ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jr orí 4 ojú ìwé 43-53
  • Ṣọ́ra Fún Ọkàn Tó Ń Ṣàdàkàdekè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣọ́ra Fún Ọkàn Tó Ń Ṣàdàkàdekè
  • Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ỌKÀN WA TÓ Ń ṢÀDÀKÀDEKÈ LÈ TÀN WÁ JẸ
  • BÍ JÈHÓFÀ ṢE Ń SỌ WÁ DI IRÚ ẸNI TÓ FẸ́
  • JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ SỌ Ọ́ DI IRÚ ẸNI TÓ FẸ́
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Béèrè Lójoojúmọ́ Pé, “Jèhófà Dà?”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Èmi Kò Lè Dákẹ́”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Kí O sì Sọ Ọ̀rọ̀ Yìí Fún Wọn”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Àwọn Wo Ló Yẹ Kó O Yàn Lọ́rẹ̀ẹ́?
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
Àwọn Míì
Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
jr orí 4 ojú ìwé 43-53

ORÍ KẸRIN

Ṣọ́ra Fún Ọkàn Tó Ń Ṣàdàkàdekè

1, 2. Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro láti mọ ipò tí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa wà gan-an?

KÁ SỌ pé láàárọ̀ kùtù ọjọ́ kan nígbà tó o ṣì wà lórí ibùsùn, àyà kàn bẹ̀rẹ̀ sí í dùn ọ́, o ò sì lè mí kanlẹ̀ dáadáa. Ẹ̀rù lè máa bà ọ́, kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í fura pé, ‘Àbí mo lárùn ọkàn ni?’ Tó o bá kàn ń rò ó lọ́kàn pé kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò ní mú ìṣòro náà kúrò. Kí ni wàá ṣe? Ṣe ni wàá tètè wá nǹkan ṣe. Wàá ní kí wọ́n tètè gbé ọ lọ sí ilé ìwòsàn níbi tí wàá ti rí ìtọ́jú tó dáa gbà. Oníṣègùn kan lè wá ṣàyẹ̀wò rẹ dáadáa níbẹ̀ bóyá kó lo ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń wo bí ọkàn ṣe ń ṣiṣẹ́. Tí wọ́n bá tètè ṣàyẹ̀wò ara rẹ tí wọ́n sì tọ́jú rẹ, wọ́n lè gbẹ̀mí rẹ là.

2 Tó bá kan ti ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa náà ńkọ́? Ó lè ṣòro láti mọ ipò tó wà gan-an. Kí nìdí? Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jer. 17:9) Ọkàn wa lè tàn wá jẹ, kó mú ká máa rò pé a ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìṣòro nípa tẹ̀mí, nígbà táwọn ẹlòmíì lè máa rí i pé a ti wà nínú ewu, tára wọn á sì máa bù máṣọ nítorí wa. Kí nìdí tí ọkàn wa fi lè rí wa tàn jẹ? Ìdí ni pé ẹran ara wa tó máa ń fẹ́ láti dẹ́ṣẹ̀ lè ṣì wá lọ́nà, Sátánì àti ayé burúkú tá a wà nínú rẹ̀ yìí sì lè jẹ́ ká má mọ ipò tí ọkàn wa wà gan-an. Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ lára Jeremáyà àtàwọn èèyàn Júdà ìgbà ayé rẹ̀ ká lè mọ bá a ó ṣe máa ṣàyẹ̀wò ọkàn wa.

3. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti sọ di ọlọ́run?

