“Lékè Ohun Gbogbo, Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan”
Ẹgbẹ́ àwọn ará wa tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ jẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Sm. 133:1) Abájọ tí àpọ́sítélì Pétérù fi sọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn pé: “Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Nítorí náà, ẹ yè kooro ní èrò inú, kí ẹ sì wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn. Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Pét. 4:7, 8) Torí pé a wà láàárín àwọn Kristẹni tá a jọ jẹ́ ará, à ń gbádùn wíwà nínú òtítọ́ pẹ̀lú àwọn bàbá, ìyá, arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí tí wọ́n ń kóni mọ́ra, tí wọ́n sì ń dúró tini. (Máàkù 10:29, 30) Síbẹ̀, lábẹ́ onírúurú ipò, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kí àjọṣe àárín àwa àti àwọn ará wa máà dán mọ́rán mọ́. Kí la lè ṣe tí ìfẹ́ wa kò fi ní dín kù nínú ayé aláìnífẹ̀ẹ́ yìí? Apá tá a fẹ́ bójú tó yìí máa jẹ́ ká lè túbọ̀ lóye ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì gbà wá nínú 1 Pétérù 4:7, 8. Á tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa àti sáwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bí i tiwa.
Ìdí pàtàkì tá a fi nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì-kìíní-kejì ni pé “ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá.” (1 Jòh. 4:7) Jèhófà tó jẹ́ orísun ànímọ́ tó ta yọ yìí ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa. Ó sì fi èyí hàn nípa bó ṣe jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ kú fún wa lórí òpó igi oró “kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.” (1 Jòh. 4:9) Kí ló yẹ kí àwa náà ṣe láti fi hàn pé a mọrírì ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí Ọlọ́run fi hàn sí wa yìí? 1 Jòhánù 4:11 sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà náà àwa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” Tá a bá ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara wa, a kò retí pé kí Ọlọ́run dúpẹ́ lọ́wọ́ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa là ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí pé ẹgbẹ́ ará tó fi jíǹkí wa yìí jẹ́ ẹ̀bùn tá a mọyì rẹ̀ gan-an. A gbà pé àwọn aládùúgbò wa náà lè di olùjọsìn Jèhófà, a ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn bá a ṣe ń sọ “ìhìn rere ohun tí ó dára jù” fún wọn. (Aisáyà 52:7) Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé aláìnífẹ̀ẹ́ yìí ṣe ń kógbá sílé, ẹ jẹ́ ká máa ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé a ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ara wa!