílé wà lónìí?

ÌDÍLÉ wà nínú yánpọnyánrin lónìí. Nínú ọ̀pọ̀ ìdílé, ìdè ìgbéyàwó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ já tán. Ìkọ̀sílẹ̀ túbọ̀ ń wọ́pọ̀ sí i, inú ọ̀pọ̀ ọmọ àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti kọ ara wọn sílẹ̀ sì ń bàjẹ́ gidigidi. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìdílé kò láyọ̀, kò sì sí ìṣọ̀kan láàárín wọn. Síbẹ̀, ìdílé kan ń bẹ tí ó mọ ìdùnnú tòótọ́ àti ojúlówó ìṣọ̀kan. Ìdílé àgbáyé, ti Jèhófà Ọlọ́run ni. Nínú rẹ̀, ẹgbàágbèje áńgẹ́lì tí a kò lè fojú rí ń bá iṣẹ́ àyànfúnni wọn lọ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. (Orin Dáfídì 103:20, 21) Ṣùgbọ́n, ìdílé kan ha wà lórí ilẹ̀ ayé, tí ń gbádùn irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ bí?

2, 3. (a) Àwọn wo ni wọ́n jẹ́ apá kan ìdílé àgbáyé ti Ọlọ́run nísinsìnyí, kí sì ni a lè fi gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wé lónìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a óò jíròrò?

2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èmí tẹ eékún mi ba fún Bàbá, ẹni tí olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé jẹ ní gbèsè fún orúkọ rẹ̀.” (Éfésù 3:14, 15) Olúkúlùkù ìran ìdílé orí ilẹ̀ ayé jẹ Ọlọ́run ní gbèsè fún orúkọ rẹ̀, nítorí pé òun ni Ẹlẹ́dàá. Bí kò tilẹ̀ sí ìdílé ẹ̀dá ènìyàn kankan ní ọ̀run, kí a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Ọlọ́run gbé ètò àjọ rẹ̀ ti ọ̀run níyàwó, Jésù yóò sì ní ìyàwó nípa tẹ̀mí tí yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run. (Aísáyà 54:5; Lúùkù 20:34, 35; Kọ́ríńtì Kìíní 15:50; Kọ́ríńtì Kejì 11:2) Àwọn ẹni-àmì-òróró olùṣòtítọ́ tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ apá kan ìdílé àgbáyé ti Ọlọ́run nísinsìnyí, “àwọn àgùntàn míràn” Jésù, tí wọ́n ní ìrètí ti ilẹ̀ ayé sì jẹ́ mẹ́ḿbà rẹ̀ ti ọjọ́ ọ̀la. (Jòhánù 10:16; Róòmù 8:14-17; Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1996, ojú ìwé 31) Bí ó ti wù kí ó rí, a lè fi gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí wé ìdílé oníṣọ̀kan kárí ayé.

3 Ìwọ́ ha jẹ́ apá kan àgbàyanu ìdílé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kárí orílẹ̀-èdè bí? Bí o bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ́ ń gbádùn ọ̀kan nínú àwọn ìbùkún pípabambarì jù lọ tí ẹnikẹ́ni lè gbádùn. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ yóò jẹ́rìí sí i pé, ìdílé àgbáyé ti Jèhófà—ètò àjọ rẹ̀ tí a lè fojú rí—jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá ti àlàáfíà àti ìṣọ̀kan nínú ayé kan tí ó jẹ́ aṣálẹ̀ tí ó kún fún gbọ́nmisi-omi-ò-to àti àìsíṣọ̀kan. Báwo ni a ṣe lè ṣàpèjúwe ìṣọ̀kan ìdílé kárí ayé ti Jèhófà? Àwọn kókó abájọ wo sì ni wọ́n ń gbé irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ lárugẹ?

Ẹ Wo Bí Ó Ti Dára àti Bí Ó Ti Dùn Tó!