3 Ó hàn lára èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn Júdà pé ọkàn wọn ti jìnnà sí Ọlọ́run gan-an. Wọ́n fi Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo sílẹ̀, wọ́n lọ ń bọ àwọn òrìṣà ilẹ̀ Kénáánì, ẹ̀rí ọkàn wọn ò sì dà wọ́n láàmù rárá. Ni Jèhófà bá gbé ọ̀rọ̀ yìí síwájú àwọn èèyàn Júdà abọ̀rìṣà yẹn, ó ní: “Àwọn ọlọ́run rẹ tí o ti ṣe fún ara rẹ dà? Kí wọ́n dìde bí wọ́n bá lè gbà ọ́ là ní àkókò ìyọnu àjálù rẹ. Nítorí pé bí iye ìlú ńlá rẹ ti pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn ọlọ́run rẹ ti pọ̀ tó.” (Jer. 2:28) Ní tiwa, ó dájú pé àwa ò ní ka ara wa sí abọ̀rìṣà. Ṣùgbọ́n ohun tí ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ọ̀rọ̀ náà “ọlọ́run,” ìyẹn òrìṣà, túmọ̀ sí ni: “Ẹnì kan tàbí ohun kan tó gbapò iwájú lọ́kàn ẹni.” Ohun tó sì gbapò iwájú lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni iṣẹ́ wọn, ìlera wọn, ìdílé wọn tàbí ohun ọ̀sìn wọn pàápàá. Ní tàwọn míì, eré ìdárayá, àwọn gbajúgbajà èèyàn, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, ìrìn àjò tàbí àṣà ìbílẹ̀ wọn ni wọ́n fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fi àwọn nǹkan yìí ṣáájú àjọṣe wọn pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá. Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni tòótọ́ àní bó ṣe ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Júdà ìgbà ayé Jeremáyà?

ỌKÀN WA TÓ Ń ṢÀDÀKÀDEKÈ LÈ TÀN WÁ JẸ

4. Ṣé tọkàntọkàn làwọn ará Júdà fi ń sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà dà? Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ó wà”?

4 Ó dájú pé wàá fẹ́ mọ ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà bá débi tó ti sọ pé ọkàn èèyàn ń gbékútà àti ohun tó tún sọ lẹ́yìn ìyẹn. Jeremáyà rí i pé ohun táwọn ará Júdà ń sọ ni pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà dà? Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ó wà.” (Jer. 17:15) Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ohun tí wọ́n sọ yẹn dọ́kàn wọn? Láti lè rí ìdáhùn, wo ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ Jeremáyà orí kẹtàdínlógún tá à ń gbé yẹ̀ wò yìí. Ó ní: “Ẹ̀ṣẹ̀ Júdà ni a ti fi kálàmù irin kọ sílẹ̀. A ti fi ṣóńṣó dáyámọ́ǹdì fín in sára wàláà ọkàn-àyà wọn.” Ìṣòro pàtàkì kan tí àwọn ará Júdà yẹn ní ni pé, ‘wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ará ayé, wọ́n fi ẹlẹ́ran ara ṣe apá wọn, ọkàn-àyà wọn sì ti yí pa dà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà.’ Àmọ́, àwọn èèyàn díẹ̀ lára wọn yàtọ̀. Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run ní tiwọn, wọ́n ń wojú rẹ̀ pé kó tọ́ àwọn sọ́nà, kó sì bù kún àwọn.—Jer. 17:1, 5, 7.

5. Kí làwọn èèyàn Júdà ìgbà ayé Jeremáyà ṣe nípa ìtọ́ni Jèhófà?

5 Ohun táwọn tó pọ̀ jù lára wọn ṣe nípa ohun tí Ọlọ́run sọ jẹ́ ká mọ bí ipò ọkàn wọn ṣe rí. (Ka Jeremáyà 17:21, 22.) Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ Sábáàtì, ṣe ló yẹ kí wọ́n sinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì fi ìgbà yẹn lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Àwọn èèyàn Júdà kò gbọ́dọ̀ ṣòwò tàbí kí wọ́n ṣiṣẹ́ kankan lọ́jọ́ Sábáàtì. Ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ń ṣe fi ipò tí ọkàn wọn wà hàn. Ìwé Jeremáyà sọ pé: “Wọn kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dẹ etí wọn sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ọrùn wọn le kí wọ́n má bàa gbọ́, kí wọ́n má sì gba ìbáwí.” Lóòótọ́ wọ́n mọ òfin Ọlọ́run, àmọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe wà lọ́kàn wọn. Wọ́n ń hùwà bí ẹní sọ pé àwọn ò mà lè jókòó gẹlẹtẹ lọ́jọ́ Sábáàtì ní tàwọn o, nítorí àwọn ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe.—Jer. 17:23; Aísá. 58:13.

6, 7. (a) Pẹ̀lú gbogbo ìmọ̀ràn tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ ń fún wa lóde òní, èrò tó kù díẹ̀ káàtó wo ni Kristẹni kan ṣì lè ní? (b) Kí ló lè sún wa débi pípa ìpàdé jẹ?

