Kí Ló Ń Mú Kí Ìṣọ̀kan Tòótọ́ Láàárín Àwọn Kristẹni Ṣeé Ṣe?
1 Kí lohun náà tó lè mú kó ṣeé ṣe fún mílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn láti igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] ilẹ̀ tí wọ́n ń sọ nǹkan bí okòó dín nírínwó [380] èdè láti wà ní ìṣọ̀kan? Àfi ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè mú kí èyí ṣeé ṣe. (Míkà 2:12; 4:1-3) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ látinú ìrírí tiwọn fúnra wọn pé ìṣọ̀kan tòótọ́ láàárín àwọn Kristẹni kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lónìí. Níwọ̀n bí a ti jẹ́ “agbo kan” lábẹ́ ‘olùṣọ́ àgùntàn wa kan,’ a ti pinnu láti yàgò fún ẹ̀mí ayé yìí tí ń fa ìpínyà.—Jòhánù 10:16; Éfé. 2:2.
2 Ète Ọlọ́run tí kò lè kùnà ni pé kí gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀ láyé àti lọ́run wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́. (Ìṣí. 5:13) Nítorí pé Jésù mọ bí èyí ṣe ṣe pàtàkì tó, ó gbàdúrà gidigidi pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun lè wà níṣọ̀kan. (Jòh. 17:20, 21) Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè mú kí ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ Kristẹni máa bá a nìṣó?
3 Ohun Tó Ń Mú Kí Ìṣọ̀kan Ṣeé Ṣe: Láìsí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀, ìṣọ̀kan Kristẹni kò lè ṣeé ṣe rárá. Fífi àwọn ohun tí à ń kà nínú Bíbélì ṣèwà hù ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ lọ fàlàlà nínú ìgbésí ayé wa. Èyí ń jẹ́ ká lè “máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfé. 4:3) Ó ń jẹ́ ká lè máa fara dà á fún ara wa nínú ìfẹ́. (Kól. 3:13, 14; 1 Pét. 4:8) Ṣé ò ń mú kí ìṣọ̀kan yìí máa bá a nìṣó nípa ṣíṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́?
4 Iṣẹ́ wíwàásù àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tí a gbé lé wa lọ́wọ́ náà tún ń mú ká wà níṣọ̀kan. Nígbà tá a bá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, tí à “ń làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ fún ìgbàgbọ́ ìhìn rere,” à o di “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.” (Fílí. 1:27; 3 Jòh. 8) Bá a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìdè ìfẹ́ tó ń mú ká wà níṣọ̀kan láàárín ìjọ á máa di èyí tó lágbára sí i. Oò ṣe ké sí ẹnì kan tó ti pẹ́ díẹ̀ tẹ́ ẹ ti jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí láti bá ọ jáde lọ́sẹ̀ yìí?
5 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ fún wa láti jẹ́ apákan ẹgbẹ́ ará tòótọ́ kan ṣoṣo tó kárí ayé, lórí ilẹ̀ ayé lónìí! (1 Pétérù 5:9) Láìpẹ́ yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló fojú ara wọn rí ìṣọ̀kan tó kárí ayé yìí ní àwọn Àpéjọ Àgbáyé “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run.” Ǹjẹ́ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa mú kí ìṣọ̀kan oníyebíye yìí máa bá a nìṣó nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, nípa fífi ìfẹ́ yanjú aáwọ̀ àti nípa wíwàásù ìhìn rere náà “pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan.”—Róòmù 15:6.