4. Ní ọ̀rọ̀ tìrẹ, báwo ni ìwọ yóò ṣe sọ ohun tí Orin Dáfídì 133 sọ nípa ìṣọ̀kan ará?

4 Onísáàmù náà, Dáfídì, ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún ìṣọ̀kan ará. A tilẹ̀ mí sí i láti kọrin nípa rẹ̀! Fojú inú wò ó, ti òun ti háápù rẹ̀, bí ó ti ń kọrin pé: “Kíyè sí i, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀. Ó dà bí òróró ìkunra iyebíye ní orí, tí ó ṣàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Áárónì: tí ó sì ṣàn sí etí aṣọ rẹ̀; bí ìrì Hámónì tí ó ṣàn sórí òkè Síónì: nítorí níbẹ̀ ni Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún, àní ìyè láé láé.”—Orin Dáfídì 133:1-3.

5. Lórí ìpìlẹ̀ Orin Dáfídì 133:1, 2, ìjọra wo ni a lè rí láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní?

5 Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹ́n ní í ṣe pẹ̀lú ìṣọ̀kan ará, tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ìgbàanì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ń gbádùn. Nígbà tí wọ́n bá wà ní Jerúsálẹ́mù fún ayẹyẹ mẹ́ta tí wọ́n ń ṣe ní ọdọọdún, wọ́n máa ń gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan. Bí wọ́n tilẹ̀ ti inú onírúurú ẹ̀yà ìran wá, ìdílé kan ṣoṣo ni wọ́n. Wíwà pa pọ̀ ní ipa ìdarí tí ó dára lórí wọn, ó dà bí òróró títuni lára olóòórùn dídùn, tí a fi ń yanni sípò. Nígbà tí a tú irú òróró bẹ́ẹ̀ dà sórí Áárónì, ó ṣàn lọ sí irùngbọ̀n rẹ̀ àti sí ọrùn ẹ̀wù rẹ̀. Lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wíwà pa pọ̀ ní agbára ìdarí rere tí ó gbilẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n pé jọ náà látòkè délẹ̀. A yanjú èdè àìyedè, a sì gbé ìṣọ̀kan lárugẹ. Irú ìṣọ̀kan kan náà wà lónìí nínú ìdílé àgbáyé ti Jèhófà. Kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé ń ní ipa ìdarí dídára nípa tẹ̀mí lórí àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀. A ń yanjú èdè àìyedè tàbí ìṣòro èyíkéyìí bí a ṣe ń fi ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. (Mátíù 5:23, 24; 18:15-17) Àwọn ènìyàn Jèhófà ní ìmọrírì gíga lọ́lá fún ìṣírí fún tọ̀tún tòsì tí ìṣọ̀kan ará ń yọrí sí.

6, 7. Báwo ni ìṣọ̀kan Ísírẹ́lì ṣe dà bí ìrì Òke Hámónì, ibo sì ni a ti lè rí ìbùkún Ọlọ́run lónìí?

6 Báwo ni wíwà pa pọ̀ Ísírẹ́lì ní ìṣọ̀kan ṣe dà bí ìrì Òke Hámónì? Tóò, níwọ̀n bí ṣóńṣó òkè yìí ti fi 2,800 mítà ga ju ìtẹ́pẹrẹsẹ òkun lọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ jálẹ̀ ọdún ní òjò dídì fi máa ń bò ó. Orí Òke Hámónì olójò dídì ń mú kí kùrukùru òru tutù, tí ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ìrì tí ó tó, tí ń mú kí ewébẹ̀ lè la ìgbà ẹ̀rùn gígùn já. Ìgbì atẹ́gùn tútù láti òkè Hámónì lè gbé irú kùrukùru bẹ́ẹ̀ títí dé ibi jíjìnnà réré bíi gúúsù agbègbè Jerúsálẹ́mù, níbi tí wọn yóò ti sẹ̀ bí ìrì. Nítorí náà, onísáàmù náà tọ̀nà láti sọ pé ‘bí ìrì Hámónì tí ń ṣàn sórí Òke Síónì.’ Ẹ wo irú ìránnilétí àtàtà ti agbára ìdarí títuni lára tí ń gbé ìṣọ̀kan ìdílé ti àwọn olùjọsìn Jèhófà lárugẹ tí èyí jẹ́!