6 Lóde òní, àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ òfin Sábáàtì. Síbẹ̀, ìwà tí àwọn ará Júdà hù, èyí tó fi ipò ọkàn wọn hàn, jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa. (Kól. 2:16) Lóòótọ́, ká lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, a ti pa ṣíṣe ìfẹ́ ọkàn tára wa àti lílépa nǹkan tara tì. A mọ̀ pé ìwà òmùgọ̀ ló máa jẹ́ láti fúnra wa yan ọ̀nà tó máa rọ̀ wá lọ́rùn láti gbà sin Ọlọ́run. Kódà a lè ti mọ ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń fi tọkàn tara ṣèfẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì rí i pé ó ń tuni lára, ó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀. Síbẹ̀, báwo ni ọkàn wa ṣe lè ṣì wá lọ́nà?

7 Kristẹni kan lè fi àṣìṣe rò pé ọkàn tòun kò lè ṣi òun lọ́nà bí ọkàn àwọn èèyàn ìgbà ayé Jeremáyà ṣe ṣì wọ́n lọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lè ronú pé, ‘Mo gbọ́dọ̀ níṣẹ́ gidi kan lọ́wọ́ tí màá fi máa gbọ́ bùkátà ìdílé mi.’ Ìyẹn ò sì burú. Àmọ́ tí èrò yìí bá wá mú kó wò ó pé, ‘Ó yẹ kí n kàwé sí i kí n lè ríṣẹ́ tó fini lọ́kàn balẹ̀ táá sì máa mówó gidi wọlé’ ńkọ́? Ìyẹn náà lè má burú lójú tiẹ̀, kó sì máa wá ronú pé: ‘Nǹkan ti yí pa dà láyé ìsìnyí o, téèyàn ò bá lọ yunifásítì ọkàn èèyàn ò lè balẹ̀ lórí iṣẹ́ tó ń ṣe.’ Ẹ ò rí i pé, láìpẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n, tó bojú mu tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye fún wa lórí ọ̀rọ̀ kíkàwé sí i nílé ẹ̀kọ́ gíga, tónítọ̀hún á sì dẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ! Àwọn kan tiẹ̀ ti jẹ́ kí ọ̀nà táwọn èèyàn ayé gbà ń ronú àti ojú tí wọ́n fi ń wo ọ̀rọ̀ kíkàwé nílé ẹ̀kọ́ gíga, nípa lórí àwọn. (Éfé. 2:2, 3) Bíbélì kìlọ̀ fún wa lọ́nà tó ṣe wẹ́kú pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ayé yìí sọ yín dà bó ṣe dà.”—Róòmù 12:2, Bíbélì Phillips.a

Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 46

Ṣé ọkàn rẹ kò ti tàn ọ́ jẹ débi pé kó o máa pa ìpàdé jẹ?

8. (a) Kí ni Kristẹni kan lè fẹ́ máa fi fọ́nnu? (b) Kí nìdí tí mímọ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ń ṣe fáwọn èèyàn nìkan kò fi tó?

8 Òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní jẹ́ ọlọ́rọ̀, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n gbajúmọ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn Kristẹni kan ní àkókò tiwa. Irú ojú wo ló yẹ kí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi máa wo ohun tọ́wọ́ wọn ti tẹ̀, ojú wo ló sì yẹ káwa máa fi wo àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀? Jèhófà pèsè ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nípasẹ̀ Jeremáyà. (Ka Jeremáyà 9:23, 24.) Dípò kéèyàn máa fi àṣeyọrí ọmọ èèyàn fọ́nnu, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn ní ìmọ̀ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, torí ìyẹn lohun tó ṣe pàtàkì jù. (1 Kọ́r. 1:31) Kí ló túmọ̀ sí láti ní ìjìnlẹ̀ òye àti ìmọ̀ Jèhófà? Ṣẹ́ ẹ rí i, àwọn èèyàn ìgbà ayé Jeremáyà mọ orúkọ Ọlọ́run. Wọ́n tún gbọ́ nípa bó ṣe dáàbò bo àwọn baba ńlá wọn ní Òkun Pupa, nígbà tí wọ́n fẹ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí, nígbà ayé àwọn Onídàájọ́ àti nígbà táwọn ọba tó jẹ́ olóòótọ́ ń ṣàkóso wọn. Àmọ́ wọn ò mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, wọn ò sì ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé: “Mo ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀. Dájúdájú, ìbínú [Ọlọ́run] ti yí padà kúrò lórí mi.”—Jer. 2:35.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká mọ̀ pé ọkàn wa máa ń ṣe àdàkàdekè? Báwo la ṣe lè ṣàyẹ̀wò ọkàn wa tá a ó fi lè mọ ojú tí Jèhófà Olùṣàyẹ̀wò ọkàn tó ga jù fi ń wò wá?

