ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/02 ojú ìwé 3
  • Ìdí Tá A Fi Nífẹ̀ẹ́ Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tá A Fi Nífẹ̀ẹ́ Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Wa
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Lékè Ohun Gbogbo, Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Ẹgbẹ́ Ará Tó Wà Níṣọ̀kan
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìpìlẹ̀ Ayé Titun naa Ni A Ń Fi Lélẹ̀ Nisinsinyi
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • A Ṣètò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láti Wàásù Ìhìn Rere
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 6/02 ojú ìwé 3

Ìdí Tá A Fi Nífẹ̀ẹ́ Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Wa

Nínú ayé aláìnífẹ̀ẹ́ tá à ń gbé lónìí, báwo la ṣe lè máa bá a nìṣó láti fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin wa nípa tẹ̀mí? (1 Pét. 2:17) Báwo la ṣe lè fi han àwọn ẹlòmíràn pé lóòótọ́ la ní ojúlówó ẹgbẹ́ àwọn ará kan kárí ayé? (Mát. 23:8) Ó jẹ́ nípa lílo fídíò náà, Our Whole Association of Brothers. Fídíò yìí jẹ́ ká mọ àwọn ìdí tá a fi nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní kejì. Wò ó ná bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:

(1) Àwọn ìgbòkègbodò mẹ́ta wo ni àwa àtàwọn ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé ń lọ́wọ́ sí? (2) Báwo làwọn arákùnrin wa ṣe ń fi ìpinnu wọn láti wàásù hàn (a) ní aginjù Alaska, (b) ní àwọn èbúté ilẹ̀ Yúróòpù tó lọ rẹrẹẹrẹ, àti (d) ní àwọn igbó kìjikìji ilẹ̀ Peru? (3) Irinṣẹ́ wo ló gbéṣẹ́ gan-an láti fi jẹ́rìí? (4) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rò pé iṣẹ́ yẹpẹrẹ kan lásán ni iṣẹ́ ìwàásù? (5) Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tu ara wọn nínú tí wọ́n sì ṣèrànwọ́ fún ara wọn lásìkò ìṣòro, irú bíi nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ wáyé, nígbà ìjì líle, àti nígbà ogun abẹ́lé. (Wo ọ̀rọ̀ tí Takao sọ nínú Jí! August 22, 1995, ní ojú ìwé 23, àti ọ̀rọ̀ tí Kotoyo sọ nínú Jí! October 22, 1996, ní ojú ìwé 20.) (6) Láwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ wo ni gbogbo wa ti lè ṣàfihàn àmì pàtàkì náà táwọn èèyàn fi ń dá ẹgbẹ́ ará Kristẹni wa mọ̀? (Jòh. 13:35) (7) Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn ìpàdé ìjọ wa ṣe pàtàkì sí wa tó? (8) Báwo ni níní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan níbi táwọn ará ti lè pàdé pọ̀ ṣe máa ń rí lára àwọn tí kò tíì ní ìkankan tẹ́lẹ̀? (9) Báwo làwọn arákùnrin wa ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù àti Rọ́ṣíà ṣe là á já nípa tẹ̀mí nígbà tí wọ́n wà lábẹ́ ìfòfindè? (10) Àní lásìkò tá a wà yìí pàápàá, àkànṣe ìsapá wo ni ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe láti lè lọ sí àpéjọ àgbègbè, kí sì nìdí? Báwo ni èyí ṣe fún ọ níṣìírí? (11) Kí ni ìdí tó o fi pinnu láti máa jọ́sìn pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ní ìṣọ̀kan, láti máa ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn lásìkò ìṣòro, àti láti máa fi ìṣòtítọ́ wàásù níbikíbi àti ní ọ̀nà èyíkéyìí tó bá ti lè ṣeé ṣe? (12) Kí nìdí tó fi máa dáa kí kálukú wa ní ẹ̀dà fídíò yìí kan, ká sì jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn wò ó?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́