7 Sáájú dídá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, Síónì, tàbí Jerúsálẹ́mù, ni ojúkò ìjọsìn tòótọ́. Nítorí náà, níbẹ̀ ni Ọlọ́run pàṣẹ kí ìbùkún náà wà. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Orísun gbogbo ìbùkún wà ní ibi mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ibẹ̀ ni ìbùkún yóò ti wá. Nítorí pé ìjọsìn tòótọ́ kò sinmi lórí ọ̀gangan kan pàtó mọ́, nítorí náà, a lè rí ìbùkún, ìfẹ́, àti ìṣọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run jákèjádò ilẹ̀ ayé lónìí. (Jòhánù 13:34, 35) Kí ni díẹ̀ nínú àwọn kókó abájọ tí ń gbé ìṣọ̀kan yìí lárugẹ?

Àwọn Kókó Abájọ Tí Ń Gbé Ìṣọ̀kan Lárugẹ

8. Kí ni a rí kọ́ nípa ìṣọ̀kan ní Jòhánù 17:20, 21?

8 A gbé ìṣọ̀kan àwọn olùjọsìn Jèhófà karí ṣíṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a lóye lọ́nà títọ́, títí kan àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi. Nípa rírán tí Jèhófà rán Ọmọkùnrin rẹ̀ sí ayé láti jẹ́rìí sí òtítọ́, kí ó sì kú ikú ìrúbọ, ọ̀nà náà ṣí sílẹ̀ fún dídá ìjọ Kristẹni tí ó wà ní ìṣọ̀kan sílẹ̀. (Jòhánù 3:16; 18:37) Jésù mú un ṣe kedere pé, ojúlówó ìṣọ̀kan yóò wà láàárín àwọn mẹ́ḿbà ìjọ náà, nígbà tí ó gbàdúrà pé: “Mo ṣe ìbéèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, kì í ṣe nípa àwọn wọ̀nyí nìkan, ṣùgbọ́n nípa àwọn wọnnì pẹ̀lú tí yóò lo ìgbàgbọ́ nínú mi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn; kí gbogbo wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Bàbá, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi tí èmí sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa, kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi jáde.” (Jòhánù 17:20, 21) Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní irú ìṣọ̀kan kan tí ó fara jọ èyí tí ó wà láàárín Ọlọ́run àti Ọmọkùnrin rẹ̀. Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí pé, wọ́n ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ẹ̀kọ́ Jésù. Irú ìṣarasíhùwà kan náà ni kókó abájọ pàtàkì tí ó fa ìṣọ̀kan ìdílé kárí ayé, ti Jèhófà lónìí.

9. Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú ìṣọ̀kan àwọn ènìyàn Jèhófà?

9 Kókó abájọ mìíràn tí ń mú àwọn ènìyàn Jèhófà wà níṣọ̀kan ni pé, a ní ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, tàbí ipá ìṣiṣẹ́. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí a ṣí payá, kí a sì lè tipa báyìí ṣiṣẹ́ sìn ín níṣọ̀kan. (Jòhánù 16:12, 13) Ẹ̀mí náà ń ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn iṣẹ́ ti ẹran ara tí ń fa ìyapa, irú bíi gbọ́nmisi-omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, àti asọ̀. Dípò èyí, ẹ̀mí Ọlọ́run ń mú èso amúnisọ̀kan ti ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu jáde nínú wa.—Gálátíà 5:19-23.

10. (a) Ìjọra wo ni a lè rí láàárín ìfẹ́ tí ó wà láàárín ìdílé ẹ̀dá ènìyàn tí ó ṣọ̀kan àti ìfẹ́ tí ó hàn gbangba láàárín àwọn tí wọ́n fi ara wọn fún Jèhófà? (b) Báwo ni ọ̀kan nínú mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ṣe sọ ìmọ̀lára rẹ̀ jáde nípa pípàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará nípa tẹ̀mí?