BÍ JÈHÓFÀ ṢE Ń SỌ WÁ DI IRÚ ẸNI TÓ FẸ́

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 48

Ṣé ò ń jẹ́ kí Jèhófà sọ ọ́ di irú ẹni tó fẹ́?

9. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé èèyàn lè yí ọkàn pa dà, báwo la sì ṣe lè yí i pa dà?

9 Ó yẹ kí àwọn Júù tí Jeremáyà jíṣẹ́ Ọlọ́run fún yí ọkàn pa dà. Wọ́n sì lè yí pa dà nítorí Ọlọ́run sọ nípa àwọn Júù tó máa pa dà wá láti ìgbèkùn pé: “Èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn-àyà láti mọ̀ mí, pé èmi ni Jèhófà; wọn yóò sì di ènìyàn mi, èmi fúnra mi yóò sì di Ọlọ́run wọn, nítorí wọn yóò . . . padà sọ́dọ̀ mi.” (Jer. 24:7) Èèyàn lè ṣerú ìyípadà bẹ́ẹ̀ lóde òní náà. Yàtọ̀ síyẹn, èyí tó pọ̀ jù nínú wa la lè mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn wa. Ohun pàtàkì mẹ́ta tó máa jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni, ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ríronú jinlẹ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ti gbé ṣe nínú ìgbésí ayé wa àti fífi ohun tá a ti kọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù. Ó yẹ ká jẹ́ kí Ọlọ́run Olùṣàyẹ̀wò ọkàn tó ga jù yẹ ọkàn wa wò, ká má dà bíi tàwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà. Àwa fúnra wa gan-an sì lè fi Bíbélì yẹ ọkàn ara wa wò, a sì tún lè ṣàyẹ̀wò ọkàn wa tá a bá ń kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà ti ń ṣe fún wa. (Sm. 17:3) Ó sì bọ́gbọ́n mu gan-an pé ká ṣe bẹ́ẹ̀!

10, 11. (a) Kí nìdí tí Jeremáyà fi lọ sílé amọ̀kòkò? (b) Kí ló ń pinnu ohun tí Jèhófà máa fi èèyàn ṣe?

10 Sátánì máa ń fẹ́ fipá mú gbogbo èèyàn tẹ̀ sí ọ̀nà kan náà láti lè sọ wọ́n dà bó ṣe fẹ́, ṣùgbọ́n ní ti Ọlọ́run, ó máa ń wo irú èèyàn tẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ́ tó bá fẹ́ sọ̀ọ̀yàn dẹni tó máa lò. A rí àpẹẹrẹ èyí nínú ohun tí Ọlọ́run ní kí Jeremáyà ṣe. Lọ́jọ́ kan, Ọlọ́run ní kí Jeremáyà lọ sí ilé amọ̀kòkò kan. Bí amọ̀kòkò náà ṣe ń mọ ìkòkò lórí àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ohun èlò tó ń mọ bà jẹ́, bó kàn ṣe fi amọ̀ tútù náà mọ ohun èlò míì nìyẹn. (Ka Jeremáyà 18:1-4.) Kí nìdí tí Jèhófà fi ní kí Jeremáyà lọ wo ohun tí amọ̀kòkò náà ń ṣe, ẹ̀kọ́ wo lohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ sì kọ́ wa?

11 Jèhófà fẹ́ fi han Jeremáyà àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé òun láṣẹ láti sọ àwọn èèyàn àtàwọn orílẹ̀-èdè dà bí òun ṣe fẹ́. Ọwọ́ wo ni Ọlọ́run máa fi ń mú àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ tó dà bí amọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀? Jèhófà kò dà bí amọ̀kòkò tó jẹ́ èèyàn, kì í ṣàṣìṣe; bẹ́ẹ̀ ni kì í dédé pa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ run. Ọwọ́ táwọn èèyàn bá fi mú ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń tọ́ wọn ló ń pinnu ohun tó máa fi wọ́n ṣe.—Ka Jeremáyà 18:6-10.

12. (a) Kí ni Jèhóákímù ṣe nígbà tí Jèhófà fẹ́ kó yí pa dà? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn Jèhóákímù kọ́ wa?

12 Báwo wá ni Jèhófà ṣe ń sọ̀ọ̀yàn di irú ẹni tó fẹ́? Ohun tó ń lò jù lóde òní ni Bíbélì. Béèyàn bá ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ohun tónítọ̀hún ń ṣe nípa ohun tó kà ló ń fi irú ẹni tó jẹ́ hàn. Ọlọ́run á wá sọ ọ́ di irú ẹni tó fẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jèhóákímù Ọba ká lè rí irú ẹni táwọn èèyàn ìgbà ayé Jeremáyà sọ ara wọn dà. Òfin Mósè pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni “kò gbọ́dọ̀ lu lébìrà tí [ó] gbà sí iṣẹ́ . . . ní jìbìtì,” síbẹ̀, ohun tí ọba yìí ṣe gan-an nìyẹn. Ó ń lo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì èèyàn rẹ̀ nílò ẹrú níbi tó ti ń kọ́ “ilé aláyè gbígbòòrò.” (Diu. 24:14; Jer. 22:13, 14, 17) Ọlọ́run gbẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ bá Jèhóákímù sọ̀rọ̀ láti lè yí i pa dà. Síbẹ̀, ńṣe ni ọba yìí jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ tó ń ṣe àdàkàdekè máa darí rẹ̀. Ó ní: “Èmi kì yóò ṣègbọràn.” Ó sì ń bá ìwà ibi tó ti ń hù láti ìgbà èwe rẹ̀ nìṣó. Nítorí náà, Ọlọ́run sọ pé: “Bí a ṣe ń sin akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a ó sin [Jèhóákímù], pẹ̀lú ìwọ́káàkiri àti ìgbésọnù.” (Jer. 22:19, 21) Ìwà òmùgọ̀ gbáà ló máa jẹ́ táwa náà bá sábà máa ń sọ pé: “Bémi ṣe ń ṣe nǹkan tèmi nìyẹn o!” Lóde òní, Ọlọ́run kì í rán àwọn wòlíì bíi Jeremáyà sí wa mọ́, ṣùgbọ́n ó máa ń tọ́ wa sọ́nà. Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye máa ń jẹ́ ká mọ àwọn ìlànà Bíbélì ká sì máa fi wọ́n sílò. Àwọn ìlànà yìí lè dá lórí àwọn nǹkan tá a sábà máa ń ṣe, irú bí, ìmúra wa, orin àti ijó jíjó níbi ìgbéyàwó tàbí láwọn ayẹyẹ míì. Ṣé a máa jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà nínú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀?

13, 14. (a) Kí ló mú káwọn tó ní ẹrú ní Jerúsálẹ́mù gbà láti dá àwọn ẹrú wọn tó jẹ́ Hébérù sílẹ̀? (b) Kí ló fi ohun tó wà lọ́kàn àwọn tó ni ẹrú náà hàn?

13 Wo àpẹẹrẹ míì. Àwọn ará Bábílónì fi Sedekáyà jẹ ọba Júdà kó lè máa ṣàkóso lábẹ́ wọn. Sedekáyà wá ṣọ̀tẹ̀ láìka ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún un látẹnu Jeremáyà sí. (Jer. 27:8, 12) Làwọn ará Bábílónì bá sàga ti Jerúsálẹ́mù. Sedekáyà àtàwọn ọmọ aládé rẹ̀ wá ronú pé ó yẹ káwọn ṣe ohun kan tó bá Òfin Ọlọ́run mu kí wọ́n lè rójú rere Ọlọ́run. Ọba yìí mọ̀ pé tí Hébérù èyíkéyìí bá jẹ́ ẹrú, ó yẹ kí ọ̀gá rẹ̀ dá a sílẹ̀ ní ọdún keje tó ti ń sìnrú. Ó wá bá àwọn ará Jerúsálẹ́mù dá májẹ̀mú pé kí wọ́n tú àwọn ẹrú bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. (Ẹ́kís. 21:2; Jer. 34:14) Ìyẹn ni pé, yíyí táwọn ọ̀tá yí Jerúsálẹ́mù ká ló mú kí wọ́n dédé wò ó pé á dára káwọn dá ẹrú àwọn sílẹ̀.—Ka Jeremáyà 34:8-10.