10 Àwọn ìdílé oníṣọ̀kan ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kíní kejì, wọ́n sì ń láyọ̀ láti wà pa pọ̀. Lọ́nà ìfiwéra, àwọn tí wọ́n wà nínú ìdílé oníṣọ̀kan ti àwọn olùjọsìn Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, Ọmọkùnrin rẹ̀, àti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. (Máàkù 12:30; Jòhánù 21:15-17; Jòhánù Kìíní 4:21) Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìdílé oníṣọ̀kan nípa ti ara ti ń gbádùn jíjẹun pa pọ̀, inú àwọn tí wọ́n ti fi ara wọn fún Ọlọ́run ń dùn láti pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, àwọn àpéjọ, àti àwọn àpéjọpọ̀ láti jàǹfààní láti inú ìkẹ́gbẹ́pọ̀ àtàtà àti oúnjẹ tẹ̀mí tí ó mìrìngìndìn. (Mátíù 24:45-47; Hébérù 10:24, 25) Mẹ́ḿbà kan nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ ọ́ lọ́nà yìí nígbà kan pé: “Lójú tèmi, pípàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn adùn pípabambarì jù lọ nínú ìgbésí ayé àti orísun ìṣírí. Mo máa ń fẹ́ láti jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí yóò kọ́kọ́ dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, tí ó bá sì ṣeé ṣe, kí n jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí yóò gbẹ́yìn síbẹ̀. Inú mi máa ń dùn jọjọ nígbà tí mo bá ń bá àwọn ènìyàn Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo bá wà láàárín wọn, ará máa ń tù mí pẹ̀sẹ̀ pẹ̀lú ìdílé mi.” Ṣe bí o ṣe ń nímọ̀lára nìyẹn?—Orin Dáfídì 27:4.

11. Inú iṣẹ́ wo ni pàtàkì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń rí ayọ̀, kí sì ni fífi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa yóò yọrí sí?

11 Ìdílé oníṣọ̀kan ń rí ayọ̀ nínú ṣíṣe nǹkan pa pọ̀. Bákan náà, àwọn tí wọ́n wà nínú ìdílé ti àwọn olùjọsìn Jèhófà ń rí ìdùnnú nínú fífi ìṣọ̀kan ṣe iṣẹ́ wọn, ti wíwàásù Ìjọba àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Lílọ́wọ́ nínú rẹ̀ déédéé túbọ̀ ń fà wá mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn fún Jèhófà. Fífi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ṣe ohun pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa àti kíkọ́wọ́ ti ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn rẹ̀ tún ń gbé ẹ̀mí ìdílé náà lárugẹ láàárín wa.

Ètò Ìṣàkóso Ọlọ́run Ṣe Kókó

12. Kí ni a fi ń dá ìdílé oníṣọ̀kan àti aláyọ̀ mọ̀, ìṣètò wo sì ni ó gbé ìṣọ̀kan lárugẹ nínú ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní?

12 Ìdílé kan tí ó ní olórí tí kò gba gbẹ̀rẹ́, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ tí ó sì ń ṣe nǹkan létòlétò ṣeé ṣe kí ó wà níṣọ̀kan kí ó sì láyọ̀. (Éfésù 5:22, 33; 6:1) Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ètò àlàáfíà, gbogbo àwọn tí wọ́n sì wà nínú ìdílé rẹ̀ kà á sí “Ọ̀gá ògo.” (Dáníẹ́lì 7:18, 22, 25, 27; Kọ́ríńtì Kìíní 14:33) Wọ́n tún mọ̀ pé ó ti yan Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi, sípò ajogún ohun gbogbo, ó sì ti fa gbogbo ọlá àṣẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé lé e lọ́wọ́. (Mátíù 28:18; Hébérù 1:1, 2) Pẹ̀lú Kristi gẹ́gẹ́ bí Orí rẹ̀, ìjọ Kristẹni jẹ́ ètò àjọ oníṣọ̀kan, tí ó wà létòlétò. (Éfésù 5:23) Láti darí ìgbòkègbodò àwọn ìjọ ọ̀rúndún kìíní, ẹgbẹ́ olùṣàkóso kan ń bẹ tí ó ní nínú, àwọn àpọ́sítélì àti àwọn “àgbà ọkùnrin” mìíràn tí wọ́n dàgbà dénú. Ìjọ kọ̀ọ̀kan ní àwọn alábòójútó tí a yàn sípò, tàbí àwọn alàgbà, àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. (Ìṣe 15:6; Fílípì 1:1) Ṣíṣègbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú ń gbé ìṣọ̀kan lárugẹ.—Hébérù 13:17.

13. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fa àwọn ènìyàn mọ́ra, kí sì ni èyí ń yọrí sí?

13 Ṣùgbọ́n, gbogbo ètò yìí ha fi hàn pé, ìṣọ̀kan àwọn olùjọsìn Jèhófà jẹ́ nítorí ìdarí lílágbára, tí kò bá ti ẹ̀dá mu bí? Láìṣe àní-àní bẹ́ẹ̀ kọ́! Kò sí ohun kan tí ó fi àìnífẹ̀ẹ́ hàn nípa Ọlọ́run tàbí ètò àjọ rẹ̀. Jèhófà ń fa àwọn ènìyàn mọ́ra nípa fífi ìfẹ́ hàn, lọ́dọọdún sì ni ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń yọ̀ọ̀da ara wọn, tí wọ́n sì ń fi ìdùnnú di apá kan ètò àjọ Jèhófà nípa ṣíṣe batisí láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn tọkàntọkàn hàn fún Ọlọ́run. Wọ́n ní irú ẹ̀mí tí Jóṣúà ní, ẹni tí ó rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin óò máa sìn ní òní; . . . ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi àti ilé mi ni, OLÚWA ni àwa óò máa sìn.”—Jóṣúà 24:15.

14. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé ètò àjọ Jèhófà jẹ́ atẹ̀lélànà ìṣàkóso Ọlọ́run?

14 Gẹ́gẹ́ bí apá kan ìdílé Jèhófà, kì í ṣe pé a ní ìdùnnú nìkan ni, ṣùgbọ́n a ní ààbò pẹ̀lú. Èyí rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, ètò àjọ rẹ̀ jẹ́ atẹ̀lélànà ìṣàkóso Ọlọ́run. Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run (láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì the·osʹ, ọlọ́run, àti kraʹtos, ìṣàkóso). Ó jẹ́ ìṣàkóso nípasẹ̀ Ọlọ́run, tí ó fàṣẹ rẹ̀ lélẹ̀, tí ó sì gbé kalẹ̀. “Orílẹ̀-Èdè mímọ́” tí Jèhófà fi òróró yàn jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ìṣàkóso rẹ̀, nítorí náà ó jẹ́ atẹ̀lélànà ìṣàkóso Ọlọ́run. (Pétérù Kìíní 2:9) Níwọ̀n bí a ti ní Atóbilọ́lá Olùṣàkóso náà, Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ wa, Olófin wa, àti Ọba wa, a ní ìdí púpọ̀ láti nímọ̀lára ààbò. (Aísáyà 33:22) Síbẹ̀, bí awuyewuye kan bá dìde ńkọ́, tí ó sì wu ìdùnnú, ààbò, àti ìṣọ̀kan wa léwu?

Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gbégbèésẹ̀

15, 16. Awuyewuye wo ni ó dìde ní ọ̀rúndún kìíní, èé sì ti ṣe?

15 Láti lè pa ìṣọ̀kan ìdílé kan mọ́, nígbà míràn a lè ní láti yanjú awuyewuye kan. Nígbà náà, kí a sọ pé, a ní láti yanjú ìṣòro kan nípa tẹ̀mí láti pa ìṣọ̀kan ìdílé Ọlọ́run, ti àwọn olùjọsìn ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa mọ́. Nígbà náà, kí ni ṣíṣe? Ẹgbẹ́ olùṣàkóso gbégbèésẹ̀, ní ṣíṣe ìpinnu lórí àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí. A ní àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ kan nípa irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.