14 Nígbà tó yá, ẹgbẹ́ ológun kan láti Íjíbítì wá gbèjà àwọn ará Jerúsálẹ́mù, èyí tó mú kí àwọn ará Bábílónì fà sẹ́yìn kúrò ní Jerúsálẹ́mù. (Jer. 37:5) Kí ni àwọn tó ti dá ẹrú wọn sílẹ̀ wá ṣe? Ńṣe ni wọ́n fipá mú àwọn ẹrú náà pa dà wá sìnrú. (Jer. 34:11) Ní kúkúrú, nígbà táwọn Júù yìí wà nínú ewu, wọ́n dọ́gbọ́n ṣe bí ẹni pé wọ́n ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́, bíi pé ìyẹn á jẹ́ kí Ọlọ́run gbójú fo ìwà àìgbọràn tí wọ́n ti ń hù tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí kò séwu mọ́, wọ́n tún pa dà sínú ìwàkiwà wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣe bí ẹni pé àwọn ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́, ohun tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà fi hàn pé, nínú ọkàn wọn, wọn ò fẹ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì di irú ẹni tí Ọlọ́run fẹ́.

Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ látinú ohun tí Jeremáyà sọ nípa amọ̀kòkò kan? Báwo ni Jèhófà ṣe ń sọ̀ọ̀yàn di irú ẹni tó fẹ́ lóde òní?

JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ SỌ Ọ́ DI IRÚ ẸNI TÓ FẸ́

15. Báwo lo ṣe máa gba Jèhófà láyè tó láti sọ ọ́ di irú ẹni tó fẹ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.

15 Ìjọ àwọn èèyàn Jèhófà tó kárí ayé lè ti jẹ́ ká mọ àwọn ìlànà Bíbélì lórí kókó kan pàtó. Bí àpẹẹrẹ, ká ní àárín àwa àti arákùnrin kan kò gún, a lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe. (Éfé. 4:32) A sì lè gbà pé ó bọ́gbọ́n mu ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì láti yanjú irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, irú amọ̀ wo la máa fi hàn pé a jẹ́? Ṣé a máa gbà kí Jèhófà sọ wá di irú ẹni tó fẹ́ gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò ṣe ń fi amọ̀ mọ ohun tó fẹ́? Tá a bá jẹ́ ẹni tí ọkàn rẹ̀ rọ̀ tó sì ṣeé tẹ̀, a óò ṣe ohun tí Bíbélì sọ; Jèhófà Amọ̀kòkò tí kò lẹ́gbẹ́ yóò sì sọ wá dohun èlò táá túbọ̀ wúlò fún un. (Ka Róòmù 9:20, 21; 2 Tímótì 2:20, 21.) Dípò ká hùwà bíi ti Jèhóákímù tàbí bí àwọn ọ̀gá àwọn ẹrú ti ìgbà ayé Sedekáyà, ṣe ló yẹ ká jẹ́ kí Jèhófà sọ wá di ẹni tó máa lò fún ète ọlọ́lá.

16. Òtítọ́ pàtàkì wo ni Jeremáyà mọ̀?

16 Ọlọ́run sọ Jeremáyà pàápàá di irú ẹni tó fẹ́. Irú ọwọ́ wo ni wòlíì yìí fi mú ọ̀rọ̀ náà? A mọ̀ láti inú ọ̀rọ̀ tó sọ. Ó gbà pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Ó wá bẹ̀bẹ̀ pé: “Tọ́ mi sọ́nà, Jèhófà.” (Jer. 10:23, 24) Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ẹ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà? Ó dájú pé ẹ ní ọ̀pọ̀ ìpinnu láti ṣe. Ńṣe làwọn ọ̀dọ́ kan máa ń fẹ́ ‘darí àwọn ìṣísẹ̀ ara wọn.’ Nígbà tó o bá ń ṣe àwọn ìpinnu rẹ, ṣé wàá jẹ́ kí Ọlọ́run máa tọ́ ọ sọ́nà? Ṣé wàá ṣe bíi ti Jeremáyà, kó o fi ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé ẹ̀dá èèyàn ò lè darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀ rárá? Rántí o: Tó o bá ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, yóò sọ ọ́ di ẹni tó túbọ̀ wúlò.

17-19. (a) Kí nìdí tí Jeremáyà fi rin ìrìn àjò lọ sí iyànníyàn Odò Yúfírétì? (b) Kí lèrò tó lè mú kí Jeremáyà má ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe? (d) Kí ni ohun tí Jeremáyà ṣe nípa ìgbànú yìí mú kó ṣeé ṣe?

17 Iṣẹ́ wòlíì tí Jeremáyà ń ṣe gba pé kó jẹ́ onígbọràn sí ìtọ́ni Ọlọ́run. Ká sọ pé ìwọ ni Jeremáyà, ǹjẹ́ gbogbo ìtọ́ni tí Jèhófà bá fún ọ ni wàá máa tẹ̀ lé? Nígbà kan, Jèhófà sọ fún Jeremáyà pé kó wá ìgbànú tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe kó sì sán an mọ́ ìdí. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ fún un pé kó gbéra kó lọ sí Odò Yúfírétì. Tó o bá wo ìwé àwòrán ilẹ̀, wàá rí i pé ìrìn àjò náà tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà. Jèhófà sọ fún Jeremáyà pé tó bá dọ́hùn-ún, kó fi ìgbànú náà pa mọ́ sínú pàlàpálá àpáta gàǹgà kí ó sì tún bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run tún ní kó pa dà lọ mú ìgbànú náà níbẹ̀. (Ka Jeremáyà 13:1-9.) Tá a bá ṣírò gbogbo ìrìn àjò tí Jeremáyà rìn, ó tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1,900] kìlómítà. Ó ṣòro fáwọn olùṣe lámèyítọ́ Bíbélì láti gbà pé Jeremáyà rìn jìnnà tóyẹn, tó ń fẹsẹ̀ rin ìrìn tó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù.b (Ẹ́sírà 7:9) Síbẹ̀, ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe gan-an nìyẹn, òun náà ni Jeremáyà sì ṣe.

18 Fojú inú yàwòrán bí wòlíì náà ṣe ń fẹsẹ̀ rìn lọ lórí àwọn òkè Jùdíà, títí táá fi sọ̀ kalẹ̀ gba inú aṣálẹ̀ kọjá lọ sí Odò Yúfírétì. Bẹ́ẹ̀ kò sóhun méjì tó fẹ́ lọ ṣe jú pé kó fi ìgbànú aṣọ ọ̀gbọ̀ pa mọ́ o! Ó dájú pé àìsí nílé rẹ̀ fúngbà pípẹ́ máa mú kí àwọn aládùúgbò rẹ̀ máa béèrè rẹ̀, wọ́n á sì fẹ́ mọ ibi tó lọ. Nígbà tó sì máa dé, kò mú ìgbànú aṣọ ọ̀gbọ̀ rẹ̀ dání wá. Ọlọ́run sì tún sọ fún un pé kó tún gbọ̀nà iyànníyàn Odò Yúfírétì lọ, kó pa dà lọ mú ìgbànú tó ti bà jẹ́ tí ‘kò sì yẹ fún ohunkóhun’ mọ́ yẹn wá. Wo bó ṣe rọrùn tó fún wòlíì náà láti ronú pé: ‘Wàhálà yìí ti wá pọ̀ jù o. Ṣe ni Ọlọ́run kàn ń dà mí láàmú kiri lásán.’ Síbẹ̀, Jeremáyà ò ronú bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó ti gbẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Dípò táá fi ráhùn, ńṣe ló tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un!

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 53

Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà kódà tá ò bá fi bẹ́ẹ̀ lóye ìdí tó fi fún wa?