16 Ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Tiwa, ẹgbẹ́ olùṣàkóso pàdé ní Jerúsálẹ́mù láti yanjú ìṣòro líle koko kan, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pa ìṣọ̀kan “agbo ilé Ọlọ́run” mọ́. (Éfésù 2:19) Ní nǹkan bí ọdún 13 ṣáájú àkókò náà, àpọ́sítélì Pétérù wàásù fún Kọ̀nílíù, àti àwọn Kèfèrí àkọ́kọ́, tàbí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n di onígbàgbọ́ tí a batisí. (Ìṣe, orí 10) Nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ Kèfèrí tẹ́wọ́ gba ìsin Kristẹni. (Ìṣe 13:1–14:28) Kódà, a dá ìjọ àwọn Kèfèrí tí ó di Kristẹni sílẹ̀ ní Áńtíókù, Síríà. Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ Júù gbà gbọ́ pé àwọn Kèfèrí tí a yí lọ́kàn padà ní láti kọlà, kí wọ́n sì pa Òfin Mósè mọ́, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn ta kò ó. (Ìṣe 15:1-5) Awuyewuye yìí ì bá ti yọrí sí ìyapa pátápátá, àní sí dídá àwọn ìjọ Júù àti Kèfèrí sílẹ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, ẹgbẹ́ olùṣàkóso gbégbèésẹ̀ ní wàràǹṣeṣà láti pa ìṣọ̀kan Kristẹni mọ́.

17. Ìlànà onífohùnṣọ̀kan ti ìṣàkóso Ọlọ́run wo ni a ṣàpèjúwe nínú Ìṣe orí 15?

17 Gẹ́gẹ́ bí Ìṣe 15:6-22 ti sọ, “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrín sì kóra jọ pọ̀ láti rí sí àlámọ̀rí yìí.” Àwọn mìíràn tún pésẹ̀ síbẹ̀, títí kan aṣojú láti Áńtíókù. Pétérù kọ́kọ́ ṣàlàyé pé ‘láti ẹnu òun ni àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìn rere tí wọ́n sì gbà gbọ́.’ Lẹ́yìn náà, “gbogbo ògìdìgbó náà pátá” fetí sílẹ̀ bí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù ti ń ṣèròyìn “ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ àmì àti àpẹẹrẹ ìyanu tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,” tàbí àwọn Kèfèrí. Lẹ́yìn èyí, Jákọ́bù dábàá bí a ṣe lè yanjú ọ̀ràn náà. Lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ṣe ìpinnu, a sọ fún wa pé: “Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìjọ fara mọ́ rírán àwọn ọkùnrin tí a yàn láti àárín wọn lọ sí Áńtíókù pa pọ̀ pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà.” “Àwọn ọkùnrin tí a yàn” wọ̀nyẹn—Júdásì àti Sílà—mú lẹ́tà afúnniníṣìírí lọ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn.

18. Ìpinnu wo tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Òfin Mósè ni ẹgbẹ́ olùṣàkóso ṣe, báwo sì ni èyí ṣe nípa lórí àwọn Júù àti Kèfèrí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni?

18 Lẹ́tà tí ó ń kéde ìpinnu ẹgbẹ́ olùṣàkóso bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin, àwọn ará, sí àwọn ará wọnnì ní Áńtíókù àti Síríà àti Kílíkíà tí wọ́n wá láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè: A kí yín!” Àwọn ará mìíràn pésẹ̀ síbi ìpàdé mánigbàgbé yìí, ṣùgbọ́n ó hàn gbangba pé “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin” ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ olùṣàkóso náà. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí wọn, nítorí lẹ́tà náà kà pé: “Ẹ̀mí mímọ́ àti àwa fúnra wá ti fara mọ́ ṣíṣàì tún fi ẹrù ìnira kankan kún un fún yín, àyàfi àwọn nǹkan pípọn dandan wọ̀nyí, láti máa ta kété sí àwọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti sí ẹ̀jẹ̀ àti sí ohun tí a lọ́ lọ́rùn pa àti sí àgbèrè.” (Ìṣe 15:23-29) A kò béèrè pé kí àwọn Kristẹni kọlà, kí wọ́n sì pa Òfin Mósè mọ́. Ìpinnu yìí ran àwọn Júù àti àwọn Kèfèrí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ́, kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ ní ìṣọ̀kan. Ìjọ hó ìhó ayọ̀, ìṣọ̀kan ṣíṣeyebíye sì ń bá a lọ, àní bí ó ṣe ń bá a lọ nínú ìdílé Ọlọ́run tí ó wà kárí ayé lónìí, lábẹ́ ìdarí tẹ̀mí ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Ìṣe 15:30-35.