19 Ẹ̀yìn tó ti rin ìrìn àjò ẹ̀ẹ̀kejì ni Ọlọ́run tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàlàyé ìdí tó fi ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn fún un. Ńṣe lohun tí Jeremáyà ṣe yìí máa jẹ́ kó rí nǹkan tọ́ka sí nígbà tó bá ń jíṣẹ́ tó lágbára tí Jèhófà rán an yìí, pé: “Àwọn ènìyàn búburú yìí tí wọ́n ń kọ̀ láti ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń rìn nínú agídí ọkàn-àyà wọn, tí wọ́n sì ń tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn ṣáá láti sìn wọ́n, àwọn pẹ̀lú yóò dà bí ìgbànú yìí tí kò yẹ fún nǹkan kan.” (Jer. 13:10) Ọ̀nà tí Jèhófà gbà tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́kàn yìí mà dára o! Bí Jeremáyà sì ṣe ṣègbọràn látọkàn wá nínú ohun tó dà bíi pé kò tó nǹkan yìí, jẹ́ kí Jèhófà rí nǹkan tọ́ka sí bó ṣe ń gbìyànjú láti mú kí ọ̀rọ̀ òun wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn.—Jer. 13:11.

20. Kí nìdí tí ìgbésí ayé tó ò ń gbé gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni fi lè ya àwọn míì lẹ́nu, àmọ́ kí ló yẹ kó dá ọ lójú?

20 Jèhófà ò sọ pé kí àwa Kristẹni òde òní fẹsẹ̀ rin ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà torí kó lè fìyẹn kọ́ aráyé ní ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ìgbésí ayé tó ò ń gbé gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kò ní máa ya àwọn aládùúgbò tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lẹ́nu, bóyá kó tiẹ̀ jẹ́ kí wọ́n máa ta kò ọ́? Ó lè kan ìmúra rẹ, ohun tó o máa ṣe tó bá dọ̀ràn lílọ sílé ẹ̀kọ́, ohun tó o fẹ́ fìgbésí ayé rẹ ṣe tàbí ojú tó o fi ń wo ọtí mímu. Ṣé ìwọ náà máa ṣe bíi ti Jeremáyà, kó o jẹ́ kí Ọlọ́run máa darí rẹ nínú ohun gbogbo? Nítorí pé o ti jẹ́ kí Ọlọ́run tẹ ọkàn rẹ síbi tó fẹ́, àwọn ohun tó ò ń ṣe á jẹ́ kó o lè máa wàásù dáadáa fáwọn èèyàn. Lọ́rọ̀ kan ṣá, jẹ́ kó dá ọ lójú pé tó o bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó o sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà, títí láé ni wàá máa jàǹfààní rẹ̀. Dípò tí wàá fi jẹ́ kí ọkàn tó ń ṣe àdàkàdekè máa darí rẹ, ńṣe ló yẹ kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà. Fi ṣe ìpinnu rẹ nígbà náà láti jẹ́ kí Ọlọ́run sọ ọ́ di irú ẹni tó fẹ́. Jẹ́ kó sọ ọ́ dohun èlò ọlọ́lá tó máa wúlò fún un títí láé.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kọjú ìjà sí ipa búburú tí Sátánì, ayé àti ọkàn wa tó jẹ́ aláìpé lè fẹ́ ní lórí wa?

a Bíbélì NET (2005) kà pé: “Má ṣe jẹ́ kí ayé mú ẹ tẹ̀ sí ọ̀nà rẹ̀.” Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tó wà níbẹ̀ sọ pé: “Ó ṣe kedere pé àwọn kan wo ọ̀rọ̀ náà ‘mú ẹ tẹ̀ sí’ tó wà nínú ẹsẹ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun téèyàn ń ṣe láìfura. Ṣùgbọ́n, . . . déwọ̀n àyè kan, ó lè jẹ́ ohun téèyàn ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Àmọ́ ṣá, ó jọ pé ọ̀nà méjèèjì ni ayé gbà ń múni tẹ̀ sí ọ̀nà rẹ̀.”

b Àwọn kan gbà pé ìtòsí ni Jeremáyà lọ dípò iyànníyàn Odò Yúfírétì. Kí nìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé: “Ìdí kan ṣoṣo táwọn aṣelámèyítọ́ yìí fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, wọ́n wò ó pé wàhálà ìrìn àjò ẹ̀ẹ̀méjì tàlọ tàbọ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí iyànníyàn Odò Yúfírétì á ti pọ̀ jù fún wòlíì náà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́