Ṣiṣẹ́ Sìn Nínú Ìṣọ̀kan Ìṣàkóso Ọlọ́run

19. Èé ṣe tí ìṣọ̀kan nínú ìdílé àwọn olùjọsìn Jèhófà fi gbilẹ̀?

19 Ìṣọ̀kan máa ń gbilẹ̀ nígbà tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn rí nínú ìdílé àwọn olùjọsìn Jèhófà. Láti jẹ́ atẹ̀lélànà ìṣàkóso Ọlọ́run, àwọn alàgbà àti àwọn yòókù nínú ìjọ ọ̀rúndún kìíní ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pátápátá pẹ̀lú ẹgbẹ́ olùṣàkóso, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìpinnu rẹ̀. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹgbẹ́ olùṣàkóso, àwọn alàgbà “wàásù ọ̀rọ̀ náà,” gbogbo mẹ́ḿbà ìjọ sì “sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan.” (Tímótì Kejì 4:1, 2; Kọ́ríńtì Kìíní 1:10) Nítorí náà, òtítọ́ Ìwé Mímọ́ kan náà ni a gbé kalẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ní àwọn ìpàdé Kristẹni, ì báà jẹ́ ní Jerúsálẹ́mù, Áńtíókù, Róòmù, Kọ́ríńtì, tàbí ní ibikíbi. Irú ìṣọ̀kan ìṣàkóso Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ wà lónìí.

20. Láti pa ìṣọ̀kan Kristẹni wa mọ́, kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe?

20 Láti pa ìṣọ̀kan wa mọ́, gbogbo wa tí a jẹ́ apá kan ìdílé àgbáyé ti Jèhófà ní láti sakun láti fi ìfẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run hàn. (Jòhánù Kìíní 4:16) A ní láti jọ̀wọ́ ara wa fún ìfẹ́ Ọlọ́run, kí a sì fi ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ hàn fún ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Bíi ti ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọ́run, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ ọ́, ìgbọràn wá jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe àti àfìdùnnúṣe. (Jòhánù Kìíní 5:3) Ẹ wo bí onísáàmù náà ṣe fi ìsopọ̀ tí ń bẹ láàárín ìdùnnú àti ìgbọràn hàn lọ́nà yíyẹ wẹ́kú tó! Ó kọrin pé: “Ẹ máa yin Olúwa. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa, tí inú rẹ̀ dùn jọjọ ní òfin rẹ̀.”—Orin Dáfídì 112:1.

21. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ atẹ̀lélànà ìṣàkóso Ọlọ́run?

21 Jésù, Orí ìjọ, jẹ́ atẹ̀lélànà ìṣàkóso Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, ó sì máa ń ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ nígbà gbogbo. (Jòhánù 5:30) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ lé Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa, nípa ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà pẹ̀lú ìṣọ̀kan nínú fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pátápátá pẹ̀lú ètò àjọ Rẹ̀ àti jíjẹ́ atẹ̀lélànà ìṣàkóso Ọlọ́run. Nígbà náà, a óò lè kọ orin onísáàmù náà ní àkọtúnkọ pẹ̀lú ìdùnnú àtọkànwá àti ẹ̀mí ìmoore pé: “Kíyè sí i, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.”

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Báwo ni ìṣọ̀kan Kristẹni wa ṣe lè ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Orin Dáfídì 133?

◻ Kí ni díẹ̀ nínú àwọn kókó abájọ tí ń gbé ìṣọ̀kan lárugẹ?

◻ Èé ṣe tí ètò ìṣàkóso Ọlọ́run fi ṣe kókó fún ìṣọ̀kan àwọn ènìyàn Ọlọ́run?

◻ Báwo ni ẹgbẹ́ olùṣàkóso ọ̀rúndún kìíní ṣe gbégbèésẹ̀ láti pa ìṣọ̀kan mọ́?

◻ Kí ni ṣíṣiṣẹ́ sìn ní ìṣọ̀kan ìṣàkóso Ọlọ́run túmọ̀ sí fún ọ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ẹgbẹ́ olùṣàkóso gbégbèésẹ̀ láti dáàbò bo ìṣọ̀kan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́